Àwọn aláìsàn ọpọlọ tó ń gba ìtọ́jú ní Aro ṣe ìwọ́de, wọ́n gé dókítà jẹ yánna-yànna

Oríṣun àwòrán, Google
Nnkan ko ṣe ẹnu re nile iwosan itọju arun ọpọlọ to wa ni Aro, niluu Abeokuta l’Ọjọru, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu karun-un ọdun 2024 yii.
Awọn ti wọn ti n ni alaafia ninu awọn alaisan naa la gbọ pe wọn yari mọ awọn olutọju ati alaṣẹ ileewosan naa lọwọ.
Koda, wọn ni diẹ lo ku ki dokita kan ati awọn nọọsi mẹta padanu ẹmi wọn sọwọ awọn olufẹhonu han naa, bi ko ṣe ori to ko wọn yọ.
Pẹlu ẹ naa, dokita kan foriko iya lọwọ awọn alarun ọpọlọ ti alaafia ti n to naa.
A gbọ pe wọn ge e jẹ yanna-yanna ni.
Afigba ti awọn ọlọpaa teṣan Lafẹnwa waa yanju wahala naa ni alaafia too jọba
Kí ló ṣẹlẹ̀ táwọn tó ń gbàtọ́jú dojú ìjà kọ àwọn tó ń tọ́jú wọn?
Ohun ti a gbọ ni pe awọn to n gbatọju naa binu lori iwa tawọn alaṣẹ ati awọn dokita Aro n hu.
Wọn ni wọn ki i fun awọn lounjẹ to daa.
Bi ina ọba ba lọ, wọn ni okunkun birimu lawọn yoo wa, awọn alaṣẹ Aro ko ni i wa ọna lati tan ẹrọ amunawa, bẹẹ wọn n gbowo ribiribi lọwọ awọn eeyan awọn.
Lati ṣe igbọnṣe tabi tura ko tun dẹrun gẹgẹ bawọn eeyan naa ṣe wi.
Bi wọn ko ṣe le rin yan fanda ninu ọgba, to bẹẹ ti wọn ki i le ri awọn ẹbi wọn ti yoo mu wọn pada sile tun jẹ ẹsun kan ti wọn ka sawọn alaṣẹ Aro lẹsẹ.
Wọn ni o ti pẹ tawọn ti n koju awọn iṣoro yii, ko ṣẹṣẹ bẹrẹ.
Ẹnikan to jẹ ẹbi ọkan lara awọn eeyan naa ṣalaye, pe bo ṣe ri gẹlẹ ni awọn olugbatọju naa sọ yẹn.
O ni owo nla ni awọn alaṣẹ ileewosan aisan ọpọlọ yii n gba, eyi to kere ju ni Idaji miliọnu naira.
Obinrin naa sọ pe nigba mi-in, ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin (700,000) ni wọn yoo gba.
O ni bi ẹni ti wọn ba fẹẹ tọju ba ṣe pẹ si lọdọ wọn ni wọn ṣe n bu owo sisan.
Ṣugbọn pẹlu owo ti wọn n gba, o lo ṣeni laanu pe iya ni wọn fi n jẹ awọn akanda ẹda to nilo itọju.
Àwọn aláṣẹ iléèwòsàn Aro náà sọ̀rọ̀
Nigba to n sọrọ lorukọ ileewosan ọpọlọ Aro, Alukoro wọn, Ajibọla, sọ pe ọrọ abẹnu lasan ni.
Alukoro ileewosan ọpọlọ Aro sọ pe iṣẹlẹ ti ko kan ara ita lo ṣẹlẹ.
O ni isẹlẹ naa ko to ohun tawọn akọroyin n gbe jade rara, nitori ohun tawọn ti pana rẹ ninu ile ni.
Ṣaa, ọga ọlọpaa teṣan Lafẹnwa, l’Abẹoluta, DPO Enatufe Omoh, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Omoh ṣalaye pe dokita kan ṣoṣo ni awọn akanda ẹda naa ge jẹ, to si fara ṣeṣe.
O ni ko sẹni to ku ninu iṣẹlẹ naa, bawọn kan ṣe n gbe e kiri.














