"Mo kọ́ iṣẹ́ Mẹ́kálíkìì ọ̀kadà lẹ́yìn ìwé mẹ́fà àmọ́ mo kẹ́kọ̀ọ́ gboyè dìgírì méjì fúnra mì i"
Yoruba ni ẹni ti yoo ga, ẹsẹ rẹ yoo tiirin nitori ọjọ ti eeyan ba gun, kọ ni yoo kan ọrun.
Bi ọrọ se ri ree pẹlu igbe aye gbajumọ osere tiata nni, Muyideen Oladapo, ti ọpọ eeyan tun mọ si Lalaa.
Odu ni Lalaa, kii se aimọ fun oloko lagbo isẹ tiata, ti ọpọ awọn osere to n bọ ẹyin ati awọn araalu to n wo lọọkan si maa n fi ọla rẹ tọrọ lọwọ Ọlọrun.
Amọ pupọ awọn eeyan yii ni ko mọ ọpọ idojukọ ati ipenija to ti la kọja, ko to di eeyan ti igba oju mọ nile aye.
Amọ nigba to n sọ itan igbe aye rẹ fun BBC Yoruba lasiko ti a kan si, Lalaa sọrọ ilẹ kun lori ohun ti oju rẹ ti ri nile ayee.

“Isẹ Fọganisa ni ẹgbọn mi taku pe maa kọ nilu Kano amọ mo ni maa kọ siẹ Mẹkaniki ọkada”
Ninu ọrọ rẹ, Lalaa, tii se ọmọ ilu Osogbo ni baba oun bimọ to pọ, to si jẹ pe iwe mẹfa lasan lo maa n ran ọmọ rẹ ti yoo fi jawọ.
Amọ iwe lo wu mi ka, ti isẹ ko si wu mi kọ rara amọ nmigba to di pe n ko fẹ wulo fun ara mi gan, mo gba si wọn lẹnu.
‘”Ẹgbọn mi kan tiẹ yari pe isẹ Fọganisa ni maa kọ nitori pe o ta pupọ nilu Kano, amọ mo ni ki wọn jẹ ki n lọ kọ isẹ mẹkaliki ọkada.
Wọn fi mi si ẹnu ẹkọsẹ, mo lo ọdun mẹfa, mo si se ayẹyẹ ominira.”

“Mo dara pọ mọ ẹgbẹ osere tiata lọdun 1992”
Lalaa tẹsiwaju pe oun wa silu Eko lati maa ba ile isẹ burẹdi kan sisẹ.
Lọjọ kan ti oun si n lọ si agbegbe Ebute Ero ni oun ri awọn eeyan kan to n lu ilu, ti oun si duro lati woran wọn.
“Mo mọ ilu lu pupọ, mo si bi wọn pe mo fẹ dara pọ mọ wọn.
Wọn ni Dagunro Alakija lo ni ẹgbẹ osere tiata naa, ti mo si ni baba mi ni nitori ọmọ ilu Osogbo ni.
Ọdun 1992 ni mo dara pọ mọ Dagunro lati kọ isẹ tiata, ti mo si tun ni sọọbu ti mo ti n bawọn eeyan gẹrun.”

“N ko sun mọju lọjọ ti mo gba lẹta pe wọn mu mi lati kawe ni fasiti OAU, ọjọ ti inu mi dun julọ niyi”
Lalaa tẹsiwaju pe oun gba olukọ nilu Eko lati maa kọ oun ni ẹkọ girama nitori ẹkọ iwe wu oun pupọ.
“Ni ọjọ ti mo kọkọ lọ sile ẹkọ lati sedanwo, bi mo se sọkalẹ ninu mọto, se ni ile ẹkọ daru pe Lalaa wa sedanwo.
Amọ n ko jẹ ki eyi di mi lọwọ, ohun ti mo fẹ se ni mo gbajumọ.
Idanwo jade, esi idanwo mi si se daadaa, lẹyin naa ni mo joko sedanwo lati wọle ẹkọ fasiti.
Mo tun yege idanwo naa, ti mo si wọle ẹkọ fasiti Obafemi Awolowo ni Ile Ife.
N ko sun mọju lọjọ ti mo gba lẹta pe wọn mu mi sile ẹkọ fasiti OAU naa.”
Lalaa wa kede pe oun to dun mọ oun ninu julọ laye ni pe oun pada kawe, ti oun si tun lọ sile ẹkọ fasiti Obafemi Awolowo.
Bakan naa, Lalaa ko duro lori imọ ijinlẹ akọkọ, se lo tun lọ kẹkọ gboye imọ ijinlẹ keji nile ẹkọ fasiti Eko, UNILAG.
O wa fi ọwọ gbaya pe ẹkọ iwe kopa gidi ninu igbe aye oun, ti o si mu ayipada nla ba bi oun se n ronu.
Lalaa ni oun ko tun ni dawọ ẹkọ duro lori imọ ijinlẹ keji nitori ti oun yoo fi ku, oun yoo si maa wa imọ si ni.






