Ọba fi àmì ẹ̀yẹ dá akínkanjú ìbejì tó dóòlà èkejì rẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀ọ̀nì lọ́lá

Aworan Ibeji Georgia ati Melissa Laurie

Oríṣun àwòrán, Facebook/Jeff Sunbury

Akinkanju ibeji kan, Georgia Laurie, ti gba ami ẹyẹ idalọla lọwọ ọba alade lẹyin to doola ekeji rẹ, Melissa lọwọ ọọni.

Georgia, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn da ẹṣẹ bo ọọni loju nigba ti ọọni naa kọlu Melissa ekeji rẹ, nigba ti wọn n wẹ ninu odo kan ni Mexico lọdun 2021.

Awọn mejeeji dero ile iwosan lẹyin naa nibi ti Melissa ko ti le sọrọ fun igba kan.

Georgia ni inu oun dun wi pe oun ati ekeji oun bori ewu nla naa.

Aworan Ibeji Georgia ati Melissa Laurie

Oríṣun àwòrán, Georgia Laurie

“Mi o lero pe ọba le pinnu lati dami lọla”

Nigba ti Georgia gbọ pe orukọ rẹ wa ninu awọn ti ọba fẹ fi ami ẹyẹ da lọla, o sọ pe "iyi nla lo jẹ fun mi.

Iyalẹnu lo jẹ fun mi nigba ti mo gba lẹta pe ọba fẹ fun mi ni ami ẹyẹ.

Mi o tiẹ lero rẹ rara."

Nigba to n ba BBC sọrọ, Melissa ṣalaye pe nkan naa ṣẹlẹ ni iṣẹju aaya.

"Nigba ti ọọni bu mi jẹ ti o ṣi n wọ mi lọ sinu omi, mo lero pe opin ti de ba mi niyẹn.

Nigba naa ni mo bẹrẹ si ni sọ fun Georgia wi pe ko di mọ mi tori mo ti n ku lọ.

Mo di mọ ejika rẹ, bayii lo bẹrẹ si ni kọ orin "duro ti mi, ma foya."

O huwa akinkanju," Melissa lo sọ bẹẹ.

Melissa moribọ lọwọ ọọni, amọ o farapa

O ku diẹ ki iṣẹlẹ naa pe ọdun mẹta bayii nibi ti egun ibadi Melissa ti kan, ti o si tun farapa ni ikun ati ẹsẹ rẹ.

Koda, ọọni yii kan naa tun ge Georgia jẹ lọwọ.

Georgia ni bi ọjọ ti n gori ọjọ lori ìṣẹlẹ naa ni o n dabi ẹni pe ko ṣẹlẹ rara.

Georgia ibaṣepọ laarin oun ati ekeji oun ti tun dan mọran si leyin iṣẹlẹ naa.

Lati oṣu kẹfà ọdun 2021 ni awọn ibeji yii ti wa ni Mexico nibi ti wọn ti fi ara wọn jin lati ṣiṣẹ ni ibugbe awọn ẹranko.