Wọ́n ti fi òkú Mohbad sílẹ̀ tipẹ́, bàbá rẹ̀ ni kò jẹ́ kí á sin ín - ìyá Mohbad pariwo

Aworan Mohbad

Oríṣun àwòrán, @IAMMOHBAD/INSTAGRAM

Arabinrin Olumiyi ti i ṣe iya akọrin takasufee to d’oloogbe, Ilerioluwa Aloba, ti ọpọ mọ si Mohbad ti ke gbajare pe wọn ti jọwọ oku Mohbad fun sinsin ṣugbọn baba rẹ, Ọgbẹni Joseph Aloba ni ko jẹ ki wọn tii sin Mohbad di akoko yii.

Arabinrin Olumiyi fọrọ yii lede ninu fidio kan to ṣe eleyii to wa kaakiri ori ayelujara lọjọ Iṣẹgun.

Arabinrin naa kepe awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn bẹ baba Mohbad lati lọ gba oku ọdọmọde akọrin naa lati ọdọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko ki wọn le sin in.

Iya Mohbad sọ ninu fidio naa pe lati igba ti wọn ti pari ayẹwo oku Mohbad ni ẹbi rẹ ti lanfaani lati gbe oku rẹ fun sinsin.

‘’Ọmọ Naijiria, ẹ jọwọ ẹ bami gba oku ọmọ mi, mo gbadura pe ẹ ko ni ri iku ọmọ.

Baba Mohbad ni ko tii jẹ ki a sin in, bi tilẹ jẹ pe mo ti bẹ ẹ ni aimọye igba.

Koda mo ti lọ ba kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Eko lọsẹ to kọja, o sọ fun mi pe awọn ti jọwọ oku Mohbad.

Ọga ọlọpaa beere lọwọ mi pe kilode ti n ṣe n fi oku Mohbad rare,’’ iya Mohbad ṣalaye.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Bakan naa ni arabinrin Olumiyi rawọ ẹbẹ si aarẹ Bola Tinubu, awọn ọdọ nile ati loke okun to fi mọ awọn ọeẹ oloogbe wi pe ki wọn dide iranwọ si oun.

O ni lati igba ti wọn ti hu oku Mohbad ni ẹmi rẹ ti n rin kaakiri eyi ti ko ko fun oun gan an ni ibalẹ ọkan.

Iya Mohabd ni ‘’gbogbo ẹyin ti ẹ lọ hu oku Mohbad lo yẹ ki ẹ panu pọ pe ki wọn sin in bayii.

Kii ṣe pe mi o fẹ sọrọ lati ọjó yii pẹlu gbogbo ohun ti baba Mohbad n sọ, amọ, mo ti fija fun Ọlọrun ja.’’

Ti ẹ o ba gbagbe, baba Mohbad ti sọ pe ẹnikẹni ko gbọdọ gba oku ọmọ oun lati sin in lẹyin oun.

Lọjọ Aiku to lọ yii ni Ọgbẹni Aloba sọrọ yii ninu fidio kan lori TikTok.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fèsì lórí àyẹ̀wò èsì òkú Mohbad lẹ́yìn oṣù méjì tí wọn hú òkú rẹ̀

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko ti ní àwọn kò ì tíì rí èsì àyẹ̀wò òkú Mohbad gbà láti oṣù méjì tí wọ́n ti ṣàyẹ̀wò náà.

Lónìí, ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kọkànlá ọdún 2023 ló pé oṣù méjì tí wọ́n hú òkú gbajúmọ̀ olórin tàkasúfèé náà lẹ́yìn tí ikú rẹ̀ fà awuyewuye lórí ayélujára.

Lẹ́yìn tí Mohbad jáde láyé lọ́jọ́ Kejìlá oṣù Kẹsàn-án, ni ikú rẹ̀ fa awuyewuye lórí ayélujára.

Àwọn ènìyàn sì ní dandan kí wọ́n tú iṣu dé ìsàlẹ̀ kòkò láti mọ ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀.

Èyí ló mú Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá hú òkú rẹ̀ láti ṣèwádìí ohun tó ṣekúpa á.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá Eko lẹ́yìn tí wọ́n ṣàyẹ̀wò "autopsy" náà tán fi sórí ayélujára rẹ̀ pé ìwádìí ti parí, pé èsì àyẹ̀wò náà ló kù báyìí.

Ẹ́bí Mohbad le sọ fún agbẹjọ́rò wọn láti kọ̀wé ránṣẹ́ sí àwọn dókítà tó ṣe àyẹ̀wò òkú Mohbad, láti mọ̀ bóyá èsì àyẹ̀wò náà ti ṣetán"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n ba ileesẹ iwe iroyin Punch sọrọ lori esi ayẹwo oku Mohbad naa, Hundeyin ní àwọn dókítà tó ṣàyẹ̀wò òkú náà kò ì tíì fi èsì rẹ̀ lé àwọn ọlọpaa lọ́wọ́.

Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ti ń gbé ìròyìn kiri lórí ayélujára pé èsì náà ti wà nílẹ̀, ó ní àwọn kò ì tíì ri gbà lọ́dọ̀ àwọn to se ayẹwo oku naa.

"Nígbà tí a bá gbà á, tí a buwọ́lu ìwé pé a ti gba èsì náà la máa fi léde àti pé àwa kìí tẹ̀lé àhesọ ọ̀rọ̀."

Bákan náà ló fi kun pé àwọn ẹbí Mohbad le sọ fún agbẹjọ́rò wọn láti kọ̀wé ránṣẹ́ sí àwọn dókítà tó ṣe àyẹ̀wò òkú Mohbad láti mọ̀ bóyá èsì àyẹ̀wò náà ti ṣetán.

Ó ní tí wọn kò bá le ṣe bẹ́ẹ̀, àwọ́n ní láti dúró títí tí wọ́n máa fi àyẹ̀wò ọ̀hún lé àwọn lọ́wọ́.

Bẹẹ ba gbagbe, sáájú ni àwọn kan ti ń ké sí Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá pé kó gbé òkú Mohbad fún àwọn láti lọ sìn.

Nínú oṣù Kẹwàá ọdún 2023 ni kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Eko lásìkò náà, Idowu Owohunwa, dárúkọ àwọn afurasí kan lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wọ́n sì gbé wọn lọ sí ilé ẹjọ́.

Ní ọjọ́ Ẹtì tó kọjá ni Naira Marley àti Sam Larry kúrò ní àhámọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ fún wọn ní béèlì láti máa wá jẹ́jọ́ láti ilé.

Àkọlé fídíò, Lalaa: Bàbá mi bímọ tó pọ̀,ìwé mẹ́fà ló máa ń tọ́ ọmọ, ìṣẹ́ Fọga ni wọ́n fẹ́ kí ń kọ́

Màá ṣe àyẹ̀wò DNA fọ́mọ Mohbad, kí wọn tó sin-ín, ẹ má gba òkú ọmọ mi lẹ́yìn mi - Bàbá Mohbad

Mohbad ati Baba re

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Joseph Aloba, tíí ṣe bàbá gbajúmọ̀ akọrin tàkasúfèé nnì, Oladimeji Aloba tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Mohbad, ti ní ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ gbìyànjú láti sin òkú ọmọ òun lẹ́yìn òun.

Nínú fídíò kan tó fi sórí ayélujára Facebook, ni bàbá Mohbad ti ń sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn kan ṣe ń pè fún pé kí wọ́n gbé òkú ọmọ náà kalẹ̀ fún àwọn, kí àwọn lọ sin òkú ọmọ náà.

Bàbá ọmọ náà ní ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ lọ gba òkú ọmọ òun láì gba àṣẹ lọ́wọ́ òun.

Ṣáájú ni àwọn kan ti ń ní kí àwọn ọlọ́pàá gbé òkú ọmọ náà sílẹ̀ fún àwọn, kí wọ́n lè sin ọmọ náà bó ṣe tọ́.

"Ó pọn dandan kí àyẹ̀wò DNA wáyé fún Liam, ọmọ Mohbad, kí wọn tó sin bàbá rẹ̀"

Èyí ló mú kí bàbá Mohbad fi ọ̀rọ̀ léde lórí ayélujára pé òun kò lọ́wọ́ nínú ìpè náà.

Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni àwọn ṣì máa ṣe lẹ́yìn tí àwọn bá ti rí ìdájọ́ òdodo gbà lórí ikú ọmọ òun.

Ó fi kun pé àwọn ṣì máa ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ fún ọmọ tí Mohbad fi sáyé, Liam láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ Mohbad gan ni.

"Mo gbọ́ pé àwọn kan fẹ́ lọ sin òkú Mohbad, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dan wò, tí ohunkóhun yóò bá ṣẹlẹ̀, èmi ni mà á fọwọ́ si.

"À ń bèèrè fún ìdájọ́ òdodo lórí ikú Mohbad, wọ́n ń sọ̀rọ̀ òkú sínsin, ẹ jẹ́ kí ìdájọ́ parí lórí rẹ̀ ná.

"Bákan náà ló pọn dandan kí àyẹ̀wò DNA wáyé."

Ẹ ó rántí pé ní ọjọ́ Kejìlá oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023 ni Mohbad jáde láyé.

Bí ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn ikú rẹ̀ ni wọ́n hú òkú rẹ̀ láti ṣe àyẹ̀wò láti mọ ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀.

Àwọn ọlọ́pàá gbé òkú rẹ̀ sí mọ́ṣúárì lẹ́yìn tí wọ́n ṣe àyẹ̀wò òkú rẹ̀.