Wo àrà tí ẹgbẹ́ akọ̀rin tó jẹ́ kìkìdá obìnrin ń dá láì sí ọkùnrin kankan níbẹ̀
Oluwatumininu Oluwarantimi Ayanleye jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, to si maa n lu iya ilu bii ọkunrin lati igba kekere rẹ.
Obinrin onilu naa, ti ọpọ mọ si Ayantummy, lo tun da ẹgbẹ akọrin kan silẹ to jẹ pe kikida obinrin ni wọn nibẹ laisi si ọkunrin kan soso.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ayantunmi ni kii kuku se pe oun kọ isẹ ilu lilu, amọ ajẹbi ni nitori inu ẹjẹ oun ni ilu lilu wa, idile ayan ni iya oun ti wa.
Yatọ si eyi, Ayantummy tun ni isẹ mii lọwọ to n se yatọ si ilu lilu, isẹ naa si ni isẹ atọkọse taa mọ si Mẹkaliki.

Ninu iwadi BBC Yoruba, a ri pe se ni obinrin naa n pe awn obinrin akẹẹgbẹ rẹ to ba n lu ilu lati wa dara pọ mọ oun lati da ẹgbẹ akọrin kan silẹ.
Nigba to n sọrọ lori iriri rẹ lati ko ẹgbẹ akọrin to jẹ kikida obinrin jọ ati awọn ipenija to n koju wọn paapaa pẹlu awọn ọkunrin.
Ayantunmmy fesi pe “awọn ọkunrin maa n fẹ kọminu lori ẹgbẹ akọrin wa, ti wọn si maa n ro pe a ko ni lee se.
A to eeyan mẹẹdogun ninu ẹgbẹ akọrin mi, o si ni ojuse ti ẹni kọọkan wa n se, amọ ilu gangan ni emi n lu.
A ni ẹni to n lu omele, iya ilu, sedion, chord, omele bata, ati bẹẹ lọ.”

Nigba to n sọrọ nipa afojusun wọn, Ayantunmmy ni awọn fẹ ki aye mọ pe ohun ti ọkunrin le se, awn obinrin naa le se.
“Isẹ ọkunrin ati agbo awọn akọ ni isẹ ilu lilu jẹ, amọ a fẹ fi han araye pe a le se ohun tawọn ọkunrin n se.
Amọ ilu lilu ti gbe mi de awọn ibi ti isẹ ọwọ mi lasan ko le gbe mi de.
Mo wa n rọ awọn obinrin lati mase sa fun ilu lilu, ko si ohun to le ninu rẹ.






