Ìdí tí èèyàn fi fẹ́ràn láti máa jẹ ìpápánu dípò oúnjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ebi kìí wọnú kí ọ̀rọ̀ mìíràn tún wọ̀ ọ́.
Àmọ́ nígbà mìíràn, èèyàn á máa jẹun lékè moyó nítorí ìfẹ́ láti máa jẹ àwọn ìpápánu bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹun gidi tán.
Ǹjẹ́ ìwọ̀ náà wà lára àwọn tó máa ń jẹ ìpápánu nní gbogbo ìgbà kódà lẹ́yìn oúnjẹ gidi? Irú jíjẹ ìpápánu bẹ́ẹ̀ ni àwọn onímọ̀ pè ní “hedonic eating”.
Jíjẹ oúnjẹ tàbí ìpápánu láì ṣe wí pé ebi ń pa èèyàn ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì pè ní “hedone” èyí tó jẹyọ láti inú èdè Gíríkì tó túmọ́ sí “mímu”.
Lóòótọ́ ni àwọn oúnjẹ kan máa ń wu ènìyàn jẹ lásìkò kan àmọ́ ohun tó máa ń fa tí èèyàn fi máa ń sábà jẹ ìpápánu kò ṣẹ̀yìn bí àwọn ìpápánu náà bá ṣe wà sí, tí yóò sì máa wu èèyàn jẹ láì ṣe wí pé ebi ń pani.
Báwo ni èèyàn ṣe le dín jí jẹ ìpanu kù?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Látara àwọn oúnjẹ àti nǹkan mímu ni èèyàn ti máa ń mú okun àti agbára. Tí èèyàn kò bá máa jẹun tó bó ṣe yẹ, ara èèyàn máa ń sọ nípa bíbéèrè oúnjẹ lọ́pọ̀ ìgbà. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí inú èèyàn ní ọ̀nà láti sọ fún ọpọlọ wa pé abi ti dé.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàpèjúwe jíjẹ ìpápánu bíi ìgbà tí èèyàn bá ń jẹ oúnjẹ lásìkò tí ebi kò bá pa á, tó kàn fẹ́ fi dí gàgá ẹnu.
Onímọ̀ nípa bí ebi àti ìwọ̀n agbára ara ènìyàn ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Leeds, Britain, Ọ̀jọ̀gbọ́n James Stubbs ní gbogbo èèyàn ló ní ìwà yìí tó sì ní ìpanu kan tó máa ń wu èèyàn jẹ lọ́pọ̀ ìgbà.
Fún àwọn kan, jíjẹ oúnjẹ wà lára nǹkan tí wọ́n fẹ́ràn láti máa ṣe.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Stubbs fi kun pé àyíká àti ìlera ara èèyàn máa ń fa kí ìpápánu máa wu èèyàn jẹ ní gbogbo ìgbà tí kìí sí jẹ́ kí èèyàn mọ ìgbà tó yẹ kí èèyàn jẹun gidi tàbí jẹ ìpápánu.
Ó ní kìí ṣé èso tàbí ẹ̀fọ́ ni tó ṣara lóore ni àwọn èèyàn máa ń jẹ tí wọ́n bá fẹ́ panu.
Ọ̀jọ̀gbọ́n àti onìwádìí ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Liverpool, Dókítà Bethan Mead ní àwọn èèyàn fẹ́ràn láti máa jẹ ìpanu tó ní ọ̀pọ̀ ṣúgà, iyọ̀ àti ọ̀rá nígbà tí wọ́n bá fẹ́ jẹ ìpápánu.
“A fẹ́ràn láti máa jẹ àwọn ìpánu yìí nítorí adùn tí a máa ń rí níbẹ̀ èyí tí kìí jẹ́ ká lè mọ̀ nígbà tí a bá ń jẹ ìpápánu bóya nítorí ebi tàbí ìpanu lásán.
Ìbẹ̀rù sísanra àsanjù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nítorí àwọn adùn tó máa ń wà nínú àwọn ìpanu yìí ló máa ń fà á ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi máa ń jẹ wọ́n, tó sì jẹ́ ọ̀pọ̀ iyọ̀, ṣúgà àti ọ̀rá ló máa ń wà nínú wọn.
Àwọn ìpanu yìí wà lára àwọn ohun tó máa ń ṣokùnfà ara sísan lásanjù.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Stubbs ní àwọn ìpanu yìí ń fa ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò yìí.
“Ohun ló ń ṣokùnfà bí àwọn èèyàn ṣe ń sanra àsanjù, sanra ju ọjọ́ orí wọn lọ. Èèyàn kan nínú èèyàn mẹ́jọ lágbàáyé lónìí ló tóbi ju ọjọ́ orí wọn lọ.”

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kí ni èèyàn lè ṣe láti dín ìpápánu kù?
Kò sí ohun tó burú nínú kí èèyàn jẹ ohun tó bá wù ú jẹ tàbí jẹ ìpanu tó bá wu èèyàn àmọ́ àwọn onímọ̀ ní ewu pé èèyàn le jẹ ju iye tó lẹ́tọ̀ọ́ lọ ló jẹ́ ohun tó máa ń kọ àwọn onímọ̀ lóminú.
Ìwádìí tí wọ́n gbé jáde ní orílẹ̀ èdè Turkey ní oṣù Kìíní ọdún 2024 nínú ìwé Human Nutrition and Dietetics ṣe àgbéyẹ̀wò bí àwọn ìpanu ṣe ń fa kí àwọn ọ̀dọ́ máa sanra àsanjù.
Ìwádìí náà ní bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe ń jẹ ìpanu sí náà ni àwọn èèyàn ṣe ń tóbi sí báyìí.
Dókítà Mead ní ara ohun tó le mú àdínkù bá àwọn ìpanu tí àwọn èèyàn ń jẹ kù ni tí wọ́n bá gbìyànjú láti mú àdínkù bá bí wọ́n ṣe sanra.
Jíjẹ àwọn àwọn oúnjẹ tó ṣaara lóore lójúnà àti mú àdínkù bá ara sísan kìí ṣe ohun tó rọrùn láti ṣe gẹ́gẹ́ bí èrò Ọ̀jọ̀gbọ́n Stubbs.
Dókìtà Mead ní ìwádìí fi hàn pé jíjẹ ìpanu máa ń dínkù tí èèyàn kò bá fẹ́ sanra, tí yóò sì mú àyípadà bá bí àwọn èèyàn náà ṣe máa ń rí oúnjẹ.
Ó ní àwọn èèyàn nílò láti ṣàwárí nǹkan mìíràn tí wọ́n fẹ́ràn láti máa ṣe bíi ijó jíjó, ṣíṣe eré pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n bá fẹ́ mú àdínkù bá bí wọ́n ṣe máa ń jẹ ìpanu.
“Ohun tó ṣe pàtàkì ni kí èèyàn mọ ohun tó fẹ́ràn, tó sì lè mu ní ara rẹ le, a ò lè ní kí àwọn èèyàn má jẹ ohun tí wan fẹ́ àmọ́ ó dára láti jẹ àwọn nǹkan tó máa fún èèyàn ní àǹfàní ju èyí tí yóò lékún ìnira lọ.















