Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí kan lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ Offa poly

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ti nawọ́ gán afurasí kan lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga gbohbonìṣe ti ìjọba àpapọ̀ tó wà ní ìlú Offa, ìpínlẹ̀ Kwara, Toyin Bamidele.
Àtẹ̀jáde kan tí kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kwara, Victor Olaiya fi síta lọ́jọ́ Àìkú ní àwọn kan pa akẹ́kọ̀ọ́ náà sínú yàrá rẹ̀ tó wà ní agbègbè Dapson ní Offa lọ́jọ́bọ̀.
Olaiya ṣàlàyé pé ní nǹkan bíi aago márùn-ún kọjá ogún ìṣẹ́jú lọ́jọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kọkànlá ni àwọn kan lọ fi tó Ọ̀gá àgbà Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Offa létí pé àwọn kan ti pa Toyin sínú yàrá rẹ̀.
Ó ní kété tí àwọn gbọ́ ìròyìn ni àwọn ọlọ́pàá lọ sí ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.
"A ri pé àpá wà níbi ojú àti ọrùn òkú Toyin nígbà tí a débẹ̀, bí ẹni pé òun àti ènìyàn kan jà."
Ọ̀gá ọlọ́pàá náà tẹ̀síwájú pé nígbà tí àwọn fi máa gbe dé ilé ìwòsàn Wale Clinic and Hospital, àwọn dókítà ní ó ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.
Ó ní àwọn ti gbé òkú náà sí mọ́ṣúárì fún àyẹ̀wò tó péye.
Ó fi kun pé ọwọ́ ti tẹ afurasí kan lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti pé afurasí ń ran àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ lórí ìwádìí wọn.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ní wí pé àwọn kò ní kó àárẹ̀ ọkàn láti ri dájú pé àwọn tú iṣu dé ìsàlẹ̀ kòkò lórí ìwádìí ọ̀hún.
Bákan náà ló rọ àwọn ará ìlú láti wà ní ojú lalákàn fi ń ṣọ́rí, pàápàá lásìkò yìí, kí wọ́n sì ri dájú pé wọ́n ń fi ẹ̀sùn àwọn ìwà kòtọ́ tàbí ti àjèjì tí wọ́n bá ń rí ní agbègbè sun ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá tó bá súnmọ́ wọn.
Afurasí agbébọn ṣá akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Offa Poly pa nínú yàrá rẹ, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Oríṣun àwòrán, Facebook/Offa Poly
Inu ibẹru nla lawọn akẹkọo ile ẹkọ gbogboniṣe ti ijọba apapọ to wa niluu Ọffa, Federal Polytechnic Ọffa, paapaa awọn akẹkọọ ati olukọ ẹka Food Technology bayii lẹyin ti awọn agbebọn kan ṣa ọkan lara akẹkọọbinrin kan pa.
Orukọ oloogbe naa ni Toyin Bamidele.
Gẹgẹ bii iroyin to tẹ BBC Yoruba lọwọ, Ọjọbọ, ọjọ Kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii ni iṣẹlẹ naa waye, bẹẹ ni ko si ẹni to le sọ boya iṣẹ ọwọ awọn adigunjale ni tabi awọn agbenipa.
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, alukoro ile ẹkọ ọhun, arabinrin Folake Oyinloye, fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni wọn ṣa akẹkọọ naa pa, inu yara ẹ gan-an ni wọn si ṣeku pa a si.
O ni ko si ẹnikẹni to mọ nnkan to ṣẹlẹ ki iṣẹlẹ naa too waye, ile rẹ to yalo ni agbegbe ile ẹkọ to n gbe si ni wọn pa a si, iwadii si ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.
O fi kun un pe, ‘‘Titi di asiko yii, a ko mọ idi ti wọn fi pa akẹkọọ naa.”
“Bakan naa ni ko sẹni to mọ awọn to ṣiṣẹ ọhun, ṣugbọn nnkan ta a le fidi ẹ mulẹ ni pe wọn sa pa a ni.”
“Awọn alaṣẹ ile ẹkọ atawọn ẹsọ alaabo ti n ṣiṣẹ papọ lati wa awọn amookun ṣeka naa lawari ti wọn a si foju wina ofin tọwọ ba tẹ wọn."
Oyinloye ṣapejuwe iku akẹkọọ naa bii eyi to gbomi je loju ẹni, to si tun ba ni lọkan jẹ ati pe adanu nla ni ku rẹ jẹ fun gbogbo awọn alaṣẹ ati oṣiṣẹ Offa Poly.
O ni awọn alaṣẹ gbadura ki Ọlọrun ṣe iku ni iṣinmi fun un, ko si rọ mọlẹbi loju ki wọn le fara gba iru adanwo naa.
Agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, SP Okasanmi Ajayi ti fidi ọrọ naa mulẹ.
O ni lootọ ni oun gbọ nipa iṣẹlẹ laabi ọun sugbon oun si n sewadii sii lori rẹ.













