Akọ́nimọ̀ọ́gbá Super Eagles ṣetán láti fún Nathan Tella ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ rẹ̀

Aworan Nathan Tella fun ikọ Bayer Leverkusen

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nathan Tella ni ala oun yoo wa si imusẹ to ba kopa fun orilẹede Naijiria ninu ìfẹsẹwọnsẹ fun igbaradi ìdíje agbaye fun ọdun 2026 lọsẹ to n bọ.

Agbawọiwaju fun ikọ agbabọọlu Bayer Leverkusen ni o wa lara awọn ti Naijiria fi iwe pe lati kopa ninu ìfẹsẹwọnsẹ pẹlu Lesotho ati Zimbabwe.

Wọn bí ni Lambeth niluu Gẹẹsi sugbọn o le gba bọọlu fun Naijiria nitori awọn obi rẹ jẹ ọmọ Naijiria

O bẹrẹ pẹlu ikọ ewe agbabọọlu Arsenal

"Mo fe soju ikọ Naijiria," Tella sọ fun BBC Sport Africa.

"Inu awọn mọlẹbi yoo dun lati wo mi rí pe ala mi wa si imusẹ.

"Oun iwuri lo jẹ pe mo je ilẹ Gẹẹsi ati Naijiria sugbọn Naijiria ni ile wa pẹlu asa, oúnjẹ ati ise."

Tella jẹ ọkan lara agbabọọlu to ta yọ fun ikọ Burley ni saa to kọja eyi ti wọn fi pada si idije Ligi Gẹẹsi sugbọn o pada si ẹgbẹ agbabọọlu Southampton ni pari saa.

Agbawọiwaju, to tun le gba ẹgbẹ ni apapọ goolu ati iranlọwọ mejilelogun ni Ligi kejì ilẹ Gẹẹsi ni saa to kọja, to si darapọ mọ Leverkusen ninu oṣu kẹjọ pẹlu ogun milọnu pọnu.

Ikọ ẹgbẹ agbabọọlu rẹ ko ti rí ijakunlẹ lẹyin ìfẹsẹwọnsẹ mẹwaa, ti apa rẹ ninu ìkọ yoo se anfani pupọ fun iwaju ikọ Super Eagles.

Lẹyin tí wọn ko ni anfani lati kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye ni Qatar 2022, ikọ Super Eagles yoo bẹrẹ ìfẹsẹwọnsẹ igbaradi fun ọdun 2026 pẹlu ikọ Lesotho ati Zimbabwe lọjọ kẹrindinlọgbọn ati kọkandinlogun ninu oṣu kokanla.

igbagbọ wa pe Naijiria yoo lewaju ipele C saaju awọn ikọ orilẹede bi South Africa ati Benin lati wa ninu ipele kana pẹlu orilẹede Canada, Mexico ati United States lẹyin ti wọn se adikun si iye awọn orilẹede to fẹ kopa lati mejilelọgbọn si mejidinlaadọtaa.

Ọwọ iwaju Naijiria si wa ni digbi pẹlu bi Osimhen ko se si ni ile

Aworan Victor Osimhen fun ikọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ireti wa pe Akọnimọgba Jose Peseiro yoo gbe ikọ Super Eagles lọ idije efe ẹyẹ agbaye pẹlu awọn agbabọọlu ti musemuse wọn da musemuse lori paapa.

Ikọ Super Eagles ni Agbawọiwaju to jẹ ọkan gboogi to fakọyọ ni ilẹ Europe, to si jẹ oun lo mi awọn ju ni Ligi Seria A, to si tun jẹ ọkan ti wọn do po agbabọọlu to da ju ni ilẹ Afrika, Victor Osimhen sugbọn ko ni anfani lati kopa fun ikọ Super Eagles nitori o farapa.

Awọn yooku bi Victor Boniface, Taiwo Awoniyi, Kelechi Iheanacho ati Terem Moffi naa jẹ Agbawọiwaju to mu isẹ rẹ.

Pẹlu bi ọwọ ṣe kun yìí, ọpọ lo n bẹru ko si awọn agbawọ aarin to pese iranlọwọ.

Lẹyin agbawọaarin ikọ Fulham, Alex Iwobi, ọpọ awọn yooku lo jẹ pe wọn agbawọaarin to n se iranlọwọ fun awọn agbawọẹyin

Ikọ Naijiria ti ṣe àṣeyọrí pẹlu bi wọn ṣe ko àwọn to jẹ pe ilẹ Gẹẹsi ni wọn bi wọn si, bí Ola Aina, Semi Ajayi, Joe Aribo ati Ademola Lookman sinu ikọ agbabọọlu naa, ti igbagbọ si wa pe Tella yoo darapọ mọ wọn.

"Awọn agbabọọlu to wa ninu ìkọ Super Eagles lo koju oṣuwọn, lati pẹlu wọn soju orilẹede Naijiria jẹ ohun iwuri.

"Ikọ Super Eagles jẹ ọkan orilẹede ni ilẹ Adulawọ to fẹran ere bọọlu, ti awọn ololufẹ si jẹ ọkan to yatọ laarin awọn yooku."

Bo tilẹ jẹ pe ko yẹ ki ìfẹsẹwọnsẹ laarin Lesotho ati Zimbabwe nira fun ikọ Super Eagles, sibẹsibẹ idanwo nla ni wọn jẹ fun Naijiria.

Amule Francis Uzoho ni ọpọ bu ẹnu atẹlu lẹyin asise rẹ lasiko ìfẹsẹwọnsẹ to waye ninu oṣu kẹwaa.

Awọn agbabọọlu tí Naijiria pe fun ìfẹsẹwọnsẹ

Amule: Francis Uzoho (Omonia Nicosia, Cyprus), Olorunleke Ojo (Enyimba), Maduka Okoye (Udinese, Italy).

Agbawọẹyin: Ola Aina (Nottingham Forest, England), Chidozie Awaziem (Boavista, Portugal), Bright Osayi-Samuel (Fenerbahce, Turkey), Bruno Onyemaechi (Boavista, Portugal), Kenneth Omeruo (Kasimpasa, Turkey), Semi Ajayi (West Bromwich Albion, England), Calvin Bassey (Fulham, England), Jamilu Collins (Cardiff, Wales).

Agbawọaarin: Raphael Onyedika (Club Bruges, Belgium), Joe Aribo (Southampton, England), Frank Onyeka (Brentford, England), Alex Iwobi (Fulham, England).

Agbawọiwaju: Kelechi Iheanacho (Leicester City, England), Sadiq Umar (Real Sociedad, Spain), Moses Simon (Nantes, France), Ademola Lookman (Atalanta, Italy), Nathan Tella (Bayer Leverkusen, Germany), Taiwo Awoniyi (Nottingham Forest, England), Terem Moffi (Nice, France), Victor Boniface (Bayer Leverkusen, Germany).