Ohun tí a mọ̀ nípa ìkọlù Israel sí ilé-ìwòsàn Al-Shifa

Awọn ọmọ ogun Israel ni ile iwosan Al-Shifa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Aworan ti ikọ IDF pese to n ṣafihan bi awọn ọmọ ogun Israel ṣe yawọ ile iwosan Al-Shifa
    • Author, Sam Hancock
    • Role, BBC News

Awọn ọmọ ogun ilẹ Israel lo ti wọ ile-iwosan to tobi julọ ni Gaza ninu nkan ti wọn juwe bii "akọlu to doju kọ awọn ẹgbẹ Hamas".

Osijumikoro kan nile-iwosan al-Shifa wi fun BBC pe awọn ologun naa lo n rin kiri ile-iwosan naa loru ti wọn si n fi ọrọ wa awọn eniyan lẹnu wo.

Lati ọjọ pipẹ ni Israel ti fẹsun kan Hamas pe wọn ni ibudo kan labẹ ile-iwosan naa ti ilẹ Amẹrika si wi pe iwadi awọn fi idi ẹsun naa mulẹ, amọ ti Hamas sẹ ọrọ naa.

Ajọ iṣọkan agbaye lo ti kọminu lori bi wọn ṣe fẹẹ sọ ile-iwosan di oju ogun, ti ajọ eleto ilera agbaye si wi pe awọn n foya fun awọn oṣiṣẹ atio alaarẹ nile iwosan naa ni bi wọn ko ṣẹ lee bawọn sọrọ mọ.

BBC n ba akọroyin kan ati dokita sọrọ nile iwosan naa lati mọ ohun to n ṣẹlẹ nibẹ amọ a ko lee fidi awọn iroyin ti awọn ọmọgun ilẹ Israel n fi lede mulẹ.

Ohun tí mo rí nínú ilé-ìwòsàn

Khader, to jẹ akọroyin kan ninu ile-iwosan naa ṣalaye fun Rushdi Abualouf ti BBC pe awọn ọmọgun Israel ni wọn ti gba iṣakoso ile-iwosan naa ti ko si si ibọn yinyin kankan.

O wi pe ọkọ afaragbọta mẹfa ati ọgọrun ọmọ-ogun ni wọn wọ ile-iwosan naa loru mọju, ti wọn si wọ gbogbo iyara nile-iwosan naa lati le awọn ọkunrin ti wọn wa laarin ọdun mẹrindinlogun si ogoji ọdun jade sita gbangba ki wọn lee yẹ wọn wo finni-finni.

Ọga agba awọn ile-iwosan lẹkun Gaza, Muhammad Zaqout, ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin Al Jazeera wi pe wọn ko yin ọta ibọn kan ninu ile-iwosan naa tori ko si awọn alatako tabi ẹni ti wọn gbe pamọ nibẹ.

Israel júwe ìkọlù wọn tó dojú kọ Hamas

Awọn ọmọgun ilẹ Israel, IDF, ni wọn ṣalaye lọjọ iṣẹgun pe awọn n gbe awọn igbesẹ kan laarin kan nile-iwosan al-Shifa to doju kọ awọn ẹgbẹ Hamas.

Wọn juwe igbesẹ yii gẹgẹ bii ohun to yẹ latari ifimufinlẹ ti wọn ṣe, ti wọn si ni ki gbogbo ọmọ ẹgbẹ Hamas to ba wa nile-iwosan naa o jade sita lati jọwọ ara wọn.

laarọ Ọjọru, ọga agba kan ni IDF ti ko fi orukọ ara rẹ lede sọ fun awọn akọroyin pe awọn ti ohun ija ogun atawọn irinṣẹ agbesunmọmi ninu ile-iwosan naa, amọ ko fi ẹri lede.

Redio awọn ọmọgun ilẹ israel wi pe wọn ko tii ri ẹnikẹni ninu awọn ti Hamas ji gbe lọjọ keje ọsu kẹwa nibẹ.

Awọn oṣiṣẹ ile iwosan al-Shifa

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn oṣiṣẹ ile iwosan al-Shifa ni ọjọru

Wiwọ ile-iwosan ọhun lo waye laipẹ si akoko ti ilẹ Amẹrika - fun igba akọkọ - ṣe atilẹyin fun ẹsun Israel pe awọn Hamas ni ibudo lbẹ ile-iwosan naa.

Agbẹnusọ eto abo fun ilẹ Amẹrika, John Kirby, wi pe awọn ni ẹri to daju latọwọ oriṣiriṣi ọtẹlẹmuyẹ to fidi rẹ mulẹ pe Hamas n lo awọn ile-iwosan ni Gaza atawọn ọna inu ilẹ to wa labẹ wọn lati ko ohun ija ogun ati awọn ti wọn ji gbe pamọ.

O wi pe "Hamas ati awọn ajijangbara Palestine ni ibudo ipaṣẹ ni al-Shifa ati pe yoo ṣoro diẹ fun awọm ọmọgun Israel to ri pe awọn Hamas darapọ mọp awọm araalu pupọ".

Ẹwẹ, Dokita Ahmed Mokhallalati, to jẹ oniṣẹ-abẹ ni al-Shifa sọ fun BBC pe oun ko ri ohun to jọ ibọn abi ọmọ ẹgbẹ Hamas kankan nile-iwosan naa ri toripe araalu nikan lo wa nibẹ.

Bakan naa lo wi pe gbogbo ile to wa ni Gaza ni ọna gba abẹ rẹ kọja, to fi mọ al-Shifa.

Nkan n burú síi

Agbegbe al-Shifa ni wọn wi pe ija to lagbara ti n ṣẹlẹ lati ọjọ diẹ sẹyin, leyi to se awọn to n ga itọju nibẹ mọle.

Dokita Mokhallalatilakoko to n ba BBC sọrọ l'Ọjọru ọsẹ yii wi pe ile-iwosan naa ko ni omi, afẹfẹ ati omi.

Ni ọjo Iṣẹgun, ọpọlọpọ iṣẹ abẹ ni wọn ṣe lai si ogun akunniloorun leyi to mu ki awọn to n gba itọju o maa kigbepẹlu irora, to si faa ti ko fi lee si iṣẹ abẹ kankan ni Ọjọru.

Ẹni kan to jona lọjọ Iṣẹgun ni awọn dokita ko lee ṣe iranwọ fun tori pe ko si ohun elo, to fi mọ ẹrọ atẹgun, leyi to jẹ ki wọn fii silẹ to fi gbẹmi mi.

Ẹwẹ, awọn ọmọ mẹfa ti wọn bi laipe ọjọ ni wọn ti dagbere faye ti Dokita Mokhallalati si wi pe oun n kọminu pe wọn yoo ṣi ju bẹẹ lọ tori aisi atẹgun ti wọn yoo mi simu, bo tilẹ jẹ pe awọn IDF wi pe awọn n pese ounjẹ ọmọde, ile itọju ọmọ ti wọn bi laipe ọjọ ati awọn ohun itọju alaarẹ miran.

Babies trapped inside Al-Shifa hospital

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọde to n gba itọju ni ile iwosan Al-Shifa

Dokita Mokhallalati beere pe "kilode ti wọn ko fi lee ko awọn ọmọ naa kuro nibi? Ṣe bi wọn ko awọn aja ati olongbo kuro loju ija ni Afghanistan.

Ajọ 'Red Cross' da? Ijọba ilẹ Gẹẹsi ati Amẹrika da? Se gbogbo wọn n reti ka ku tan nibi ki wọn wa maa pe wa ni 'eeyan rere' ni?"

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọgun Israel ti wi ṣaaju pe igbalaye yoo wa fun awọn oṣiṣẹ atawọn alaarẹ lati kuro nibẹ, awọn ọmọ Palestine wi pe niṣe ni awọn ọmọgun Israel doju ibọn kọ wọn ati pe o ṣoro lati ko awọn alaarẹ ti ipalara wọn pọ gan.

Awọn to wa nibẹ wi pe igbe aye buru jayi nile-iwosan naa ni bi awọn mọlẹbi ko ṣe ri ounjẹ ati omi, ti oorun awọn to ti ku tipẹ si gba gbogbo afẹfẹkan.

A kò fẹ́ ìjà ní ilé-ìwòsàn - Amẹ́ríkà

Ṣaaju ki awọn ọmọgun Israel to wọ al-Shifa ni wọn ti wi pe awọn ko nii sẹ akọlu sile-iwosan kankan amọ pe ni tootọ ni ija n waye nitosi awọn ile-iwosan to fi mọ Shifa lati ọjọ diẹ sẹyin.

Lakoko to n sọrọ lori bi Israel Se gbakoso Shifa, ilẹ Amẹrica lo wi pe awọn araalu ati awọn to n gba itọju ni aabo to peye ni lati wa fun, ti ko si yẹ ki ija kankan oi waye nibi tawọn eeyan ti n gbiyanju lati gba itọju.

Akọwe abẹle fun ajọ iṣọkan agbaye, Griffiths, wi pe "aabo awọn ọmọ ikoko, alaarẹ, awọn oṣiṣẹ eto ilera atawọn araalu ju ohunkohun lọ.

Hamas ko lee lo, ko si gbọdọ lo ile-iwosan bii aye ipamọ.

O yemi pe niṣe ni awọn ọmọgun ilẹ Israel n wa awọ adari Hamas. Eyi ko kan awa. Ohun to kan wa ni lati daabo bo Gaza ninu ohun to n ṣẹlẹ nibẹ yii."

Ajọ Red Cross ninu atẹjade kan wi pe awọn "kọminu gidi lori ipa ti igbese ilẹ Isarel yii yoo ni lori awọn alaarẹ, awọn to farapa, awọn oṣiṣẹ eto ilera,atawọ araalu".