Èsí àyẹ̀wò òkú Mohbad kò tẹ́ mí lọ́rùn, mo fẹ́ tún àyẹ̀wò òkú ọmọ mi ṣe - Bàba Mohbad

Oríṣun àwòrán, Mohbad/Instagram
Latigba ti esi ayẹwo lati mọ iru iku to pa gbajugbaja olorin takasufee nni to ku lasiko ti ogo rẹ n buyọ, Ilerioluwa Alọba ti jade ni oriṣiriṣi awuyewuye ti n lọ kaakiri ori ikanni ayelujara.
Bi awọn kan ṣe n sẹ sọ ejo lọwọ ninu, bẹẹ lawọn miran n sọ pe boya nitori ti wọn ti tete sin oku naa ni esi ayẹwo ko ṣe iru iku to pa Ilerioluwa ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Mohbad.
Oriṣiriṣi awuyewuye to n lọ nigboro yii lo mu ki BBC YORUBA kan si baba oloogbe naa, Ọgbẹni Joseph Alọba lati mọ boya esi ayẹwo ọhun tẹẹ lọrun tabi ko tẹẹ lọrun.
Ṣugbọn nigba to n ṣalaye, Ọgbẹni Joseph Alọba jẹ ko di mimọ pe oun ko nigbagbọ kankan ninu esi ayẹwo naa ti wọn gbe jade.
O ni ko ṣee ṣe ki esi ma jade lori ayẹwo, lai nii ṣe bo tilẹ pẹ to, ṣugbọn to sọ pe oun ṣetan lati na owo lori ayẹwo miran.
Bakan naa ni Ọgbẹni Alọba sọ pe irọ to jinna si otitọ ni iyawo ọmọ oun tẹlẹ naa, Wunmi n pa mọ oun kaakiri wi pe oun mọ nipa bi wọn ṣe tete sinku Mohbad, ọmọ oun.
Ninu ọrọ rẹ, o ṣalaye pe “Mo ni awọn ohun ti mo fẹẹ sọ sita nipa ohun to n ṣẹlẹ yii, akọkọ ni bi wọn ṣe gbe oku ọmọ mi si mọṣuari, eyi ti Darosha ṣe, ẹlẹẹkeji ni lori esi ayẹwo to jade sita laipẹ yii.
“Wọn ti ṣe ayẹwo lati mọ iku to pa Mohbad, esi ayẹwo naa si ti jade. Gẹgẹ bi mo ṣe gbọ nipa esi ayẹwo naa, ko tẹ mi lọrun rara, bẹẹ ni ko tun tẹ gbogbo ẹbi ati aye lọrun.
“Awa naa fẹẹ ṣe ayẹwo aladani ti wa lati mọ iru iku to pa Ilerioluwa. A ti kọwe sile ẹjọ lati gba aṣẹ fun un, aṣẹ lati ṣe ayẹwo tiwa la n duro de bayii ko to di pe a lọ ṣe e.
“Ohun ti mo fẹ ki gbogbo aye gbọ lasiko yii ree, nitori pe mi o gbọdọ di ẹnu lori rẹ. Ayẹwo aladani ti awa ba ṣe lo maa jẹ ka fọkanbalẹ.”
Bi esi ayẹwo ọhun ko ṣe tẹ mi lọrun naa ni ko tẹ gbogbo aye lọrun
Baba Mohbad tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe “Bi esi ayẹwo yẹn ko ṣe tẹ mi lọrun naa ni ko tẹ gbogbo aye lọrun. Ṣugbọn a ni lati gba aṣẹ lati ile-ẹjọ pe ohun ti a fẹẹ ṣe ree, ti a ba si ti gba aṣẹ, iṣẹ ti bẹrẹ naa niyẹn.
“Awọn to ṣe ayẹwo naa ko fi falẹ rara, ṣugbọn nitori awọn ohun ti a n duro de, ni ko tii jẹ ka lọ gbe oku naa kuro nibi to wa.
“Idi ti wọn fi lọ wu oku Mohbad ni lati mọ iru iku to pa a, ṣugbọn pẹlu esi to jade, o tunmọ si pe wọn ko ri pato nnkankan nipa ohun to ṣeku pa a.
“Emi si mọ pe a gbọdọ mọ iru iku to ku, ohun ti a fẹẹ ṣiṣẹ le lori niyẹn.
“Ninu isọrọsi Wunmi, o sọ pe emi ni ko jẹ ki wọn ri esi ayẹwo ti wọn ṣe, o ni mo tete sare lọ sin in. Alaye ti mo fẹ ṣe ni pe nigba ti wọn nilo iwe dokita lati gbe oku rẹ lọ si mọṣuari.
“A pada lọ si mọṣuari loru ọjọ yẹn, to ba jẹ pe wọn ri iwe dokita, bi a ko tiẹ ri iwe ọlọpaa, o ṣee ṣe ki wọn gba oku naa si mọṣuari.
Wunmi ni olori ẹni to jẹ ki wọn tete sin Mohbad
“Wunmi to mu iwe dokita dani, ko mu silẹ, eyi ni ko jẹ ki wọn gba oku ọmọ mi, Mohbad si mọṣuari. Mo fẹ ki gbogbo agbaye mọ wi pe Wunmi gan-an ni olori ẹni to jẹ ki wọn tete lọ sin Mohbad.
“Kani wọn gba oku yẹn si mọṣuari ni, ko ni si wi pe wọn n kanju lati sin in loru yẹn. Gbogbo araye lo ti mọ pe onirọ ni Wunmi.
“O sọ pe oun ko mọ ibi ti wọn gbe ọkọ oun lọ, ẹ beere pe bawo lo ṣe ṣeto aṣọ to fẹẹ fi sin oku. Mo fi silẹ si mọṣauri ni, nitori pe a jọ debẹ ni.
“Awọn ni wọn ṣeto gbogbo bi wọn ṣe ra posi ati awọn nnkan ti wọn lo, mi o le fi oju rii gẹgẹ bi ọmọ si mi, awọn nnkan wọnyi ni mo fẹ ki gbogbo aye mọ ohun to ṣẹlẹ gangan.”















