Wo àwọn gómìnà tí ilé ẹjọ́ ti yọ nípò lẹ́yìn oṣù mẹ́sàn án tí wọ́n wọlé ìbò

Oríṣun àwòrán, Plateau State Government
Lọjọ Aiku to kọja ni ile ẹjọ kotẹmilọrun paṣẹ pe ki ajọ Inec gba we ẹri moyege lọwọ gomina ipinlẹ Plateau, Caleb Mutfwang ti ẹgbẹ PDP ki o si fun Nentawe Goshe ti ẹgbẹ oṣẹlu APC wi pe oun gan an lo jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ naa to waye lọjọ kejidinlogun oṣu kẹta ọdun 2023.
O kere tan ile ẹjọ ti yọ gomina mẹta nipo kaakiri orilẹede Naijiria tawọn ẹgbẹ oṣelu alatako ti gbe lọ sile ẹjọ pe wọn ko wọle ibo gomina ti ajọ Inec ti kede wọn gẹgẹ bi oludije to jawe olubori.
Awọn gomina ko lo ju oṣu mẹsan an pere lọ ti ile ẹjọ fi yẹ aga mọ wọn nidi,
Wọnyii ni awọn gomina ti ile ẹjọ ti yọ nipo ati idi abajọ:
Abba Kabir Yusuf (NNPP) Kano
Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ eleto idibo Inec ṣe sọ, Abba Kabir Yusuf ti ẹgbẹ oṣelu NNPP ri ibo 1,019,602 lati jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ Kano, nigba ti oludije APC, Nasir Gawuna ṣe ipo keji pẹlu ibo 890,705.
Amọ igbimọ igbẹjọ ‘’tribunal’’ ẹlẹni mẹta to n gbọ awuyeawuye lori ibo gomina ninu eyi ti Adajọ Akintan Osadebay wọgile ibo to gbe Gomina Yusuf ni ogunjọ oṣu kẹsan an ọdun yii wọle.
Ileẹjọ Triunal sọ ninu idajọ rẹ pe ibo 165,663 ti Yusuf ni lo jẹ ayederu nitori osisẹ ajọ eleto idibo INEC ko buwọlu iwe ibo naa.
Bakan naa ni ileẹjọ kotẹmilọrun to joko niluu Abuja wọgile ibo to gbe Gomina Yusuf,
Ile ẹjọ kotẹmilọrun fontẹ lu idajọ ileẹjọ ‘’tribunal’’, o si dajọ wi pe Nasiru Gawuna oludije ẹgbẹ oṣelu APC lo wọle ibo ọhun.
Abdullahi Sule (APC) Nasarawa
Ile ẹjọ ‘’tribunal’’ ẹlẹni mẹta to n gbọ awuyeawuye lori ibo gomina wọgile ibo to gbe gomina ipinlẹ Nasarawa, Abdullahi Sule ti APC wọle ninu oṣu Kẹwaa.
Ile ẹjọ naa paṣẹ pe ki ajọ Inec gba iwe ẹri moyege lọwọ rẹ ki o si fun David Ombugadu ẹgbẹ oṣelu PDP.
Igbimọ igbẹjọ ni Ombugadu lo wọle ibo naa.
Igbimọ igbẹjọ eleyii ti Adajọ Ezekiel Ajayi dari wọn ṣe iyọkuro ibo eeru to wa ninu ibo ti Inec ka fun Sule wọn si roo pọ mọ ibọ ti adinku ba tẹlẹ.
Igbesẹ yii da lori awọn iwe idibo EC8A ti olupẹjọ mu wa sile ẹjọ gẹgẹ bi ẹri.
Ẹwẹ, ile ẹjọ kotẹmilọrun ninu Abuja sun idajọ rẹ siwaju lori ẹjọ kotẹmilọrun ti Sule pe.
Dauda Lawal (PDP) Zamfara
Dauda Lawal ẹgbẹ oṣelu PDP ni ajọ Inec kede ré gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu ibo gomina ipinlẹ Zamfara.
Inec ni Lawal fidi gomina Bello Metawalle APC gbalẹ ninu ibo ọhun eleyii to jẹ ki Metawalle gba il ẹjọ lọ.
Amọ, igbimọ igbẹjọ ‘’tribunal’’ yi ẹjọ naa danu, o ni ko lẹsẹ nlẹ.
Ṣugbọn, ile ẹjọ kotẹmilọrun paṣẹ pe ki atundi ibo waye ni ijọba ibilẹ meji nipinlẹ Zamfara.
Ile ẹjọ ni Metawalle to jẹ minisita keji fun eto abo bayii wi awijare lori awọn ibo ti ko tọna.
Caleb Mutfwang (PDP) Plateau
Nentawe Goshe oludije ẹgbẹ oṣẹlu APC gbe gomina Caleb Mutfwang lọ sile ẹjọ pe PDP ko fa fa kalẹ lọna ẹtọ lati jẹ aṣoju ẹgbẹ naa ninu ibo gomina ipinlẹ Plateau.
Amọ, igbimọ igbẹjọ ẹlẹni mẹta ti adajọ R. Irele-Ifijeh jẹ adari wọn yi ẹjọ naa danu, wọn ni ko fẹsẹ mulẹ.
Igbimọ igbẹjọ kotẹmilọrun eleyii ti Adajọ Elfrieda Williams-Dawodu dari wọn dajọ lọjọ Aiku to lọ pe PDP ko yan goimina Mutfwang lati ṣoju rẹ ninu ibo gomina ipinlẹ Plateau gẹgẹ bi alakalẹ ẹka 177 iwe ofin Naijiria.















