Wo orílẹ́èdè Adúláwọ̀ márùn-ún tí ètò ọrọ̀ ajé wọn tóbi àmọ́ tí òṣì àti ìṣẹ́ ń báwọn èèyàn wọn fínra

Àwòrán owó

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àtẹ̀jáde kan tí àjọ àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ owó ní àgbáyé ìyẹn International Monetary Fund, IMF ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde ti ṣàfihàn àwọn orílẹ̀ èdè márùn-ún tí ètò ọrọ̀ ajé wọn gbòòrò si ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Nàìjíríà, tó fi ìgbà kan wà ní ipò kìíní àwọn orílẹ̀ èdè tí ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀ da jùlọ ní Áfíríkà ti wà ní ipò kẹrin báyìí, tí South Africa sì ti gba ipò kìíní mọ lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde IMF ṣe sọ.

Ẹ̀wẹ̀, bí ètò ọrọ̀ ajé orílẹ̀ èdè kan bá ṣe tóbi tó kò túmọ̀ sí irú ìgbé ayé tí àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè náà ń gbé.

Ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè ló ní gbèsè púpọ̀ lọ́rùn, ìpèníjà àwọn ohun amáyédẹrùn, ọ̀wọ́n gógó àti àìrajaja ètò ọrọ̀ ajé.

IMF ní àwọn ìṣòro yìí ń ṣàkóbá fún ètò ọrọ̀ ajé àwọn orílẹ̀ èdè Áfíríkà.

South Africa ni orílẹ̀ èdè àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀ ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀ gbòòrò, tí Egypt sì tẹ̀le. Algeria ló wà ní ipò kẹta nígbà tí Nàìjíríà ti bọ́ sí ipò kẹrin. Ethiopia ló wà ní ipò karùn-ún.

Dókítà Zainab Usman tó jẹ́ adarí ní Carnegie Endowment for International Peace ní àtẹ̀jáde náà ṣàfihàn bí àwọn orílẹ̀ èdè náà ṣe mójútó àwọn ìpèníjà ètò ìsúná wọn sí.

Ó ní Nàìjíríà àti Egypt ń rí ìjáwálẹ̀ nínú owó tí wọ́n ń pa wọlé látara pípèsè ọjà àti láti máa kó ọjà lọ sí ilẹ̀ òkèrè láti orílẹ̀ èdè wọn, gbèsè gọbọi àti ìjáwálẹ̀ owó wọn.

Ó ní àwọn nǹkan wọ̀nyí ti ṣàkóbá fáwọn èèyàn orílẹ̀ èdè yìí tí kò jẹ́ kí owó tó ra nǹkan lọ́jà.

Àmọ́ ó bà ni, kò bàjẹ́ ni IMF wí nígbà tí wọ́n ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀ máa lọ sókè si jùlọ ní àgbéyè pẹ̀lú ìdá 3.5% lọ́dún 2024 àti 4% lọ́dún 2025.

South Africa

Àwòrán èèyàn tó ń gbówó

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àjọ IMF ní orílẹ̀ èdè South Africa ni ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀ máa búrẹ́kẹ́ jùlọ lọ́dún 2024 pẹ̀lú èròńgbà pé wọ́n máa ní tó $373bn.

Orílẹ̀ èdè ọ̀hún tó ti wà lára àwọn orílẹ̀ èdè tó ń pèsè ọjà jùlọ mú ìgbòrò bá ẹ̀ka ìwàkùsà, ọ̀gbìn, ìnàjú àti àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ láti pọkún ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀.

Àmọ́, síbẹ̀ ìgbé ayé àwọn olùgbé South Africa kò dára si.

Ìwádìí kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní FinScope Consumer Sotg Africa 2023 ní ìlàjì àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè ló máa ń yá owó láti fi ra oúnjẹ ni.

Ìwádìí náà ṣàlàyé pé àwọn ènìyàn South Africa máa ń lo ìdá ọgọ́rin nínú owó wọn láti fi wọkọ̀, jẹun, san owó ilé, iná mọ̀nàmọ́ná àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Pẹ̀lú ètò ohun àmúṣagbára tí ìjọba South Africa fi lọ́lẹ̀ nínú oṣù Kẹjọ, ọdún 2023 síbẹ̀ iná mọ̀nàmọ́ná kò ì dúró ire níbẹ̀.

Ìgbìmọ̀ iléeṣẹ́ Ààrẹ lórí àyípadà ojú ọjọ́ bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ náà pé kò lè tán ìṣòro iná mọ̀nàmọ́ná South Africa.

Egypt

Àwòrán

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àjọ IMF kéde Egypt bí orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀ lágbára pẹ̀lú owó $347bn.

Àmọ́ láti ọjọ́ pípẹ́ ni ọ̀wọ́n gógó àti àìsí owó ilẹ̀ òkèrè ti ń bá orílẹ̀ èdè náà fínra.

Nínú oṣù Kẹta ni ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ Egypt lékún pẹ̀lú ìdá 45%. Bákan náà ni ìjọba tún fi kún owó epo bẹntiróòlù, èyí tó jẹ́ kí ọ̀wọ́n gógó tún peléke si.

Bákan náà ni ogun tó ń wáyé láàárín Israel àti Gaza tún ṣàkóbá fún Egypt nítorí àdínkù ti bá iye ọkọ̀ òfurufú tó ń gbéra ní Suez Canal, tó jẹ́ ọ̀nà kan gbòógì tí Egypt ti ń pawó wọlé.

Láìpẹ́ yìí ni wọ́n yá owó bílíọ̀nù mẹ́jọ dọ́là ní IMF kún bílíọ̀nù mẹ́ta dọ́là tí wọ́n ti ṣáájú gbà.

Algeria

Algeria

IMF ní ètò ọrọ̀ ajé Algeria wọ $267bn.

Lẹ́yìn tí Russia kógun ja Ukraine ni wọ́n ṣàwárí afẹ́fẹ́ gáàsì ní Algeria, tó sì ti mú àlékún bá iye owó tó ń wọ àpò orílẹ̀ èdè náà àti ètò ọrọ̀ ajé rẹ̀.

Àmọ́ síbẹ̀, ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ ń bá àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè náà fínra.

Nàìjíríà

Àwòrán oúnjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nàìjíríà ni ó wà ní ipò kẹrin orílẹ̀ èdè tí ọrọ̀ ajé rẹ̀ tóbi ní Áfíríkà pẹ̀lú $253bn, gẹ́gẹ́ bí IMF ṣe fi léde.

Ìjọba Nàìjíríà lábẹ́ àkóso Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sọ pé ohun ló ṣokùnfà bí ètò ọrọ̀ ajé ṣe dẹnu kọlẹ̀.

Láti ọdún pípẹ́ ni Nàìjíríà ti ń kojú ọ̀wọ́n gógó epo bẹntiróòlù. Tinubu, tó gba àkóso ìjọba ní oṣù Karùn-ún ọdún 2023 kéde pé àwọn ti yọ ìrànwọ́ orí epo nítorí ó ń ṣe àkóbá fún àwọn ẹ̀ka mìíràn tó yẹ kó máa jẹ àǹfàní owó náà.

Ìlọ́po mẹ́ta tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni àwọn èèyàn fi ń ra epo báyìí èyí tó ń fa ìṣòro fún ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà.

Charlie Robertson, olórí ẹ̀ka Macro Strategy ní lára nǹkan tó ń ṣe àkóbá fún ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ni bí owó náírà ti ṣe ní ìjákulẹ̀ sí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.

Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé àwọn ọjà tí wọ́n ń kó wọ Nàìjíríà láti òkè òkun yóò gbówó lórí si nítorí nǹkan ilẹ̀ òkèrè ni àwọn ọmọ Nàìjíríà máa ń rà jù.

Ethiopia

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ethiopia ló wà ní ipò karùn-ún àtẹ IMF pẹ̀lú owó $205bn.

Ní December, Ethiopia kó sí ìyọnu látara pé ìjọba kọ̀ láti dá gbèsè mílíọ̀nù mẹ́tàlélọ́gbọ̀n dọ́là nínú bílíọ̀nù dọ́là tí wọ́n gbà ní Europe àti IMF padà. Ethiopia ń bá IMF sọ̀rọ̀ láti bèèrè fún owó láti mú àyípadà bá ètò ọrọ̀ ajé wọn.

Ethiopia tó ń kojú ogun ní agbègbè Tigray láti bí ọdún méjì àti àdínkù owó tí wọ́n ń pa wọlé ṣokùnfà kí àwọn ará ìlú máa kojú ìṣòro.

Pẹ̀lú bí ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Ethiopia ṣe ní ọ̀wọ́n gógó tó ń bá orílẹ̀ èdè náà fínra dínkù sí ìdá 23.3 ní oṣù kẹrin láti 33.5 síbẹ̀ àwọn ènìyàn kò rí owó rà oúnjẹ.

Ṣáájú ni Orílẹ̀ èdè náà ń jẹ àǹfàní àìní san owó orí àwọn ọjà tí wọ́n bá rà ní Amẹ́ríkà lábẹ́ ètò Africa Economic Development and Opportunities Act.

Ṣùgbọ́n ètò náà wá sópin ní December 2021 látàrí ogun tó ń wáyé ní Tigray.

Láti ìgbà náà, gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde United Nations Economic Development Agency, UNDP, àwọn iléeṣẹ́ 450 ni kò ṣiṣẹ́ lórílẹ̀ èdè náà mọ́, tí àwọn míì sì ń ṣe ìdá ọgbọ̀n nínú ìdá ọgọ́rùn-ún tó yẹ kí wọ́n máa ṣe.