Ẹ̀sùn owó orí ìyàwó sísan fa ikú èèyàn mẹ́ta, gbé èèyàn méje dọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Anshu àti Anshika ní ọjọ́ ìgbéyàwó wọn

Oríṣun àwòrán, Ankit Srinivas

Àjálù ńlá kan ti mú kí ẹbí méjì pàdánù ẹ̀mí èèyàn mẹ́ta, tí àwọn méje mìíràn sì wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá.

Ní alẹ́ ọjọ́ Kejìdínlógún oṣù Kẹta, ọdún 2024 ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà wáyé ní ẹkùn àríwá ìlú Prayagraj (tó ń jẹ́ Allahabad tẹ́lẹ̀), orílẹ̀ èdè India.

Ìkìlọ̀: ìròyìn yìí ní àwọn nǹkan tó lè banilọ́kànjẹ́

Shivani Kesarwani sọ fún BBC pé ní nǹkan bíi aago mọ́kànlá alẹ́ ọjọ́ náà ni àwọn àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́ta yawọ ilé àwọn, tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní lu àwọn ní ànàbolẹ̀.

Ó ní àwọn ènìyàn ìyàwó ẹ̀gbọ́n òun, Anshika, tí àwọn ṣàdédé bá òkú rẹ̀ nínú ilé ní nǹkan bíi aago mẹ́wàá alẹ́ lálẹ́ ọjọ́ kan náà, wà lára àwọn èèyàn ọ̀hún.

Shivani àtàwọn ọlọ́pàá ní Anshika ṣekúpa ara rẹ̀ àmọ́ àwọn ẹbí rẹ̀ ń fẹ̀sùn kàn pé wọ́n pa á ni nítorí ọ̀rọ̀ owó orí.

Láti ìgbà tí Anshika ti ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkọ rẹ̀, Anshu Kesarwani, ilé ẹbí wọn tó jẹ́ ilé alájà mẹ́ta ni wọ́n ń gbé. Orí àjà kẹta ni tọkọtaya náà ń gbé, àwọn òbí ọkọ ń gbé orí àjà kìíní, tí àbúrò Anshu, Shivani ń gbé orí àjà kejì.

Shivani ṣàlàyé pé aago mẹ́jọ ni Anshika máa ń sọ̀kalẹ̀ láti wá jẹ oúnjẹ alẹ́ ṣùgbọ́n kò sọ̀kalẹ̀ lọ́jọ́ náà, tí àwọn sì rò pé bóyá ó sùn lọ ni.

Ó ní nígbà tí ẹ̀gbọ́n òun dé ní aago mẹ́wàá alẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó lọ sókè láti lọ pe ìyàwó rẹ̀.

“Nígbà tí ẹ̀gbọ́n mi kan ilẹ̀kùn títí tí kò gbọ́ ìjẹ́ ìyàwó rẹ̀ ló fọ́ gíláàsì tó wà lókè ilẹ̀kùn láti rí ilẹ̀kùn náà ṣí láti inú, òkú ìyàwó rẹ̀ ló bá.

“Ó pariwo, gbogbo wa sáré lọ ba lókè.”

Shivani

Oríṣun àwòrán, Ankit Srinivas

'Wọ́n dáná sun ilé wa, wọ́n sun ìyá àti bàbá mi mọ́lé'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Anshu àti àbúrò bàbá rẹ̀ kan lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá tí kò ju kìlómítà kan sí ilé wọn láti lọ fi nǹkan tó ṣẹlẹ̀ náà tó wọn létí, tí wọ́n sì lọ sọ fún àwọn òbí Anshika nípa ikú rẹ̀.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní kò tó wákàtí kan tí àwọn ẹbí Anshika yabo ilé àwọn Anshu pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ẹbí mìíràn, tí ìjà ńlá sì bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ẹbí méjéèjì.

Shivani fi fídíò bí àwọn ọkùnrin ṣe ń jà, tí wọ́n ń la igi mọ́ ara wọn. Ọlọ́pàá kan wà láàárín wọn tó ń gbìyànjú láti la àwọn tó ń jà náà àmọ́ pàbó ni gbogbo ìgbìyànjú rẹ̀ já sí.

Àwọn ọlọ́pàá ní bí wọ́n ṣe gbé òkú Anshika kúrò nínú ilé àwọn Anshu ni àwọn ẹbí rẹ̀ dáná sí ilé náà.

Àwọn igi tí ẹbí Kesarwani ń tà tó wà ní abẹ́ ilé náà ni wọ́n fi dáná sí ilé náà lásìkò tí Shivani, àwọn òbí rẹ̀, àti àbúrò bàbá rẹ̀ wà nínú ilé.

Shivani ṣàlàyé pé òun àti àbúrò bàbá òun já fèrèsé àjà kejì láti sá kúrò nínú ilé lásìkò tó ń jó lọ́wọ́ náà lọ sí ilé àbúrò bàbá rẹ̀ kan tó wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn ṣùgbọ́n àwọn òbí rẹ̀ kò ríbi kúrò jáde nínú ilé náà.

Nígbà tí àwọn panápaná, tó lo kọjá wákàtí mẹ́ta láti fi paná ọ̀hún, òkú ìyá àti bàbá Anshu tí wọ́n ti jóná di eérú ni wọ́n gbé jáde níbẹ̀.

“Ní ẹnu ọ̀nà ni a ti rí òkú ìyá mi tó jókòó sí, ààpò ṣaka ni wọ́n fi gbé òkú rẹ̀ dé mọ́ṣúárì,” Shivani sọ pẹ̀lú omi ẹkún lójú.

Nínú ẹ̀sùn tí Shivani kọ fún àwọn ọlọ́pàá ló ti dárúkọ àwọn ẹbí Anshika méjìlá àtàwọn èèyàn ọgọ́ta tí kò mọ̀ tó lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ bí wọ́n ṣe dáná sun ilé wọn tó pàdánù àwọn òbí rẹ̀ sí.

Àwòrán bàbá àti ìyá Anshu tó jóná mọ́lé

Oríṣun àwòrán, Ankit Srinivas

Ọlọ́pàá kan sọ fún BBC pé èèyàn méje, tó fi mọ́ bàbá Anshika àtàwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin ló ti wà ní àhámọ́ àwọn.

Bákan náà ni wọ́n bàbá Anshika náà fi ẹjọ́ sùn àwọn ọlọ́pàá pé Anshu àtàwọn ẹbí rẹ̀ ló pa ọmọ òun àti pé wọ́n dúnkokò mọ lórí owọ orí nígbà tó wà láyé.

Shivani jiyàn àwọn ẹ̀sùn náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní lóòótọ́ ni àwọn gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ ẹbí àwọn Anshika tó fi mọ́ ọkọ̀ nígbà tí Anshika àti Anshu ṣe ìgbéyàwó.

Ó ní àwọn kò bèèrè ohunkóhun lọ́wọ́ wọn pé àwọn lọ wà láti fún ọmọ wọn ní gbogbo ẹbùn náà.

Ó ní Anshu kò ì tíì padà sílé láti alẹ́ ọjọ́ tí ìyàwó rẹ̀ ti jáde láye, pé ó lọ fara pamọ́ nítorí inú ìbẹ̀rù ló wà pé àwọn ẹbí Anshika máa ṣe òun ní ìjàmbá tí òun bá yọjú sóde.

Fífún àti gbígba owó orí ìyàwó ní India ti di ìwà tó lòdì sófin láti ọdún 1961 àmọ́ ìwádìí kan fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìdá àádọ́rùn-ún ìgbéyàwó tó ń wáyé ní India títí di àsìkò yìí ni wọ́n ṣì ti ń gba owó orí.

Láàárín ọdún 2017 sí 2022, ìwádìí fi hàn pé ìyàwó 35,493 ló pàdánù ẹ̀mí wọn fẹ́sùn wí pé wọn kò san owó orí tó péye fún àwọn ọkọ wọn lásìkò ìgbéyàwó.

Ṣùgbọ́n irú ẹ̀san tó lágbára bí èyí kò ì tíì sí ní àkọ́ọ́lẹ̀ rárá.

Shivani ní òun ń fẹ́ ìdájọ́ òdodo lórí ikú àwọn òbí òun àti ilé àwọn tí wọ́n dáná sun di eérú. Ó ní òun ń fẹ́ ìwádìí tó gbòòrò lórí ìṣẹ̀lẹ̀ kí àwọn tó bá jẹ̀bi fojú winá òfin.

“Kí ni ìdí tí wọ́n fi dáná sun ilé wa? Báwo ni a ṣe fẹ́ rí nǹkan tó máa jẹ́ ẹ̀rí lórí ikú Anshika múlẹ̀ báyìí?

Ile ẹbi awọn Anshu ti wọn dana sun

Oríṣun àwòrán, Ankit Srinivas

Lórí ẹ̀sùn tó fi kan àwọn ọlọ́pàá pé wọn kò ṣe ohunkọhun nígbà tí àwọn ènìyàn náà dáná sun ilé àwọn, ọlọ́pàá kan ní ohun tí àwọn fi ọkàn si ní láti gbé òkú Anshika lọ sí ilé ìwòsàn fún àyẹ̀wò, pé àwọn kò mọ̀ pé wọ́n máa sáná sun ilé náà.

Ó ní ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn pé àwọn panápaná àti pé àwọn ran òṣìṣẹ́ panápaná láti dóòlà èèyàn márùn-ún nínú ilé náà.

Nígbà tí BBC kàn sí ilé àwọn Anshika láti gbọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ láti ọ̀dọ́ wọn náà, bàbabàbá Anshika ní kí ni òun fẹ́ sọ nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ òun àti ọmọọmọ wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá.

Ó fẹ̀sùn kan àwọn ẹbí Anshu pé àwọn ló pa Anshika, tí wọ́n wá fi òkú rẹ̀ kọ́ láti jẹ́ kó dàbí pé ó pa ara rẹ̀ ni.

Bàbabàbá Anshika ní ọ̀pọ̀ owó ní àwọn ná sí ìgbéyàwó òun àti ọkọ rẹ̀. Mílíọ̀nù mátùn-ún rupees ($60,000) ni a ná. Gbogbo nǹkan tó nílò ní ilé ọkọ rẹ̀ ni a fun àti ọkọ̀ tí iye rẹ̀ tó 1.6m rupees.

Ó fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé nígbà tí Anshika yọjú sí àwọn gbẹ̀yìn nínú oṣù Kejì, “ó sọ fún wa pé wọ́n ń dúnkokò mọ́ òun nínú àmọ́ a ba sọ̀rọ̀ pé kó ní sùúrù, pé gbogbo nǹkan máa da láìpẹ́.”

Àwọn ẹbí Anshika gbajúmọ̀ ní agbègbè wọn, tí ọ̀pọ̀ sì júwe wọn bíi onírẹ̀lẹ̀ tí kìí fa wàhálà kankan, wọ́n ní ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn pé wọ́n lè dáná sun ilé àwọn àna wọn.

Ọkùnrin kan tó ń gbé agbègbè náà ní àwọn kò mọ ẹni tó dáná sun ilé àmọ́ tó ní kò sí ẹni tí k]olè ṣi ìwà wù nígbà tí wọ́n bá rí òkú ọmọ wọn.

Bákan náà ni obìnrin míì ní ọmọ dáadáa ni Anshika nígbà tó wà láyé tí kò ní ẹ̀mí àti pa ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń sọ.

Ó ní nǹkan burukú ni pé àwọn òbí ọkọ Anshika jóná mọ́ ilé ṣùgbọ́n ó ní ohun tó ń ba òun nínú jẹ́ ni pé k]o sí ẹni tó ń sọ̀rọ̀ lórí ikú Anshika mọ́, pé báwo gan-an ní ó ṣe kú àti pé kí ló fa ikú rẹ̀?