Tani Ọlọhun bù sẹ́kún báwọn oníṣẹ̀ṣe ṣe fí ọkọ́ bọ̀gìnì ta á lọ́rẹ

Aworan Tani Olohun

Oríṣun àwòrán, TANI OLOHUN

Lẹyin ti Abdulazeez Adegbola, tawọn eeyan mọ si Tani Olohun, to wọ wahala nitori awọn ọrọ ibanilorukọjẹ to n sọ lori ẹrọ ayelujara se kuro ni ahamọ, idunnu ti wa subu lu ayọ fun.

Idi ni pe ẹgbẹ onisẹse kan ti fi ọkọ bọginni ta lọrẹ eyi to mu ki inu rẹ dun pupọ̀.

Pẹlu omije ni Tani Olohun fi gba kọkọrọ lọwọ ajọ Ọba Ela Foundation niluu Ibadan lọjọ Aje, Ogunjọ oṣu Kọkanla ọdun 2023.

Nigba to n sọrọ pẹlu omije, Tani Olohun ni gbogbo ohun to sẹlẹ si oun ko ju pe oun ri otitọ ọrọ oun si sọ sita, ki i ṣe pe oun fẹ ba ẹsin kankan jẹ.

“Bi mo ṣe ri niyẹn, ki ṣe pe a fẹ ma ba ẹsin kan jẹ.

Nigba ti a ba ri otitọ ọrọ ti awọn eeyan kan ti n ṣe bakan lati ẹyin wa, ti a dẹ ni ko yẹ ki kini yii ri bayii”.

Tani Olohun ati awọn akẹgbẹ rẹ ninu isẹ awo lo kọwọrin lọ gba kọkọrọ ọkọ naa lọwọ ajọ Ọba Ela Foundation.

Tani Olohun ti mọ saaju pe nnkan bayii yoo waye, iransẹ Olodumare ni - Oba Ela

Aworan Tani Olohun

Oríṣun àwòrán, Tani Olorun

Oludasilẹ Oba Ela Foundation, Babaawo Ifaseyi ti ọpọ mọ si Ọba Ela agbaye salaye pe ki ṣe pe Tani Olohun lọ si ọgba ẹwọn nikan sugbọn o di ẹsin isẹse rẹ mu.

“Tani Olohun mu ọrọ isẹse lọkunkundun nigba to tun jade lọgba ẹwọn, a ro pe yoo yi pada kuro ninu ẹsin isẹse nitori wọn le fi owo tan an sugbọn o kuna lati tẹle.

“Gbogbo ohun to sẹlẹ wa lọwọ kadara, ọjọ ti wọn sọ ifa to bi Tani Olohun fun mi, ni mo ri ninu ifa naa pe arakunrin yii, ọrọ ẹjọ yoo sẹlẹ ninu pipe ẹsin si ara wọn.

”A tun ri pe wọn yoo ko sẹkẹsẹkẹ si lọwọ, koda oun gan ti mọ pe nnkan bayii ma sẹlẹ, bi ko sẹlẹ ni ọna yii, yoo gba ọna miiran.

“Iransẹ Olodumare ni Tani Olohun, nnkan ẹyọ kan ni Tani Olohun sọ, wọn ni ọrọ odi, a gba.

Sugbọn awọn eeyan naa ti sọrọ odi si wa ri, to pọ, ti a ko fi bẹẹ gbe wọn lọ si ile ẹjọ sugbọn bayii a ti mọ pe a le ma gbe ara wa lọ ileẹjọ.

“Nitori rẹ ni Tani Olohun fi tọrọ aforijin.”

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post

Ki lo sẹlẹ saaju?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Saaju ni Ile ẹjọ Majisireeti kan to n joko niluu Ilọrin gba beeli ati oniduro fun gbajugbaja onisẹse naa, Tani Olorun.

Awọn Aṣiwaju ẹsin Musulumi kan atawọn ẹgbẹ mẹrin ọtọọtọ lo pe Tani Ọlọhun lẹjọ ni ile ẹjọ ọtọọtọ fun ẹsun ti o da lori ibanilorukọjẹ ati itabuku ẹṣin Islam.

Ẹjọ akọkọ ni eyi ti Kọmisonna Ọlọpaa Kwara pe e lorukọ ẹgbẹ̀ kan to n jẹ Association of Proud Sons and Daughters of Ilọrin (Ogo Ilorin) ni iwaju Magistrate Muhammad Ibrahim fun ẹsun ibanilorukọjẹ.

Ekeji ni ti Alfa Tonile Okutagidi ni iwaju Honourable Sunday Adeniyi ti ile ẹjọ Upper Area fun ẹsun ibanilorukọjẹ bakan naa.

Lẹyin ti Tani-Ọlọhun gba iyọnda ile ẹjọ lo rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn olupẹjọ lati foriji oun.

Tani Ọlọhun fi kun un pe oun ko mo pe ohun ti oun n se nigba naa jẹ ẹsẹ sugbon oun ko see lati fi tabuku ẹni kan tabi ẹṣin kan.

Lẹyin eyi ni adajọ Muhammad Adam gbe idajọ ranpẹ kalẹ, o si gba beeli olujẹjọ naa ni odunwo millionu meji naira pẹlu oniduro meta ti meji gbudọ jẹ ibatan rẹ.