‘Ojú títì ni mo ti rí òkú àwọn mọ̀lẹ́bí mi lásìkò òjò tó fa ẹ̀kún omi’

Aworan Noor Mohammed to jokoo sita
Àkọlé àwòrán, Noor Mohammed padanu iyawo rẹ, aburo rẹ lobinrin, ọmọ rẹ ati awọn ọmọ-ọmọ meji nigba ti omiyale kọlu agbegbe rẹ
    • Author, Yama Bariz, BBC Pashto
    • Role, BJ
    • Reporting from, Baghlan province, Afghanistan

Ni ọjọ keji ti iṣẹlẹ omiyale waye, Noor Mohammed ri oku awọn mọlẹbi rẹ oju titi.

Ẹni ọdun marundinọgọrin ni, o jina ni iwọnba kilomita ọgọrun un si ile rẹ nigba to gbọ ariwo omi to n yabọ .

Noor sare pada si ile nibi ti iyawo, aburo rẹ lobinrin, ọmọ rẹ ọkunrin ati awọn ọmọ-ọmọ meji ti n rẹju.

Sugbọn aṣọ ko ba ọmọ yẹ mọ.

Agbara omiyale nla ti wọ awọn mọlẹbi rẹ ati ile kuro. Omiyale ojiji yii lo waye alẹ ọjọ Ẹti

Ileeṣẹ to n risi iseto ounjẹ lagbaye ni o le ni ọọdurun eeyan to ti jade laye.

Bakan naa lo ni ẹgbẹrun meji ile si dawo ninu iṣẹlẹ naa to n bawọn finra ni agbegbe apa ariwa Afghanistan ni Baghlan.

Igbagbọ wa pe afikun yoo de ba awọn iye yii.

Gbogbo agbegbe Badakhshan, Ghor ati iwọ oorun Herat ni omiyale naa ṣe ikọlu si.

"O da bi pe n ko ni oluranlọwọ." Noor sọrọ.

Ni irọlẹ ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, o gbiyanju lati wa gbogbo ayika boya yoo ri awọn mọlẹbi sugbọn pabo lo jasi.

Aago kan loru lo yọwọ ninu wiwa awọn mọlẹbi rẹ, ni oorun yẹn naa lo rin irin wakati mẹta lọ si ile ọmọ rẹ lobinrin, Saeeda.

O pada si ile lọjọ keji ni o ri oku mọlẹbi.

"Ohun to bani lọkan jẹ pupọ ni."

Aworan awọn mọlẹbi niwaju ile wọn to dawo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọ ile lo dawo lasiko iṣẹlẹ omiyale naa

Abule Noor ko ṣe gba fun ọkọ, ọpọ mọlẹbi to wa nibẹ lo ti padanu eeyan kan tabi meji tori ẹkun omi

Noor ni oun ko ri iru nnkan bayii ni igbesi aye rẹ - boya nipasẹ iru iṣẹlẹ bayii tabi ki ogun waye ni ilu.

Sweeda, ẹni ti ọmọ rẹ, ẹni ọdun marundinlọgbọn wa lara ọmọ-ọmọ Noor to padanu ẹmi rẹ nibi iṣẹlẹ omiyale.

Ni abule Noor, Gaz, ibi ti ko ṣe gba fun ọkọ, ọpọ mọlẹbi to wa nibẹ lo ti padanu eeyan kan tabi meji nitori iṣẹlẹ omiyale , ti wọn si kegbe sita pe wọn nilo iranlọwọ.

"A ti lọ si awọn agbegbe to jẹ pe gbogbo nnkan ni wọn ti padanu," Rouzatullah, nọọsi kan to ti lọ si awọn agbegbe ti omiyale naa kọlu pẹlu ikọ rẹ ṣalaye.

Oun pẹlu awọn nọọsi marunlelogun to fi mọ Dokita, sure lọ si awọn agbegbe naa lati ilu to wa ni Samangan.

O ni oun pese iranlọwọ fun eeyan to le ni igba ni iye, paapa ọkunrin kan to padanu eeyan mẹrindinlogun ninu mọlẹbi rẹ.

"Nnkan ti a ri ba wa lọkan pupọ," o ni. "Awọn eeyan gbiyanju lati ri awọn oku eeyan pada. Ọpọlọpọ ile lo ti dawo."

Aworan maapu agbegbe ti omiyale ṣe ikọlu si

"Ko si omi mimu fun wa, ti arun si le tan kaakiri"

Pẹlu gbogbo igiyanju Rouzatullah ati ikọ rẹ, wọn ko ni anfani lati de awọn agbegbe kan nibi ti awọn to nilo iranlọwọ wa, ti wọn si pariwo sita pe omiyale ti n fa aarun si wọn lara.

"Ko si omi mimu," Rouzatullah ṣe ikilọ. "Ati aarun yii le tan ka."

Ni awọpn agbegbe ti wọn ni anfani lati de si, awọn ikọ naa pese iranlọwọ ti o n ba awọn yoo oku sita.

Ni abule Gudan Bala, Mohammad Bassol ni ọgba nla to ti n ṣe agbẹ sugbọn omiyale ti ba gbogbo oko rẹ jẹ.

Nigba ti a n kọja lọ, a ri oko owu ati wheat sugbọn omiyale ti ba gbogbo rẹ jẹ.

Inu Mohammed dun pe awọn mọlẹbi rẹ wa laye sugbọn o ni oun ti padanu gbogbo nnkan yooku.

Aworan Mohammad Rasool niwaju ile rẹ ti omiyale gbe lọ
Àkọlé àwòrán, Mohammad Rasool duro sibi ile rẹ wa tẹlẹ ko di pe omi gba lọ
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O fi oko to ti n gbin kan ti omiyale bajẹ

"Nnkan to n mu owo wọle fun mi ree," o ni. "Ko si oluranlọwọ fun mi"

O to ida ọgọrin ọmọ ilẹ Afghan, ti gbe ọkan le isẹ agbẹ lati mu owo wọle. Muhammad ni ko ro pe awọn le ye asiko yii.

O na ọwọ si nnkan to ku ni ile rẹ niwaju. Ko le pada sibẹ nitori omi na si ga .

"N ko ni nnkan mọ, ki ni mo fẹ ṣe? Mo ni mọlẹbi ti mo fẹ pese fun sugbọn n ko ni nkankan."

Saaju ki iṣẹlẹ omiyale naa to waye ni Ajọ agbaye UN ti kede pe o le ni milọnu mẹrinlelogun eeyan ni yoo nilo iranlọwó ni ọdun yii.

"Ko ki n ṣe nnkan ọgbin nikan ni omiyale yii ṣe akoba fun. Mohammed ni awọn to mu ile ti oun padanu maalu meji ninu iṣẹlẹ omiyale .

Noor to n gbe pẹlu ọmọ rẹ ni oogun kan ti oun ni bayii ni aṣọ to wọ sọrun.

O ti n gbe ninu ile ti omi ti gbe lọ lati igba to ti ni ọmọde- baba rẹ lo kọ ile naa ni ọdun marundinlaadọrun sẹyin.

"Mo kan ni ireti nipa ọjọ ọla." "Ọmọ mi ati ọmọ-ọmọ mi jẹ olukọ, ti wọn si jẹ ohun iwuri fun mi nitori wọn n kopa ninu ọjọ ọla orilẹede.

"Awọn mejeeji ti ku bayii

"Omiyale ti gba gbogbo rẹ."