Ọlọ́pàá Oyo fojú Auxiliary han síta, ó fẹ̀sùn ìjínigbé, ìdigunjalè àti ìṣekúpani kàn-án

Aworan Mukiala Lamidi ni ahamọ ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Oyo Police

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti fi oju alaga tẹlẹ fun ẹgbẹ awakọ nipinlẹ Oyo, Lamidi Mukaila, ẹni ti ọpọ mọ si Auxillary han ti wọn si ka ẹsun si lẹsẹ.

Bẹẹ ba gbagbe, ninu oṣu yii iroyin jade pe awọn agbofinro lo mu Auxillary lẹyin ọpọlọpọ ọjọ ti wọn kede sita pe wọn n wa.

Iroyin kan fidi rẹ mulẹ pe ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lo lọ gbe alaga igbimọ alamojuto awọn gareeji ọkọ, PMS, tẹlẹri l’Oyo, Auxiliary.

Sugbọn Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti jẹ ko di mimọ pe ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Auxillary wa.

Eṣun ijinigbe, iṣekupani ati idigunjale wa lara ẹsun ti wọn fi kan Auxillary pe wọn furasi pe o lọwọ ninu wọn.

“A ri ohun ija oloro bii ọpọ ibọn, ọta ibọn 724, Ada 25, Ọbẹ Jack 7, ẹrọ ibaraẹnisọrọ 33, ẹrọ kọmputa , oogun abẹnu gọgọ, ọkọ akero Mazda, ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Sienna ati owo toto N3.45m"

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Kọmisana fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Oyo, Adebola Hamzat ni afurasi naa yoo foju ba ileẹjọ laipẹ lati wi tẹnu rẹ lori ẹsun ti wọn fikan.

“Awọn ohun ija oloro ni a ri ni ile rẹ ni agbegbe Alakia-Isebo Egbega labẹ ijọba ibilẹ Egbeda ni ibọn AK47, Ile ọta ibọn mẹrin, ibọn Pumb Action, Ibọn Barreta, Ibọn cut to size ati ibọn oyino kan.

“Awọn yooku ni ọta ibọn 724, Ada 25, Ọbẹ Jack 7, ẹrọ ibaraẹnisọrọ 33, Ẹrọ kọmputa , Oogun abẹnu gọgọ, Ọkọ akero Mazda, Ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Sienna, Owo toto N3.45m.

“Afurasi naa yoo foju ba ile ẹjọ fun awọn ẹsun ti a ka si lẹsẹ."

Ki lo ṣẹlẹ saaju?

Ni oṣu kẹfa ọdun 2023 ni awọn ọlọpaa ti kede Auxillary gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa.

Ikede wọn yii ko pẹ pupọ si asiko ti gomina ipinlẹ Ọyọ, Gomina Ṣeyi Makinde yọ Ọgbẹni Mukaila Lamidi kuro nipo gẹgẹ bi alaga ajọ amojuto gareeji ọkọ nipinlẹ Ọyọ, PMS nigba naa.

Awọn ọlọpaa ṣe ayẹwo ile rẹ, gẹgẹ bi alukoror ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Adewale Oṣifẹsọ ṣe sọ, nigba naa nibi ti wọn ti ba awọn ibọn ati ọta ibọn pẹlawọn ohun ija oloro miran pẹlawọn janduku ni ile rẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ ni awọn n wa Auxillary nigba naa fun awọn ẹsun “igbimọran lati gbẹmi eniyan, ṣiṣe eniyan leṣe, katakara ibọn, ipaniyan, idigunjale ni ipinlẹ yii ati ijinigbe lagbegbe Oke Ogun ati Ibarapa.”

Lati igba naa wa ko si ẹnikẹni to gbọ ohunkohun mọ nipa ọrọ naa ki eyi to ṣẹlẹ.

Ki ni Auxillary sọ saaju ki ọwọ to tẹ?

Ninu ọrọ rẹ saaju ọwọ ọlọpaa to tẹ, Auxillary ti ni gbogbo ohun ti awọn ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo safihan gẹgẹ bi ohun ija oloro ti wọn ko ni ile rẹ ni ko ki se tirẹ rara, ti wọn ko si le kede pe wọn n wa nitori ko tapa sofin tabi wuwa janduku kankan.

Ti a ko ba gbagbe, ija bẹẹ silẹ laarin ẹgbẹ awakọ nipinlẹ Oyo lẹyin ti Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde kede pe ki awọn alakoso paaki nipinlẹ Oyo lọ rọkun ni ilẹ.

Awọn ọlọpaa ni eeyan mejidinlọgọrin ni awọn ko nile 'Auxiliary' lasiko ti wọn ya wọ ibẹ.

Auxillary sọrọ lori eto kan lori redio saaju ki o to dero ahamọ, ni oun ko fi igba kankan tako asẹ Gomina Seyi Makinde nitori olore oun ni.

Auxillary salaye pe Gomina Seyi Makinde lo ni isakoso ipinlẹ Oyo, to si le dari rẹ bi o ṣe fẹ si, ti oun ko si tako asẹ Gomina ni igba kankan.

O ni bi ileeṣẹ ọlọpaa se kede pe wọn wa oun ni ko boju mu, ti ko dẹ ki n se ti toun rara nitori oun koja tabi fa wahala.