"Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ òfin ni mi, kò sẹ́ni tó kọ́ mi níṣẹ́ àkàrà òyìnbò, orí ayélujára ni mo ti kọ́ ọ"

Àkọlé fídíò, Ẹ̀ẹ̀marùn-ún ni mo ṣèdánwò JAMB, kí ń tó wọlé sí fásitì láti kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ òfin
"Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ òfin ni mi, kò sẹ́ni tó kọ́ mi níṣẹ́ àkàrà òyìnbò, orí ayélujára ni mo ti kọ́ ọ"

Yoruba ni ohun to ba n wu ni, lo maa n pọ lọrọ ẹni, Ologunẹru ku, asọ rẹ jẹ ọkan soso.

Bẹẹ lo ri fun ọkunrin kan, Aberuagba Fawaz, tii se akẹkọọ ni fasiti Ilorin, to si n kọ nipa imọ ofin, ẹka ipele eto ẹkọ fasiti kẹta si lo wa.

Fawaz nifẹ pupọ si isẹ amofin, to si tun nifẹ pupọ gan si sise akara oyinbo fun tita.

BBC Yoruba wa akẹkọ naa de ilu Ilorin lati mọ bo se rọrun fun si lati pa isẹ mejeeji naa pọ, ti ọkan ko si pa ekeji lara.

Bakan naa, Fawaz tun sọrọ lori bo se kọ isẹ akara oyinbo sise ati bo se di akẹkọ nipa ofin lẹyin to ti kuna lati sedanwo yege fun eto ẹkọ naa lọpọ igba.

Fawaz Aberuagba

“Ko si ẹni to kọ mi nisẹ akara oyinbo sise, ori ayelujara ni mo ti kọ”

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Fawaz Aberuagba ni oun maa n ta akara oyinbo, se e, ti oun si tun maa n se awọn nnkan miran ti wọn n fi fulawa se.

“Ọdun meji sẹyin ni mo bẹrẹ si ni kọ nipa sise akara oyinbo yii ni asiko igbele arun Coronavirus, ti mo si wa nile ẹkọ Adekunle Ajasin nipinlẹ Ondo.

Mo kan n wo ori ayejara lọjọ kan, ni mo ri bi wọn ti n se akara oyinbo yii, mo sọ fun iya mi, a si dan wo, o jade daadaa.

Lati igba yẹn ni mo ti n nifẹ lati maa se akara oyinbo lẹyin ti arun Koro lọ tan, ti mo si mu bii okoowo ti mo gbajumọ.

Mo n ta awọn akara oyinbo yii atawọn ohun miran ti ẹnu n jẹ, ti wọn n fi fulawa se fawọn akẹkọọ ti a dijọ n gbe ni ilegbe akẹkọọ nile ẹkọ fasiti.

Ẹnikẹni ko kọ mi bi wọn ti n se akara oyinbo, ori ayelujara ni mo ti mọ ọ.”

Bakan naa ni Fawaz fikun pe kii se pe boya oun joko tabi lọ sọdọ ẹnikan lati lọ wo o bi wọn ti n se akara oyinbo yii lati fun ara oun ni imọ.

Amọ oun mọ pe oun ni itara ati ifẹ si bi eeyan ti n se akara oyinbo, bẹẹ ni ori ayelujara si dara pupọ lati kọ orisirisi nnkan.

O wa fikun pe obinrin kan tun kọ oun ba ti maa n se akara oyinbo to ni oorun Vanilla ninu.

Fawaz Aberuagba

"Mo nifẹ lati kọ ẹkọ nipa imọ ofin, ẹẹmarun si ni mo joko se idanwo asewọle sile ẹkọ fasiti ta mọ si JAMB"

Fawaz Aberuagba, lasiko to n salaye ohun ti oju rẹ ri, ko to di akẹkọ nipa imọ ofin, eyi to wu u lọkan, o sọrọ, ilẹ kun.

“JAMB karun ti mo kọ, ni mo fi wọle sile ẹkọ fasiti Ilorin lati kọ nipa imọ ofin, ẹkọ nipa ofin Islam ni mo n kọ lọwọ.

Mo fẹ di agbẹjọro, mo si tun fẹ maa se ohun ti mo nifẹ si julọ, iyẹn akara oyinbo sise.

Ko si ohunkohun to le di mi lọwọ lati mase se isẹ mejeeji papọ nitori mejeeji ni mo nifẹ si julọ.”

Fawaz Aberuagba

“Ninu aye mi, ifẹ si isẹ sise sise akara oyinbo ko ida ọgọta, ti isẹ amofin si ko ida ogoji ninu ọgọrun”

Nigba to n salaye boya o le fi isẹ sise akara oyinbo silẹ, to ba di agbẹjọro tan, Fawaz ni laelae oun ko le se bẹẹ.

“Ti mo ba kẹkọ tan, ti mo si n sisẹ agbẹjọro, mo si le maa se akara oyinbo, ti mo ba ti ibi isẹ de.

Amọ ti wọn ba ni ki n gbe isẹ mejeeji si ori odiwọn nipa bi mo se fẹran wọn si, sise akara oyinbo yoo ko ida ọgọta ninu ọgọrun, ti isẹ amofin yoo si ko ida ogoji ninu ọgọrun.

Awọn eeyan maa n fi lẹta ransẹ si mi lori ayelujara pe awọn fẹ kọ isẹ, mo si ti kọ ọpọlpọ eeyan.

Bi mo se kọ ọkunrin naa ni mo fọ awọn obinrin, ọpọ wọn si lo jẹ obinrin, ti mo si maa n kọ wọn ni ọfẹ.”

Nigba to n sọrọ lori bo se n se akoso akoko rẹ laarin sise akara oyinbo ati kikọ ẹkọ bii amofin, Fawaz ni Ọlọrun nikan lo jẹ ko rọrun fun oun, amọ oun si maa n se akoso akoko oun bo se yẹ.