Wo ọ̀pẹ abàmì tó lórí tó lé lógójì ní Ilogbo Ekiti 'tó ń dáhùn ádurà' àwọn èèyàn

Bẹẹ ba n gbọ Ọpẹ Umalẹ, Ọpẹ olori yeye, ẹ ma sa lọ, ẹyinkunle yin nibi lo wa o.
Kayeefi BBC ti oṣu yii gbe wa lọ si inu igbo aramanda kan to wa ni ilu Ilogbo ni ipinlẹ Ekiti nibi ti igi ọpẹ to ni ori to le ni ogoji wa.
Awọn ara ilu naa sọ fun akọroyin Kayefi BBC Yoruba pe awọn gbagbọ pe igi abami yii ti wa ko tilẹ to di pe wọn tẹ ilu naa do ni ọpọlọpọ ọdun sẹhin.
O le lati gbagbọ amọ iṣẹ aramanda ọwọ Eledumare to fi ṣa sababi fun wa ni Ilogbo ni. Kabiyeis Owalogo ti ilu Ilogbo Ekiti sọ bẹẹ.
Nibayii igi naa ti di Ooṣa pataki ni ilu Ilogbo Ekiti gẹgẹ bi awn agba awo ṣe sọ pe awọn ti awọn tẹ ilu naa do gan baa nibẹ ni.
"Beeyan n jiya ọmọ, to ba de ibẹ, yoo ri ọmọ bi".
Awọn eeyan ilu Ilogbo ti wọn ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye wi pe ko si ohun ti eeyan ba beere nibi ọpẹ yii ti ẹni naa ko ni ri idahun si..

Wọn ni bi awọn ṣe n tọju ọpẹ yii ni oun naa n tọju awọn araalu Ilogbo.
Awọn eeyan ilu Ilogbo sọ pe ọpẹ yii n mu ilọsiwaju ba awọn eeyan ilu naa.
Awọn eeyan yii gbagbọ pe ọpẹ yii ti wa lati igba iwasẹ ki ilu Ilogbo gan an to wa.
Nnkan mii to tun jẹ abamọ nipa ọpẹ yii ni pe ki i so ẹyin, ikin lo maa n so.
Ikin yii ṣi lawọn babalawo maa n lo fun ifa dida.
Koda, wọn ni ẹẹkan logun ọdun ni ọpẹ yii maa n so ni ogun ọdun.
Amọ, eewọ ọpẹ yii ni pe obinrin ko gbọdọ de idi ọpẹ olori yeye yii.
Bakan naa ẹni to ba jẹ ẹpa ko gbọdọ de idi ọpẹ yii















