Ìwé ìròyìn UK kan ní wọ́n ti dájọ́ ẹ̀wọ̀n ogún ọdún fún Oluwo rí l'Amẹ́ríkà tórí ìwà ọ̀daràn, Kábíyèsí fèsì

Aworan Oluwo

Oríṣun àwòrán, emperortelu1/Instagram

Oluwo tilu Iwo nipinlẹ Ọṣun, Ọba AbdulRọsheed Adewale Akanbi, Telu kinni ti sọ pe oun ko ni nnkankan lati sọ lori iroyin kan ti Daily mail iwe iroyin ori ayelujara ilẹ Gẹẹsi sọ pe wọn le kabiesi naa kuro lorilẹede Amẹrika nigba meji ọtọtọ tori iwa ọdaran.

Iroyin yii jade lẹyin abẹwo Ọmọọba ilẹ Gẹẹsi, Harry ati aya rẹ, Meghan Markle si Naijiria.

Kabiyesi ni gbogbo ọna lati bu ẹnu ẹtẹ lu abẹwo naa ni awọn oyinbo ilẹ Gẹẹsi n wa, ṣugbọn to ni iyẹn ko le ṣee ṣe rara.

Bakan naa ni ọba alaye naa sọ pe ohunkohun to le wu ki awọn oyinbo maa ba Ọmọọba Harry fa, ọrọ inu ile wọn niyẹn, wọn si mọ bi wọn yoo ti pari rẹ laarin ara wọn, iyẹn ko kan oun.

Ki lo ṣẹlẹ gan an?

Laipẹ yii ni iwe iroyin Daily Mail gbe iroyin kan jade, nibi ti wọn ti n bu ẹnu atẹ lu abẹwo Ọmọba Harry ati aya rẹ si Ọba Akanbi.

Ninu iwe iroyin naa, wọn ni itiju nla lo jẹ nigba ti Ọmọọba Harry n pe Oluwo ni ọkan ninu awọn ana rẹ.

Iwe iroyin naa tun sọ pe iwa ọdaran ni wọn fi le e kuro nilẹ Amẹrika lẹẹmeji ọtọọtọ, koda ti wọn tun ju sẹwọn ogun ọdun.

Iwe iroyin Daily Mail tun sọ pe ko yẹ ko jẹ iru Ọba Oluwo ti awọn araalu, paapaa awọn ọmọ ilu naa to n gbe lẹyin odi n pe fun iyọnipo rẹ loun yoo lọ darapọ lati ba a ni ajọṣepọ.

Lara awọn ohun ti iwe iroyin naa tun sọ nipa Oluwo ni pe o lu jibiti nipa ṣiṣe ayederu iwe sọwedowo to jẹ Poun mẹtadinlaadọtalenigba (£247,000), ti wọn si ni Oluwo funra rẹ bẹbẹ pe loootọ loun jẹbi ẹsun naa.

Wọn ni ẹwọn ogun ati owo itanran ọtadinigba poun (£197,000) ni ile-ẹjọ fun Oluwo.

Iwe sọwedowo ọhun ni wọn lo jẹ ti ọkunrin kan, Joseph Pigott ti Oluwo pe ara rẹ lo fẹ lọ gba nile ifowopamọ BankBoston.

Gbogbo nnkan to ba wu ki wọn maa sọ, ko si nnkan to kan awa - Oluwo

Aworan Oluwo

Oríṣun àwòrán, emperortelu1/Instagram

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹwẹ, Kabiesi Oluwo ti fesi si gbogbo nkan ti iwe iroyin Daily Mail kọ nipa rẹ.

Oluwo ni iroyin naa da lori ọna lati bu ẹnu ẹtẹ lu abẹwo Ọmọba Harry si orilẹede ni Naijiria.

“Ẹ fẹ bu ẹnu atẹ lu abẹwo ti Harry ati iyawo ẹ ṣe si ilẹ Yoruba ni, eyi to si pọn wọn le gẹgẹ bi ọmọọba.

Ọmọọba ni awa mọ Harry ati iyawo rẹ si, a si pọn wọn le gidi nigba ti wọn wa.

A tun fun wọn ni orukọ to dara, orukọ Adetokunbọ ni wọn n jẹ.

Wọn pe ilẹ Yoruba ni ilẹ mama oun, o tumọ si pe wọn fun ni orukọ.

Ija to ba wu ki awọn ile ọba ilẹ Gẹẹsi maa ba ara wọn ja, ko kan awa, wọn le pari rẹ laarin ara wọn, ju ki wọn wa fẹẹ ba abẹwo naa jẹ lọ.

Abẹwo nla ti agboole ọba ni, a si nifẹ rẹ gidigidi. Gbogbo igba to ba ti n wa ni a ma maa gba a lalejo nla. A si dupe pe nnkan ti awọn ko ṣe ni Harry ṣe yii.

“Harry ti lọ soju ogun ni Afghanistan ri, to si jagun fun ilu rẹ.

Ọlọrun ni ko jẹ ko ṣiṣe, nnkan toun wa ṣe ni Naijiria ni lati mu koriya fun awọn ọmọ ogun, ki wọn le tubọ maa tẹpa mọ iṣẹ.

“Lati mu inu awọn ọmọ ogun to jẹ pe wọn ja fun ominira ilẹ Yoruba ati Naijiria lapapọ, ati agbaye.

Awọn ti wọn farapa, ti wọn si ni aleebu lara ni Ọmọọba Harry ronu nipa wọn lati maa bu ọla ati iyi fun.

“O fi n dupẹ lọwọ Ọlọrun ni. Gbogbo nnkan to ba wu ki wọn maa sọ, ko si nnkan to kan awa, nitori pe a ti mọ wọn.

“Gbogbo ẹnu atẹ ti wọn ba fẹẹ bu luu, ko le jẹ Harry ati Meghan. Awa nifẹẹ wọn pupọ, a o si maa nifẹ wọn titi lai ni, nitori pe nnkan ti wọn gbe lọwọ yẹn, awa ko nii jẹ ki aimọkan awọn eeyan yin ni UK ba abẹwo naa jẹ.

“Ọbakọba to ba wa gan-an ko le ba abẹwo naa jẹ. Wọn ti rii wi pe a tun lo anfaani abẹwo naa lati gbe Yoruba ga ni, a ko si ni jẹ ko bajẹ.

“Aṣa ati iṣẹ Yoruba nikan ni emi maa n gbe ga, ohun ti mio kii ba wọn gbe ga ni ibọriṣa nitori pe awọn baba ti wa, wọn ko bọriṣa.

“Awa ko nii ba wọn da si iroyin ti wọn n gbe jade yẹn, ile-ẹjọ ni awa maa n lọ to ba ti di ni iru nnkan bẹyẹn.

Mi o si ni ohunkohun lati sọ bi ko ṣe pe wọn fẹẹ ba abẹwo Harry ati Meghan jẹ ni.

“Awa ko sii ni gba ki wọn ba a jẹ nitori pe a ti gbe aṣa Yoruba ga lati ibẹ.

Abojuto awọn ologun ti wọn farapa loju ogun ni wọn wa ṣe.

“Wọn ti bi Harry ni Ọmọọba, ẹ ko si le yọ ọ kuro nibẹ, ko ṣee ṣe.”