APC fẹ́ fi ẹ̀ka ìdájọ́ dojú ìjọba àwaarawa bolẹ̀ - Atiku

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Alhaji Atiku Abubakar ti fẹ̀sùn kan ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ń lo ẹ̀ka ètò ìdájọ́ láti fi tẹ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò lórí mọ́lẹ̀.

Atiku sọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn yọ àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò mẹ́rin nípò.

Àwọn ìpínlẹ̀ náà ni Zamfara, Plateau, Kano àti Nasarawa.

Ó ní ìjọba ń sá sábẹ́ ẹ̀ka ètò ìdájọ́ láti fi gba àwọn ìpínlẹ̀ náà ni tipátipá lọ́wọ́ ẹgbẹ́ alátakò.

Àmọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC jiyàn àwọn ẹ̀sùn tí igbákejì Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní Nàìjíríà náà fi kàn wọ́n.

Atiku Abubakar ni orin tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ APC ń mú bọ ẹnu ni pé àwọn fẹ́ tẹ àwọn ẹgbẹ́ alátakò rì pátápátá àti pé ọ̀rọ̀ náà ti yé àwọn báyìí.

Agbẹnusọ fún Atiku Abubakar, Abdurrashid Shehu sọ fún BBC pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC ń fẹ́ dojú ìjọba àwaarawa bolẹ̀ ni.

"Ẹ̀ka ètò ìdájọ́ tó yẹ kó dá dúró ni wọ́n ti tọwọ́bọ̀ láti máa fi gba àwọn ìpínlẹ̀ kiri."

Ó ní kí ìjọba túwọ́ lọ́rùn ẹ̀ka ìdájọ́ kí ìjọba àwaarawa ní Nàìjíríà má bá a dojú délẹ̀ pátápátá.

Ẹlẹ́nu méjì ni Atiku - APC

Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ti ní ẹnu méjì ni Atiku máa fi sọ̀rọ̀ àti pé kì í dúró lójú kan láti fi mọ́ ibi tí ó fì sí.

Agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Mallam Bala Ibrahim ní Atiku you Abubakar ń kan sáárá sí ẹ̀ka ètò ìdájọ́ nígbà tí ilé ẹjọ́ da láre lórí ẹjọ́ tó pè tako Ààrẹ àná ní Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo.

Ibrahim ní Atiku Abubakar máa ń sọ ọ́ nígbà náà pé ẹ̀ka ètò ìdájọ́ Nàìjíríà ń mú ìṣèjọba àwaarawa dúró ire si ni.

Ó ní àmọ́ nítorí ìdájọ́ kò lọ bó ṣe ń fẹ́ ni ó ṣe ń bu ẹnu àtẹ́ lu ẹ̀ka ìdájọ.

Àwọn ìpínlẹ̀ tí àwọn ìdájọ́ yìí ti wáyé ní ojú Ọlọ́run ni àwọn ń wò báyìí.

Olùrànlọ́wọ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Nasarawa lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú, Adamu Musa Alkali ni àdúrà ni àwọn ń gbà sí Ọlọ́run kí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ lọ bí àwọn ṣe fẹ́.

Ó ní àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ náà ló dìbò yan àwọn sípò tí àwọn sì ní ìgbàgbọ́ pé pẹ̀lú àdúrà, àwọn máa mókè nílé ẹjọ́ tó ga jùlọ.