Kàyééfì! Wo bi Israel ṣe ń lo ẹyẹ ìdì láti wá òkú àwọn tó bá ìkọlù Hamas lọ

Àkọlé fídíò, Wo bí Israel ṣe ń lò ẹyẹ láti ṣàwárí àwọn òkú làwọn ibùdó tí Hamas ṣe ìkọlù sí.
Kàyééfì! Wo bi Israel ṣe ń lo ẹyẹ ìdì láti wá òkú àwọn tó bá ìkọlù Hamas lọ

Airinjina lairi abuke ọkẹrẹ, kayeefi lo jẹ fun ọpọlọpọ bi orileẹde Israel ti n lo ẹyẹ idi oniru funfun

lati ṣawari awọn oku lawọn ibudo ti Hamas ṣe ikọlu si.

Ohad Hatzofe jẹ onimọ nipa ayika ati nkan abẹmi.

O ṣalaye pe "iṣẹ mi ni ki n mojuto awọn ẹyẹ ti a fi GPS si lara,

lati ṣayẹwo awọn ti ko ti i ku, awọn to n lọ to n bọ.

Igba akọkọ ree ti ayẹwo bayii yoo waye, a si yege ninu wiwa awọn eeyan to sọnu.

Bi olugbala wa ṣe rin niyẹn."

Ni ogunjọ oṣu Kẹwaa, ẹyẹ naa fo pada lọsi orilẹede Israel.

Awọn ijọba bẹ dide nigba to balẹ si Israel.

"Lẹyin ikọlu ọjọ kẹjọ oṣu Kẹwaa,

Ọgọrun-un oku...

ni a ti ṣawari ṣugbọn awọn kan ṣi wa ta a ri.

O ye wa pe ebi a ti maa pa ẹyẹ naa nitori pe o n fo latọna jinjin, ko dẹ lo to wakati mẹrinlelogun

ko to de si iwọ oorun Negev, ti o jinna si Gaza.

O si fo lọ si ibi ikọlu ti ṣẹlẹ gan-an gan-an laaarin Reim ati Be'eri," Hatzofe ṣalaye.

Ẹyẹ idi ṣe iranwọ fun awọn olufarajin ṣiṣẹ lati ṣawari oku mẹrin...

ati ẹya ara to wa layika.

Hatzofe ni "ẹyẹ idi oniru funfun jẹ ọkan ẹyẹ idi ti o ti o parun lorileẹde Israel.

Ati eyi ti a n gbiyanju lati dapada pẹlu ọpọlọpọ inawo ati akitiyan.

O ṣi n sa ipa rẹ, lati ran wa leti pe a ni lati gbiyanju sii

lati ma jẹ kawọn ẹyẹ meji to ku naa ọ s'oko ìparun."