Ó wù mí kí n pẹ́ láyé àmọ́ owó oògùn ti wọ́n jù – Àwọn aláìsaǹ ké síta látàrí bí oògùn ṣe gbówó lórí

Devalued currency and currency fluctuation in Nigeria have caused medication prices to soar leaving many patients unable to afford their treatments

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Makuochi Okafor & Chigozie Ohaka
    • Role, BBC News
    • Reporting from, Lagos, Nigeria

Bi owo oogun ṣe gbowo lori ni Naijiria ti n mu inira ba ọpọ eeyan, paapaa awọn to n ṣaisan tabi ti wọn ni eeyan sile iwosan.

Laarin oṣu diẹ sẹyin, owo awọn oogun to wọnpọ lo ti gbowo ni ilọpo meji tabi ilọpo mẹta, eyii to n mu ko ṣoro fun awọn alaisan lati ri itọju to peye.

Lapapọ, nnkan ti gbowo lori ni Naijiria ni nnkan bii ida 33%, eyii to buru julọ lati ọgbọn ọdun sẹyin.

Minisita eto ilera Naijiria, Muhammed Ali Pate, sọ fun BBC pe bi owo naira ṣe n ṣe segesege si owo dọla lo fa a ti oogun fi wọn nitori pe ṣe ni wọn n ko pupọ ninu rẹ wọle lati ilẹ okere.

O fi kun pe awọn araalu tun kọ lati forukọsilẹ fun eto adojutofo ilera ijọba lo jẹ ki wọn maa ra oogun ni owo gọbọi.

Ẹwẹ, ijọba ti kede awọn ọna ti yoo gba ti owo oogun yoo fi lọ silẹ.

Lara awọn ọna naa ni mimu irọrun ba bi awọn ileeṣẹ to n po oogun yoo ṣe maa ko awọn eroja ti wọn fi n po oogun wọle lati oke okun.

Rhoda Husseini, a single mother of four, can't afford asthma drugs anymore and has turned to using traditional herbs instead.

'Agbo ni mo n lo bayii'

Lọwọ yii, awọn ọmọ Naiiria bii Jane Aibangbe, to jẹ ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ko le ra oogun mọ nitori pe o ti gbowo lori.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Aisan ‘systemic lupus erythematosus’ ni Jane n ba finra, eyii to maa n mu ki agọ ara rẹ rẹwẹsi.

Laarin ipari ọdun 2023 si ibẹrẹ ọdun 2024, iye owo ti Jane n ra oogun ti fo lati N21,000 si N35,000.

O ni “inu mi ko dun rara amọ ki ni mo fẹ ṣe bayii?

Ni ti Sarah Erekosim, to jẹ ẹni ọdun mejidinlọgbọn to n ba aisan ‘asthma’ finra fun ọjọ pipẹ, o ti yi igbeaye rẹ pada lati maa ṣọra fun oun to le ṣe ipalara fun latari aisan naa.

Sarah ni “omi gbigbona ni mo n mu bayii dipo omi tutu pẹlu oru to wa niluu Eko yii.”

Iye owo oogun rẹn ninu oṣu karun un, ọdun 2023 jẹ N9,000, amọ oogun naa ti di N67,000 bayii.

O ni “Mo mọ pe ọrọ ilera mi la n sọ yii mo si fẹ pẹ laye, amọ lootọ ni oogun naa ti gbowo lori gidi.”

Dokita kan niluu Eko, Uche Tralagaba sọ pe bi awọn alaisan ti oun n tọju ko ṣe le ra oogun wọn mọ n kọ oun lominu.

Dokita naa ni bi gbogbo nnkan ṣe gbowo lori ko jẹ ki awọn eeyan kọbi ara si eto ilera wọn mọ.

O ni “awọn kan ti kọ lati gba isinmi lẹnu iṣẹ bo tilẹ jẹ pe ko yẹ ki wọn maa ṣiṣẹ lapọju amọ wọn kọ eti ikun si amọran dokita wọn.”

Aarẹ ẹgbẹ awọn to n ta oogun ni Naijiria, Cyril Usifoh sọ pe ijọba ni lati din iye owo ori awọn to n ko ogun wọle n san ku.

The Nigerian government says it is improving health insurance to cover more people and is working to reduce reliance on imports, which will help lower drug costs.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ki ni ijọba n ṣe?

Ni ibẹrẹ ọdun yii, minisita eto ilera, Muhammed Pate kede erongba Aarẹ lati mu adinku ba iye owo oogun.

O tun ṣalaye pe ijọba yoo gbe owo ti iye rẹ to N1.3b si ẹka eto ilera lọna ati pese eto ilera to peye faraalu.

Ọdun 1999 ni ijọba ṣagbekalẹ eto ilera adojutofo, NHIS, to si bẹrẹ isẹ lẹkunrẹrẹ lẹyin ọdun kẹfa.

Ṣugbọn iwọnba eeyan kereje lo n janfani eto naa, ti pupọ ninu wọn si jẹ oṣiṣẹ ijọba.