Àṣírí bí wọn ṣe ń fi òwò gẹdú ṣagbátẹrù ìgbésùmọ̀mí

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn to n ta igi gẹdu lọna aitọ ni iroyin ti sọ pe wọn n fi owo rẹ ṣatilẹyin fun awọn alakatakiti ẹsin ni Mozambique.
Okoowo naa ti ko ba ofin mu, ni iye owo ti wọn n pa nidi rẹ to miliọnu mẹtalelogun dolla lọdun.
Ninu atẹjade kan ti ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba, Environmental Investigation Agency fisita (EIA) eyii ti BBC foju ri, iwadii fi han pe igi gẹdu naa ti wọn n pe ni ‘rosewood,’ eyii ti wọn n ji ko lati Mozqmbique lọ si China, ni wọn n fi owo rẹ ṣagbatẹru awọn agbesumọmi Al-Shabab lagbegbe Cabo Delgado.
Bo tilẹ jẹ pe ajọṣepọ wa laarin awọn orilẹede nipa iye igi gẹdu ‘rosewood’ ti wọn le ta, ki igi naa ma ba parun, iwadii idakọnkọ ọlọdun mẹrin ti EIA ṣe fi han pe, lọpọ yanturu ni wọn n ko igi naa lati Mozambique lọ si China lai si idiwọ kankan, ti ijọba ko si mọ nipa rẹ.
"Owo latinu okoowo igi gẹdu ni awọn ọmọ ogun agbesumọmi Al-Shabab n na, ti wọn si fi n ra nnkan ija oloro"
Aṣiri yii lo tu sita latari igboya tuntun ti awọn agbesumọmi n lo lati ṣe akọlu lemọlemọ ni ariwa Mozambique.
Atẹjade kan kan ti ijọba ilẹ naa fi lede fi han pe owo igi gẹdu ọhun ni awọn ọmọ ogun agbesumọmi al-Shabab n na, ti wọn si fi n ra nnkan ija oloro.
Iwadii atẹjade naa sọ pe owo to n jade nidi owo igi ọhun ko din ni $1.9m loṣoṣu.
Bo tilẹ jẹ pe o ṣoro lati ṣabẹwo si agbegbe Cabo Delgado ti awọn agbesumọmi naa ti n ṣọṣẹ julọ, iroyin ni awọn ileeṣẹ to n ge igi ọhun n fun awọn agbebọn naa ni idamẹwaa owo ti wọn n pa fun abo.
Awọn ileeṣẹ to n ko igi lọ soke okun sọ pe ida ọgbọn igi ti wọn ta silẹ okere lo wa lati agbegbe ti awọn agbesumọmi n dari.
Ẹwẹ, ijọba China ti ni oun fofin de kiko igi ‘rosewood’ naa wọn ilẹ oun ṣugbọn awọn kan ṣi n gba ọna ẹyin ko wọle.
Orukọ ti wọn n pe igi naa ni China ni ‘hongwu.’
Mozambique ni orilẹede akọkọ ni Afrika ti China ti n ko igi ‘rosewood’ wọle.
Lọdun to kọja, nnkan bii ogun tọọnu igi naa ti iye owo rẹ to $11.7m lo wọle si China lati Mozambique.
Laarin oṣu Kẹwaa, ọdun 2023 si oṣu Kẹta ọdun 2024, ọọdunrun kọntena lo ko igi naa lo kuro ni eti omi Beira ni Mozambique lọ si China.
Apapọ iye owo igi to wa ninu awọn kọntena ọhun ko din ni $18m.















