Usyk fẹ̀ṣẹ́ dárà sí Fury lójú láti gbadé ògo ẹ̀ṣẹ́ kíkàn lágbàáyé, Fury yarí pé òun lóun borí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Abẹṣẹku bi ojo ọmọ Ukraine n ni, Oleksandr Usyk fi ẹṣẹ dara si Tyson Fury loju lati gba ade ẹsẹ kikan lagbaaye.
Ninu awọn adajọ mẹta to wo ija naa, meji ninu wọn lo sọ wi pe Usyk lo bori ija ọhun nigba ti ẹyọkan ni Fury lo pegede pẹlu ami ayo 115-112, 114-113 for Usyk ati 114-113 fun Fury.
Igba akọkọ ree ti Fury, ẹni ọdun marunlelọgbọn yoo fidirẹmi ni bi ọdun mẹrindilogun to ti di ogbontagi ninu ẹsẹ kikan.
Fury to jẹ ọmọbibi orilẹede England yoo lanfani lati koju Usyk lẹẹkan si lọdun to n bọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Mo mọ pe Usyk gbiyanju amọ emi ni mo pegede julọ - Fury
Fury yarí lẹyin ti wọn kede Usyk gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu ija wọn to waye niluu Riyadh lorilẹede Saudi Arabia lalẹ ọjọ Àbámẹ́ta pe oun loun bori ina naa.
Fury ni "lootọọ ni Usyk pegede l'awọn ipele kan ninu ija wa, amọ, emi lo pegede julọ.
Ọkan lara idajọ to buru julọ ninu ẹṣẹ kikan leyi, ṣugbọn mo mọ pe mo maa pada bori.'
Ni bayii, Usyk ti gba bẹniiti WBC to wa lọwọ Fury, o si ti fi kun bẹniiti WBA, WBO ati IBF to wa lọwọ rẹ.
Usyk ẹni ọdun metadinlogoji ko tii fidirẹmi ri ni bii ọdun mẹẹdọgbọn ti o ti di ogbontagi abẹṣẹkubiojo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Mo dupẹ lọwọ ikọ mi fun ija yii.
Anfani nla ni eyi jẹ fun emi ati ẹbi mi, ati orilẹede mi pẹlu.
Emi naa ṣetan lati koju Fury lẹẹkan si ti o ba ti ṣetan," Usyk lo sọ bẹẹ.
Usyk ni gbogbo bẹniiti ẹṣẹ kikan ti ipele to laami-laaka julọ wa lọwọ rẹ bayii.
Igba akọkọ ree ti abẹṣẹku-bi-ojo kan yoo gba gbogbo bẹniiti mẹrẹẹrin sọwọ ni nkan bi ọdun mẹẹdọgbọn.















