Ẹgbẹ́ àwọn dókítà NMA sàlàyé ìdí táwọn dókítà kò fi pọ̀ mọ́ ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Image
Bi awọn eeyan ṣe n fi orilẹ-ede Naijiria silẹ ti wọn n japa lọ siluu oyinbo ki i ṣe nnkan tuntun mọ.
Bẹẹ lo si tun jẹ pe gbogbo ẹka iṣẹ pata ni jijapa naa ti n ṣẹlẹ. Ṣugbọn ti ẹka to foju han ju ni ti awọn dokita oyinbo.
Kedere lo han pe ọpọ dokita lo ti fi Naijiria silẹ lọ si oke okun, bẹẹ lawọn mi-in si n tun n palẹmọ ati lọ bayii.
Ṣugbọn yatọ si pe ọrọ aje Naijiria ko ṣe daadaa lati igba pipẹ sẹyin wa, pẹlu ai ri ẹtọ to yẹ gba ti awọn dokita n tori ẹ fi orilẹ-ede yii silẹ, ajọ Nigerian Medical Association (NMA) to n ri si ọrọ awọn dokita ti ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ gan-an.
Kí ni NMA wí?

Oríṣun àwòrán, Getty image
Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria, Ọjọgbọn Bala Audu, ṣalaye fun BBC pe ni 2023, o fẹrẹ to ẹgbẹrun lọna aadọta dokita (50,000) ti wọn ṣe isọdọtun iwe iṣẹ wọn.
’’Isọdọtun iwe iṣẹ naa ni yoo jẹ ki wọn le ṣiṣẹ nile iwosan, ẹni ti ko ba ṣe tiẹ ko le da alaarẹ lohun.
Audu ni ’’O to ẹgbẹrun lọna aadoje (130,000) dokita ta a ni ni Naijiria, ninu wọn ni 50,000 pere ti ṣe isọdọtun iwe ẹri wọn yẹn.
’’Eyi tumọ si pe awọn to ku ti wọn ko ṣe tiwọn le ti pa iṣẹ da. Wọn le ma ṣiṣẹ dokita mọ, tabi ki wọn ti japa bii awọn yooku wọn.’’
Àṣekú iṣẹ to le gba ẹmi eeyan, to bẹẹ ti dokita kan ku sẹnu iṣẹ laipẹ yii, tun jẹ idi kan ti dokita ko fi pọ ni Naijiria mọ bo ṣe wi.
O ni wakati mẹrinlelogun to n bẹ ninu ọjọ ni awọn dokita ilẹ yii fi n ṣiṣẹ, ti wọn n da alaisan lohun ju iye asiko ti ajọ eleto ilera agbaye ni ki wọn maa fi tọju wọn lọ.
Bẹẹ, ẹkunwo ko ba owo oṣu awọn dokita yii, iṣẹ wulẹ n pọ si i lai si owo ni.
’’Dokita kan ṣoṣo yoo da ẹgbẹrun mẹfa alaisan (6,000) lohun ni Naijiria, ẹgbẹta (600) eeyan ni si ni ajọ eleto ilera agbaye ni ki dokita kan ṣoṣo da lohun.
Wọn n ṣiṣẹ ilọpo mẹwaa ohun to yẹ ki wọn ṣe.
‘’Awọn nnkan wọnyi n ṣakoba fun ẹmi awọn dokita Naijiria funra wọn, o si n fa ijafafa wọn sẹyin.
‘’Àṣekú iṣẹ to pa dokita kan laipẹ yii niyẹn. Awọn ohun ti ko jẹ ki dokita pọ lorilẹ-ede yii mọ niyẹn’’
Pẹlu alaye Aarẹ NMA yii, awọn araalu tun n rawọ ẹbẹ sijọba lẹẹkan si i ni.
Wọn ni ki wọn dahun si iṣoro to n ṣẹlẹ lẹka ilera yii, nitori alaafia araalu ti wọn n ṣejọba le lori ṣagba ohunkohun.














