Boko Haram kọlu ikọ̀ aláàbò gómínà Yobe, ọlọ́pàá kan kú, àwọn mẹ́fà míì farapa

Oríṣun àwòrán, @IntelRegion
Ori ti ko gomina ipinlẹ Yobe, Mai mala Buni yọ lọwọ iku ojiji lẹyin ti awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ Boko Haram kọlu ikọ ẹṣọ alaabo rẹ loju ọna marosẹ Jakana si Mainok, nipinlẹ Borno.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Yobe, DSP Dungus Abdulkarim, lo fidi iroyin naa mulẹ fun BBC Yoruba.
Iroyin ni ọlọpaa kan jade laye lasiko ikọlu naa, nigba ti eeyan mẹfa mii farapa.
Ki ilọlu naa ṣe waye
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ikọ ẹṣọ alaabo naa tẹle gomina ọhun lọ siluu Maiduguri fun ayẹyẹ ikẹkọọjade fasiti naa ilu Maiduguri, nibi ti wọn ti fun igbakeji Aarẹ Naijiria, Kashim Shettima ni oye Ọmọwe.
Ẹwẹ, awọn agbesunmọmi naa ko mọ pe gomina Mai Mala Buni ko tẹle ikọ ẹṣọ alaabo rẹ pada sipinlẹ Yobe.
A gbọ pe gomina naa duro si Maiduguri nigba ti awọn ẹṣọ alaabo rẹ pada si Yobe nitori o n mura lati gba ilu Maiduguri lọ si Abuja fun iṣẹ mii.
Asiko ti awọn ẹṣọ alaabo gomina naa pada ni ikọlu naa waye, bo tilẹ jẹ pe ko tẹle wọn.
Ileeṣẹ iroyin abẹle Punch jabọ pe agbẹnusọ gomina ọhun, Mamman Mohammed sọ pe ṣe ni ikọ agbesunmọni ọhun atawọn ọlọpaa doju ibọn kọ ara wọn, nibi ti ọlọpaa mẹta ti farapa.
Mamman ṣalaye pe awọn ọlọpaa naa bori awọn agbesunmọmi ọhun, awọn to farapa si ti n gba irọju.
Mamman ni “Gẹgẹ bi ẹyin naa ṣe mọ, awọn akọṣẹmọṣẹ agbofinro wa doju ibọn kọ awọn agbebọn naa, eyii to mu ki awọn agbesunmọmi ọhun ṣa pada sẹyin.”
“Amọ o ṣeni laanu pe ọlọpaa kan padanu ẹmi rẹ, nigba ti ọmọ ogun meji, awakọ kan, ọlọpaa mẹta ati oṣiṣẹ DSS kan farapa.”
Lẹyin ikọlu naa ni awọn ẹṣọ alaabo ọhun balẹ siluu Damaturu, nibi ti wọn ti ko awọn to farapa lọ sile iwosan.













