Ọ̀pọ̀ agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Áfíríkà làwọn ẹbí wọn máa dúnkokò mọ́ láti gbowó lọ́wọ́ wọn - Mikel

Aworan John Mikel Obi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbabọọlu tẹlẹri fun ikọ Super Eagles ati Chelsea, John Mikel Obi ni pupọ awọn agbabọọlu ilẹ adulawọ LO n san owo to sapajuwe gẹgẹ owo ori lati fi ṣe iranlọwọ fun mọlẹbi ati awọn eeyan to n reti wọn fun owo.

O ni pupọ awọn agbabọọlu yii lo n koju idunkoko lati ọwọ mọlẹbi ti wọn ba kọ lati fun wọn ni owo.

“Ti o ba wa lati ilẹ Afrika, eyi lo n jẹ nnkan ti a ki i sọrọ nipa ni ọpọ igba, to ba ti sisẹ ni owo, ko ki n ṣe owo rẹ nikan mọ” Mikel sọ eyi ninu ifọrọwerọ pẹlu Rio Ferdinand.

“O ni mọlẹbi kaakiri, ọmọ ẹgbọn, ọmọ aburo ati awọn mii.

”Awọn ẹgbọn ati aburo rẹ obinrin, wọn yoo lọ lọkọ. Ọkunrin fẹ fẹ wọn nitori wọn jẹ mọlẹbi John Mikel Obi ti aye rẹ dara.

“Wa ma ṣe itọju ọkunrin yii, wa fi owo ransẹ si mọlẹbi rẹ, wọn yoo fun ọkọ wọn lowo, ti yoo ṣe bi o ṣe fẹ.

“Eyi jẹ nnkan ti ọpọ eeyan ko ki sọrọ nipa, owo rẹ ki ṣe owo rẹ nikan.

“Wa gba owo oṣu, wa ni owo yii fun eeyan kan, eyi fun ẹlomiiran, owo yii fun iya ati baba rẹ, ko to mọ owo ti tan lọwọ rẹ.

“Aṣa ni eyi ni ilẹ adulawọ. Gbogbo wọn n reti pe ko ṣe nnkan fun wọn nitori o jẹ wọn nikan.

“A ni lati sọ nipa nnkan yii. Pupọ awọn ọdọ agbabọọlu to n bọ lẹyin wa ni a ni lati mọ awọn nnkan yii nitori awọn naa yoo la nnkan yii kọja.

“Wọn ni lati mọ bi wọn yoo ṣe koju awọn nnkan yii.”

Mikel ni awọn agbabọọlu lati pinnu ọkan wọn pe awọn ko fẹ ran mọlẹbi kankan lọwọ ti yoo ba ti lẹyin.

“Igba miiran, eeyan ni lati sọ pe o to gẹ, mi o ṣe mọ. Fun emi, akoko yii wa fun nibi nnkan bi ọdun marun un sẹyin.

Aworan John Obi Mikel

Oríṣun àwòrán, Getty Images

“Mo ni o to gẹ nitori mo ti n ṣe nnkan yii lati igba ti mo tibẹrẹ si ni gba bọọlu.

“Mo di eeyan buruku, Wọn ko ni gbe ipe rẹ mọ. O ti mọ wọn lara lati pe, ki ṣe pe wọn fẹ mọ boya alaafia lo wa sugbọn lati bere pe ki lo fẹ fun wọn.

“Eeyan ni lati ṣe ọkan akin. Mo n fun mọlẹbi mi ni ọpọlọpọ nnkan.

Mikel ni ọpọ igba ni awọn agbabọọlu n koju idunkoko lati ọwọ mọlẹbi .

“Wọn yoo ma sọ nnkan bii, ti o ko ba fun wọn lowo, wọn yoo lọ ọdọ awọn akọroyin.

“Wa ma ro pe, ṣe mọlẹbi re lẹyin ọpọlọpọ nnkan ti mo ti ṣe fun yin?’