Bánkì CBN wọ́gilé yíyọ owó orí 0.5% nínú àkáùntì ọmọ Nàìjíríà fún àbò lórí jìbìtì orí ayélujára

Ọga agba banki apapọ Naijiria, Olayemi Cardoso

Oríṣun àwòrán, @Dryemicardoso/X

Àkọlé àwòrán, Ọga agba banki apapọ Naijiria, Olayemi Cardoso

Banki apapọ orilẹ-ede yii (CBN) ti wọgile ofin to ṣẹ tẹlẹ pe ki awọn banki maa yọ owo ori aabo lara awọn onibaara lori ayelujara.

Irọlẹ ọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlogun oṣu karun-un ọdun 2024 yii ni CBN fi atẹjade to kede ayipada ofin naa sita .

Chibuzor Efobi ati Haruna. B. Mustafa ti wọn n ri so owo sisan ati ilana rẹ ni banki naa ni wọn buwọ lu atẹjade ọhun.

Wọn si fi ranṣẹ si awọn banki gbogbo.

Kì ló ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú?

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹfa oṣu karun-un ọdun 2024 yii ni banki agba ilẹ wa kede pe oun yoo maa yọwo ori aabo lara idunaa-dura ori ayelujara.

Wọn ni eyi ko yọ awọn oniPOS silẹ, gẹgẹ bo ṣe kan awọn banki kaakiri ilẹ yii.

Wọn fi kun un pe awọn onibaara to ba ti n gbowo tabi ṣowo lori afẹfẹ yoo maa fara gba a owo naa fun aabo wọn ati fun imugbooro okoowo ori ayelujara.

’’Ida 0.5 ni wọn ni wọn yoo maa yọ gẹgẹ bii owo aabo yii, ẹka ‘National Cyber Security Fund’’ ni owo ọhun yoo maa bọ si.

Ọfiisi to n gba wọn nimọran lori aabo (National Security Adviser) ni yoo si maa ṣakoso rẹ bi wọn ṣe sọ.