Ta ni Christian Malanga tó ṣagbátẹrù ìdìtẹ̀gbàjọba tó foríṣánpọ́n ní DR Congo?

The Congolese Republican Guard and police block a road around the scene of an attempted Coup in Kinshasa on May 19, 2024.

Oríṣun àwòrán, AFP

    • Author, Khadidiatou Cissé
    • Role, BBC News

Ọkan awọn eeyan ko balẹ mọ ni DR Congo bayii lẹyin iditẹgbajọa kan to ku diẹ ko wayenibẹ laarin ọjọ diẹ sẹyin.

Ọgagun Sylvain Ekenge, to n gbẹnusọ fun ileeṣẹ ọmọ ogun DR Congo sọ pe lọjọ kọkandinlogun oṣu Karun un, ọdun 2024 yii ni awọn kan ti wọn wọ aṣọ ologun kọlu ọọfisi Aarẹ.

Awọn eeyan naa tun kọlu ile olori oṣiṣẹ ijọba tẹlẹ, Vital Kamerhe, to jẹ ọrẹ timọtimọ Aarẹ to wa lori oye.

Wayi o, ijọba ti fi ṣikun ofin mu aadọta eeyan si atimọle, ninu eyii ti ọmọ ilẹ Amẹrika wa ninu wọn.

Ọpọ eeyan nilẹ naa lo gbagbọ pe awọn ọmọ ogun lati orilẹede Congo lo wa nidi iṣẹlẹ naa.

Amọ lẹyin ikọlu ọhun lo han gbagba pe Christian Malanga, to jẹ olori ẹgbẹ alatako Aarẹ Félix Tshisekedi lo wa nidi iṣẹlẹ naa.

Lamanga farahan ninu fidio kan, nibi to ti fi ọrọ ranṣẹ si Aarẹ Félix Tshisekedi pe “Felix, akoko rẹ ti tan. A n bọ wa kogun ja ọ.”

Iwaju ile aarẹ DR Congo ni Kinshasa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ile Aarẹ DR Congo

Ilu Kinshasa ni wọn ti bi Christian Malanga amọ idile rẹ fi orilẹede Congo silẹ lọ si Swaziland ki wọn to tun tẹkọ leti lọ si Salt Lake City, ni Utah, lọdun 1998.

Lẹyin to pari ile ẹkọ mẹwaa nilẹ Amẹrika, o ṣiṣẹ gẹgẹ bii oniṣowo kereje, bakan naa lo tun da ajọ ti kii ṣe ti ijọba, Africa Helpline Society, silẹ.

Lọdun 2006, o pada si DR Congo nibi to ti ṣiṣẹ ologun, lẹyin naa lo da ileeṣẹ Malanga Congo silẹ.

Ni 2011, o darapọ mọ oṣelu nibi to ti dije fun ipo aṣofin amọ ọlọpaa mu ṣaaju eto idibo, o si lo ọpọlọpọ ọsẹ ni atimọle.

Lẹyin ti wọn tu silẹ ni ahamọ, Malanga kọ ipo olori ọdọ ti ijọba fi dọla, o si lọ da ẹgbẹ oṣelu tirẹ silẹ.

Lọdun to tẹle, o pada silẹ Amẹrika lati da ẹgbẹ United Congolese Party (UCP), silẹ lati ko awọn ọmọ orilẹede naa to wa lokere jọ.

Lọdun 2017, won fun ni oye Grand Cross nile ijọsin Kingdom of Saint Peter and Paul ni Vatican.

Aarẹ Felix Tshisekedi DR Congo

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Ọdun 2019 ni Félix Tshisekedi di Aarẹ DR Congo

Ẹwẹ, aṣoju ilẹ Amẹrika si DR Congo tẹlẹ, Lucy Tamlyn ti sọ pe o jẹ ohun iyalẹnu pe ẹni to jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika le maa gbimọpọ lati gbajọba lọna aitọ.

O ni “A fẹ ko da yin loju pe a o ṣiṣẹ papọ pẹlu ijọba DR Congo lati ṣe iwadii iwa ọdaran yii ki a si fi imu ọmọ ilẹ Amẹrika to wa ninu wọn danrin.”

Aarẹ Tshisekedi ko tii sọ ọrọ kankan nipa iṣẹlẹ naa titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ.

Oṣu Kejila ọdun to kọja ni wọn dibo yan Aarẹ naa fun saa keji.

Ninu oṣu Kẹrin ọdun yii, wọn yan onimọ nipa eto ọrọ aje Judith Tuluka gẹgẹ bii obirin akọkọ sipo adari ijọba.