Mọ̀ nípa àìsàn ABS tó máa ń jẹ́ kí èèyàn ṣe bí ọ̀mùtí láì mu ọtí

Ray Lewis, ìyàwò rẹ̀, Sierra, àti ajá Mia

Oríṣun àwòrán, Ray Lewis

Àkọlé àwòrán, Labradoodle Mia ń ran Ray Lewis láti mójútó ABS
    • Author, Fernando Duarte
    • Role, BBC World Service

Ọkùnrin ara Belgian kan ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ gba orí ayélujára lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ da láre pé kò jẹ̀bi ẹ̀sùn pé ó múti kó tó wa ọkọ̀ tó sì ń sáré ju iye tí ó yẹ kó máa wà lójú pópó lọ.

Pẹ̀lú àtìlẹyìn àwọn onímọ̀ ìlera, ọkùnrin ẹni ogójì ọdún náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ ní ilé ẹjọ́ pé òun ní àìsàn kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ “Auto-Brewery Syndrome”, ABS.

Àìsàn ABS yìí máa ń kí ara máa pèsè ọtí fúnra rẹ̀ láì ṣe pé ẹni náà fi ẹnu kan ọtí.

Kí ni ABS? Àti pé báwo ni ajá ṣe wúlò fún ṣíṣe àmójútó rẹ̀?

Nígbà tí Ray Lewis lajú ní ilé ìwòsàn ní Orego, orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà méjì ló dáa lójú. Àkọ́kọ́ ni pé ó mọ̀ pé òun ti wọ wàhálà fún fífi ọkọ̀ tí òun fi kó ààyè ẹja ẹgbẹ̀rún mọ̀kánlá tó jẹ́ ti iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹja àti àwọn ẹranko inú igbó níbi tó ti ń ṣiṣẹ́.

Èkejì ni pé òun kò fẹnu kan ọtí ní ọjọ́ tí ìjàmbá náà wáyé lóṣù Kejìlá ọdún 2014 bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àyẹ̀wò tí iléeṣẹ́ ọlọ̀pàá ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọtí pọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

Ó ní òun kò lè mú ọtí nígbà tí òun ti mọ̀ pé òun máa wa ọkọ̀ fún wákàtí méjì nínú òtútú àti ọ̀nà tí gbogbo rẹ̀ kún fún yìnyín.

Oṣù mẹ́jọ lẹ́yìn ìjàmbá ọkọ̀ náà, àwọn dókìtà ní Ray Lewis ní àìsàn ABS, tí wọ́n sì ní ara rẹ̀ ló mu kí ó yó.

(A social media post from US TV channel Fox 13 Seattle shows the wreck following Ray's crash in 2014.)

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Kí ni ABS?

ABS jẹ́ àìsàn kan tí kò ṣe é ṣàlàyé tó máa ń lé kún iye ọtí tó wà lára ènìyàn, tó sì máa ń jẹ́ kí ènìyàn ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ bí ẹni tọ mutí kódà tí ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá fẹnu kan ọtí rárá.

Ó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí kòkòrò àìfojúrí tó wà nínú ènìyàn, ilé ìtọ̀ àti ẹnu bá ń sọ àwọn oúnjẹ àti ṣúgà ara di ọtí.

Ó le fa kí èèyàn máa ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ tó bá ń rìn, àìlè sọ̀rọ̀ dáadáa bí ẹni tó bá mu ọtí.

Ní nǹkan bíi ọdún 1940 ni àwọn dókítà kọ́kọ́ ṣàwárí àìsàn yìí ní orílẹ̀ èdè Uganda nígbà tí ṣàgbéjáde èsì àyẹ̀wò òkú kan nínú àtẹ̀jáde British Medical Journal. Ọmọ ọdún márùn-ún ni ọmọ náà tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ àìsàn inú kan tí wọ́n sì ri pé òórùn ọtí sì ń jáde láti inú rẹ̀ lásìkò tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ abẹ fún-un.

Àwòrón kòkòrò àìfojúrí fungus Saccharomyces cerevisiae

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ta ni àìsàn ABS le mú?

ABS jẹ́ àìsàn tí kò wọ́pọ̀ rárá. Ìwádìí kan tí wọ́n gbé jáde nínú àtẹ̀jáde Amẹ́ríkà Journal of Gastroenterology lọ́dún 2021 ní wọn kò ì tíì ṣàwárí ju ọgọ́rùn-ún àìsàn yìí lọ ní Amẹ́ríkà, àmọ́ àwọn onímọ̀ kan sọ pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé wọn ò ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ rẹ̀ tó bó ṣe yẹ ni.

Àwọn dókìtà kò ì tíì mọ ìdí tí àìsàn yìí ṣe máa ń mú àwọn èèyàn kan.

Ẹ̀yà ara ènìyàn máa ń pèsè ọtí díẹ̀ nínú mọ́ ìfun nígbà tó bá fẹ́ lọ oúnjẹ. Àmọ́ èyí kìí pẹ́ rárá tí ara fi máa gbọ̀n-ọ́n dànù kọ tọ wọ inú ẹ̀jẹ̀.

“Gbogbo èèyàn ló máa ń pèsè ọtí lára ṣùgbọ́n àwọn tó ní àìsàn ABS máa ń pèsè rẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu tó jẹ́ pé ó máa ń wọnú ẹ̀jẹ̀ wọn,” èyí ni àlàyé Dókítà Ricardo Jorge Dinis-Oliveria tó jẹ́ onímọ̀ nípa ‘biomedical’ ní orílẹ̀ èdè Portugal tó sì ti kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé lórí ìwádìí nípa àìsàn ABS.

Obìnrin kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

“Ohun tó burú níbi àìsàn yìí ni pé èèyàn kìí mọ̀ pé òun ní àìsàn yìí àyàfi tí àwọn àjálù ńlá bíi ìwà ọ̀daràn bá ṣẹlẹ̀ si.”

Ó pe àìsàn ABS ní èyí tí ọ̀pọ̀ nǹkan máa ń fà á kí ọtí náà máa pọ̀ lára. Ó ní ohun àkọ́kọ́ ni àìsàn ìtọ̀ ṣúgà, ara àsanjù tàbí àìsàn Crohn.

Ó ní nǹkan kejì jọ mọ́ àwọn oògùn tí ẹni tó bá ní àìsàn yìí lára bíi àwọn ògùn láti fi dènà àwọn kòkòrò àìfojúrí tó lè ní ipa lórí àwọn kòkòrò àìfojúrí àtàwọn ẹ̀yà ara tó wà nínú ìfun.

Kí èèyàn máa gbé pẹ̀lú ABS

Nígbà tí nọ́ọ̀sì ilẹ̀ Amẹ́ríkà, Joe Cordell bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ bí ẹni tó ti mú ọtí yó kó tó di pé ó dákú lọ lásìkò tí wọ́n ń ṣe ìdúpẹ́ nígbà tó ń jẹ oúnjẹ alẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀, ó ní òun rò pé òun ti jẹun jù ni.

Ó ní akẹgbẹ́ òun kan ní ilé ìwòsàn Texas tí àwọn ti jọ ń ṣiṣẹ́ ti ṣaájú fẹ̀sùn kan òun pé òun mu ọtí yó lẹ́nu iṣẹ́ – ìwà tó lè gba iṣẹ́ lọ́wọ́ òun.

“Wọ́n ní èémí òun ń rùn fún ọtí,” Cordell ẹni ọdún 75 ṣèrántí. “Àwọn èèyàn máa ń rò pé ọlọ́tí ni mí ni.

“Nǹkan tó máa ń tìmí lójú ni nítorí mo jẹ́ èèyàn kan tó fẹ́ràn iṣẹ́, tí mi ò sì ń pa iṣẹ́ jẹ fún ọjọ́ kan rí.”

Joe Cordell àti Barbara Cordell

Oríṣun àwòrán, Barbara Cordell

Àkọlé àwòrán, Barbara Cordell bẹ̀rẹ̀ ìpolongo àìsàn ABS lẹ́yìn tí wọ́n sọ fún wọn pé ọkẹ̀ rẹ̀, Joe ní àìsàn náà

Ní àwọn àsìkò kan ìyàwó rẹ̀, Barbara ní òun ń rò ó pé bóyá ọkọ òun fẹ́ràn ọtí àmupara.

Barbara t;i òun náà jẹ́ nọ́ọ̀sì ní ọ̀pọ̀ ìgbà lòun máa ń wá ilé láti wò bóyá ọkọ̀ òun ń kó ìgò ọtí pamọ́ síbì kan nítorí kò gbàgbọ́ lásìkò kan pé ọkọ òun kò máa mu ọtí àmupara.

“Mi ò kọ́kọ́ gba Joe gbọ́ láwọn àsìkò kan, mo máa ṣàmì sí àwọn igi ọtí tó bá ní nílé láti mọ̀ bóyá ó ń mu wọ́n lẹ́yìn.”

Joe ní yàtọ̀ sí bí àwọn èèyàn ṣe máa ń fi ẹ̀spun kan òun, ó ní bí òun kàn ṣe máa ń ṣàdédé ri pé òun ń ṣe bí ẹni tó ti mu ọtí yó máa ń kó ìdàmú bá òun.

Ó ní ó ṣe ìdàmú fún ara àti ọpọlọ òun.

Pizza tó ní àwọn iṣu díndín lórí

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Reducing carbohydrates can help control ABS

Ní ọdún 2010 ni wọ́n ṣàwárí pé Joe ní àìsàn ABS, ọdún mẹ́rin lẹ́yìn tó bẹ̀rẹ̀ sí ní àmì rẹ̀. Ojoojúmọ́ ló máa ń ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ láti fi mọ iye ọtí tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nígbà tó bá dé ibiṣẹ́.

Èyí lú mú Barbara dá ẹgbẹ́ Auto-Brewery Syndrome Advocacy and Research láti ṣe àtìlẹyìn fáwọn tó bá ní àìsàn ABS. Wọ́n ti ní tó ọmọ ẹgbẹ́ 850.

“A gbọ́ nípa bí àwọn dókítà ṣe máa ń lé àwọn tó ní àìsàn yìí lọ, pè wọ́n ní onírọ́, pé wọ́n ń parọ́ àìsàn tí kò ṣe wọ́n.”

Ó ní àwọn ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tó ti sọ pé àwọn kò ti mu ọtí mọ́ nígbà tí àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìwòsàn.

Joe ní ọtí máa ń wu òun mu nígbà gbogbo láwọn àsìkò kan, tóun sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wá ìwòsàn kíá àti pé òun kò fi ẹnu kan ọtí mọ́ láti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn.

Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣàwárí ABS àti ìtọ́jú rẹ̀?

Àwọn dókítà máa ṣe àyẹ̀wò láti mọ àwọn kòkòrò àìfojúrí tó wà nínú ẹ̀yà ara tó máa ń lọ oúnjẹ nínú èèyàn láti mọ̀ bóyá kòkòrò tó máa ń pèsè ọtí sára wà níbẹ̀.

Wọ́n tún máa ń ṣàwárí rẹ̀ nípa ṣíṣe àyẹ̀ wò gúlúkóòsì, wọ́n máa sọ fún èèyàn láti jẹ oúnjẹ tó èròjà carbohydrate púpọ̀ tàbí lá gúlúkóòsì láì tíì jẹ oúnjẹ kankan tẹ́lẹ̀.

Lẹ́yìn wákàtí díẹ̀, wọ́n máa ṣàyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ ẹni náà láti mọ̀ bóyá ó ní ọtí nínú. Kò ní sí ọtí dàbí alárà nínú ẹ̀jẹ̀ ẹni tí kò bá ní ABS àmọ́ ó máa wà tó sì máa pọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ẹni tó bá ní ABS.

Ray àti Mia ní ṣọ́ọ̀bù

Oríṣun àwòrán, Ray Lewis

Àkọlé àwòrán, Ray máa ń mú ajá Mia kiri gbogbo ibi tó bá ń lọ láti máa gba òórùn ara rẹ̀

Dókítà Dinis-Oliveria ní wọ́n le ṣe àmójútó ABS pẹ̀lú lílo àpapọ̀ àwọn ògùn kan àti jíjẹ àwọn oúnjẹ tí kò bá ní carbohydrate púpọ̀ pẹ̀lú lílo àwọn ògùn tó ní ṣe pẹ̀lú inú ìfun.

Èyí ló ti ń ran Joe lọ́wọ́ láti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn tí kò sì ní ìkọlù kankan mọ́.

Àmọ́ pẹ̀lú títẹ̀lé àwọn ìlànà yìí, àìsàn yìí ṣì máa ń da Ray láàmú àma kò wọ́pọ̀ bíi ti àtẹ̀yìnwá láti ọdún 2020.

Ó ti wá ọ́nà mìíràn láti ṣe àmójútó ara rẹ̀ pllú lílo ajá tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mia.

Ajá Labradoodle náà ni wan ti kọ́ láti máa gbọ́ òórùn ara Ray, tí yóò sì mọ̀ nígbà tí àyípadà bá ti bá kẹ́míkà kan lára rẹ̀ tó fi mọ́ tí ọtí bá ti fẹ́ máa pọ̀ lára rẹ̀.

Ajá náà yóò dúró síwájú Ray, yóò sì máa wò ó púpọ̀ nígbà tó bá ti ń gbọ́ òórùn tó yàtọ̀ lára rẹ̀.

“Mi ò kí ń lè jáde ṣáájú kí n tó ní Mia, ẹ̀rù máa ń bà mí pé kí ń ma lọ ṣe ara mi àtàwọn èèyàn míì léṣe.”

“Nígbà tí mo ní ìjàmbá ọkọ̀, ohun kan tó dùn mọ́ mi nínú ni pé èmi nìkan ni mo ṣèṣe, mi ò kọlu ẹnikẹ́ni.”

Àwọn tó ń fi igo ọtí lu ara wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn tó ní àìsàn ABS máa ń ní àmì àpẹẹrẹ bí àwọn tó mu ọtí

Ọ̀rọ̀ Ray kò dàbí ti àwọn mìíràn tí wọ́n máa gbà láyè láti tẹ̀síwájú pẹ̀lú ọkọ̀ wíwà nígbà tí wọ́n bá ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àìsàn ni wọ́n ní pá [waọn kọ́ ló mu ọtí àmupara.

Ó ní ó yé adájọ́ pé òun ni òun mọ bí ọtí ṣe dé ara òun.

“Ilé ẹjọ́ ms pé mo ní àìsàn, síbẹ̀ ilé ẹjọ́ pinnu pé èmi ni kí n jà fún ohun tó tọ́.

Òun àti ìyàwọ rẹ̀ Sierra ń pe ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn nítorí Ray pàdánù iṣẹ́ rẹ̀ lórí ẹjọ́ tó wà lọ́rùn rẹ̀ àti àìsàn ABS tó ní ṣùgbọ́n ó ní òun kò sọ ìrètí nù.