Sanyeri gbówó kalẹ̀ fẹ́ni tó bá lè fìdí rẹ̀ múlè pé ó fẹ́ f’iṣẹ́ tíátà sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Sanyeri234/Instagram
Latigba ti gbajugbaja oṣere apanilẹrin nni, Ọlaniyi Afọnja ti sọ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe laipẹ yii, nibi to ti ṣalaye idi ti kii fi saba kopa ninu iṣẹ sinima daadaa mọ, ni oriṣiriṣiri iroyin miran ti n jade nipa rẹ.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe Afọnja ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ tun mọ si Sanyẹri ti fiṣẹ tiata silẹ, nitori ti ko pe e mọ, bẹẹ lawọn miran n sọ pe o ti fẹyinti.
Ṣugbọn ọmọ bibi ilu Ọyọ ni ipinlẹ Ọyọ naa ti wa jade sita funra rẹ lati sọ pe irọ to jinna si otitọ ni iroyin ti awọn kan jokoo si kọọrọ yara wọn, ti wọn si n gbe kaakiri ori ikanni ayelujara nipa oun.
Ninu fọnran to gbe sori ikanni Instagram rẹ, Sanyẹri sọ pe oun ko figba kankan sọ pe oun ti fi iṣẹ tiata ti gbogbo aye mọ oun mọ, ati pe awọn kan ti wọn fẹẹ dan iṣẹ Ọlọrun wo ni wọn n gbe iroyin ẹlẹjẹ kaakiri nipa oun.
Siwaju sii ni Sanyeri naa tun sọ pe awọn to fẹẹ pana ogo ati irawọ Ọlọrun lara oun ni wọn n wa ọna, ṣugbọn to sọ pe Ọlọrun ko le fun wọn ṣe.
Bẹẹ lo fi kun ọrọ rẹ pe oun ṣetan lati fun ẹnikẹni to ba le mu ẹri ibi toun ti sọ pe oun fi iṣẹ tiata silẹ ni ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe
“Ewo ninu yin lo fẹẹ pana ogo ti Ọlọrun ṣe fun Sanyẹri, ṣe ọkunrin ni abi obinrin? Ewo ninu yin lo fẹẹ pana irawọ ti Ọlọrun fun Sanyẹri?
“Ewo ninu yin lo gbe ẹnu si ẹrọ gbohungbohun to n sọ wi pe oun fẹẹyin ara oun ti lai kii ṣe emi. Nigba ti Ọlọrun ko wa fẹyinti mi ti nkọ, ẹmi ko le fẹyin ara mi ti.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
“Emi o mọ gbogbo awọn to n ṣe iru iṣẹ yii o, yala ọkunrin ni tabi obinrin ni, mo fa gbogbo yin le Ọlọrun lọwọ, ayafi to ba wa jẹ pe ẹ tobi ju Ọlọrun lọ lo ku.
“Ni bayii, mo wa fẹẹ fi asiko yii tun sọ fun gbogbo ẹyin ololufẹ mi ni gbogbo agbaye wi pe emi Ọlaniyi Afọnja ti mo jẹ ololufẹ yin, mi o figba kankan sọ fun un yin wi pe mo fẹẹ fi iṣẹ tiata silẹ.
“Koda, mi o sọ wi pe o su mi, o rẹ mi, debi ti maa wa sọ wi pe mi o ṣe tiata mọ. Ko si nnkan to jọ bẹẹ. Ti ẹ ba wa fẹẹ mu ẹri rẹ wa fun mi, ẹ dakun, mo n pe gbogbo ẹyin ololufẹ mi kaakiri agbaye nija, ati awọn to n fẹ mi, ati awọn ti ko fẹ mi naa, nitori mo mọ pe gbogbo eeyan kọ lo le nifẹẹ eeyan.
“Ẹ dakun, ẹ kan ba mi mu ẹri kan ṣoṣo pere wa, nibi ti mo ti la ẹnu sọrọ wi pe mi o ṣe tiata mọ, ti mo si sọ pe mo ti fi iṣẹ tiata silẹ, wi pe mi o ṣe mọ.
“Ti a ba wa ri ẹni to ri ẹri naa mu wa, ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan (N100,000) ni maa fun ẹni naa pẹlu ogo Ọlọrun.”















