Báwo ni ìjọ ẹ̀sìn mẹ́talọ́kàn ṣe di èyí tó ń dá èdèàìyedè sílẹ̀ láàrín àwọn aṣíwájú ẹ̀sìn Islam ní Ilorin?

Aworan adari awọn alfaa to tako isin ijọ yii, aworan ijọ naa ati Alhaja More Blessing

Awọn Alfa kan ni ilu Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara ti pariwo sita wi pe awọn o ni gba ẹṣin mẹtalọkan laaye ni ilu naa ati agbegbe rẹ.

Ariwo wọn yii n waye lori bi wọn ṣe ni arabirin kan, Alhaja Aminat Omoronike Akankẹ ti ọpọ mọ si More Blessing gbe ijọ kan kalẹ ti o ti n se ẹṣin abalaye, ẹṣin Kristẹni ati ẹṣin Musulumi.

Alhaja ‘More Blessing’ ni oludasilẹ ijọ kan ti wọn da pe ni “Ọlọrun o see kọju ija si” ni ilu Alalubọsa, ni ipinlẹ Kwara kan naa.

Fidio kan ti awọn Alfa naa fi sita ṣe afihan bi wọn ṣe lọ ba a ni ile ijọsin rẹ ni agbegbe Alalubọsa ti awọn igun mejeji si n takurọsọ, eyi si ti n fa awuyewuye lori ayelujara.

Bi awọn eeyan kan ṣe n fapajanu pe Emir ilu Ilọrin lo ran awọn Alfa naa lati lọ ree wo mọsalasi Alhaja naa lulẹ, lawọn miran tun n sọ̀ ọ lori ayelujara pe rara ọrọ ko ri bẹẹ rara.

Awọn Alfa ṣalaye ohun to ṣẹlẹ niluu Alalubọsa

Asiwaju awọn Alfa to n dojukọ 'Alhaja More Blessing'

BBC News Yoruba kan si awọn Alfa to wa ninu fidio naa lati mọ ohun ti wọn lọ ṣe ati isẹ ti wọn lọ jẹ nibẹ boya isẹ Emir ilu Ilorin ni tabi isẹ tarawọn.

Imam Abdulfatai Arowolo Magaji to jẹ aarẹ fun awọn ọdọ Alfa ni ilu Ilorin labẹ ẹgbẹ Youth Islamic Scholar for Ilọrin, sọ pe oun ati awọn akẹgbẹ oun lawọn lọ ba iya More Blessing ni ilu Alalubọsa.

O ni ilu Ilọrin ni awọn wa fun, Emir Ilorin si lo gbe ẹgbẹ awọn kalẹ lati maa dena, pẹlu koju ohun gbogbo to ba jẹ ibajẹ ninu ilu, fun idi eyi, Emir ni o fi isẹ ran awọn.

O ni awọn gbọ pe wọn n se ẹṣin mẹtalọkan, eyi ti o jẹ isẹse, Kristẹni ati Musulumi lawọn ṣe wa ba wọn ki wọn fọwọ mukan nitori awọn o ni faye gba iru ẹ ni ilu Ilorin ati agbegbe rẹ.

O ni wọn n pe Jesu ninu Mọsalasi ti wọn ti n kirun, eleyi to ni o lodi si ohun ti awọn gbe lọwọ, awọn kosi fara mọ.

O salaye pe iroyin ẹlẹjẹ ni pe awọn fẹ wo mọsalasi rẹ, "Emir Ilorin o ran wa lati lọ wo mọsalasi, Emir jẹ adajọ ti wọn mọ ofin ti wọn si n pa ofin mọ, wọn ko lee pasẹ pe ki a wo mọsalasi rẹ.

"Ọmọ Ilorin ni arabinrin yii ati ọkọ rẹ, o si ni ominira lati se ẹṣin ti o ba fẹ, amọ ki o mase paa ẹṣin pọ mọrawọn.

"A si wa lori ọrọ naa, a o si ni gba a laaye lai lai"

Ẹsin Kristẹni ati Musulumi ni Olorun fi ran mi, Alhaja ‘More Blessing’ fesi

Alhaja 'More Blssing'
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

BBC News Yoruba tun de ilu Alalubọsa lati gbọ tẹnu Alhaja Aminat Omoronike Akanke, More Blessing ti o jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ Olorun o see kọju ija si.

O see lalaye pe, isẹ ti Olorun fi ran ohun ni ki ohun maa da awọn eniyan lohun ni ilana Jesu Kristi ati Mohammed.

O ni ohun o se mẹtalọkan bi wọn ṣe sọ sugbọn ohun n gbadura nilana Kristẹni ati Musulumi nikan gẹgẹ bi Olorun ṣe gbe le ohun lọwọ.

"Musulumi ni mi, sugbọn Olorun ni ki n maa da awọn eniyan lohun nipasẹ Jesu Kristi, mo n se bẹẹ, awọn ẹri si n tẹ lee. Koda, Kristẹni kan ti Olorun gbọ adura rẹ nipasẹ mi lo kọ Mọsalasi yii fun mi.

"Wọn wa ni ki mase pe Jesu, bẹẹ, ẹṣin mejeji ni Olorun ran mi si, kiise ọkan, mo si ni ominira ẹṣin ni wọn igba ti mi o ti fi di eeyan tabi ẹṣin kan lọwọ. Ọmọ Naijiria, ẹ gba mi o

"Lotitọ awọn Alfa ti wọn wa, wọn o ba ti ija wa, wọn o si ba nkankan jẹ sugbọn wọn fi ẹnu ba nkan jẹ. Ọpọlọpọ eeyan to wa fun adura, ni wọn pe jade, tan si gbe wọn sori ayelujara.