Mọ̀ nípa afurasí tọkọ-taya tí àjọ NDLEA ń wá lórí ẹ̀sùn gbígbé egbòogi olóró

Oríṣun àwòrán, NDLEA Nigeria/X
Ajọ to n gbogun ti lilo egboogi oloro lorileede Naijiria, NDLEA ti kede tọkọ-taya kan, Ọgbẹni Kazeem Ọmọgoriọla Owoalade ati aya rẹ, Rashidat Ayinkẹ Owoalade gẹgẹ bi ẹni ti wọn n wa.
Ninu atẹjade ajọ naa gbe jade soju opo X wọn lọjọ Aiku to kọja, wọn ni tọkọ-taya naa ko niṣẹ meji ju gbigbe egboogi oloro lọ, ati pe ogbontarigi ni wọn jẹ.
Atẹjade ọhun ti agbẹnusọ NDLEA, Fẹmi Babafẹmi buwọ lu jẹ ko di mimọ pe orileede India ni Kazeem Ọmọgoriọla Owoalade ti awọn eyan mọ si Abdul Qassim Adisa Balogun ati aya rẹ Rashidat Ayinkẹ Owoalade ti awọn eeyan mọ si Bọlarinwa Rashidat Ayinkẹ ti n ṣiṣẹ wọn.
NDLEA sọ pe ọwọ awọn ti tẹ mẹrin ninu ikọ to n ba tọkọ-taya naa ṣiṣẹ papọ niluu Eko.
Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe awọn ti gba ọkọ ayọkẹlẹ kan ati ile meji ọtọọtọ ti wọn fi owo egboogi oloro ọhun ra lọwọ wọn, ati pe ijọba apapọ ti gbẹsẹ le wọn.
Bí ọwọ́ ṣe tẹ àwọn méjì ọ̀hún
“Meji ninu ikọ yii, Imran Taofeek Ọlalekan ati Ishola Isiaka Ọlalekan ni ọwọ tẹ lọjọ kẹta, oṣu kẹrin, ọdun 2024 lasiko ti wọn n gbiyanju lati gbe egboogi to jẹ kilogiraamu mẹta le diẹ (3.40kg) lọ sorileede Oman.
“Papakọ ofurufu Murtala Muhammed to wa ni Ikẹja, ipinlẹ Eko lọwọ ti tẹ wọn ninu ọkọ ofurufu ti Qatar, eyi to n lọ si orileede Oman.
“Nigba ti Imran jẹ ẹni to n gbe awọn egboogi oloro naa lọ si Oman, Ishola jẹ gẹgẹ bi ẹni to gba a si iṣẹ gẹgẹ bi olori akẹru, eyi ti iwadii ti wa fidi rẹ mulẹ pe Alaaji Kazeem Ọmọgoriọla Owoalade to n gbe lorileede India, ṣugbọn ti orukọ rẹ ninu iwe igbelu jẹ Abdul Qassim Adisa Balogun based in India lo ran wọn niṣẹ.
“Igbiyanju lati ba itakun to fi n ṣiṣẹ rẹ jẹ lorileede Naijiria lo pada ja si ayọ lẹyin ọsẹ marun-un ti wọn ti n fimu finlẹ, nigba ti ọwọ tun tẹ ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ naa, Hamed Abimbọla Saheed, ẹni ti wọn lo n ṣiṣẹ pẹlu awọn ogbologbo yii.
“Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinla, oṣu karun, ọdun 2024 lọwọ tẹ Hamed lagbegbe Abule Ẹgba nipinlẹ Eko.”
NDLEA fi ye wa ninu atẹjade ọhun pe Saheed lo gba Imran si otẹẹli kan nigba to ku ọjọ kan ko gbera lọ si Oman, to si tun lọ ja oun ati Ishola si papakọ ofurufu l’Eko lọjọ ti ọwọ tẹ wọn.
Siwaju sii ni wọn sọ pe nigba ti wọn lọ yẹ ile Hamed wo, oriṣiriṣi egboogi bii phenacetine, eyi ti wọn ge lara kokeeni ti iwọn rẹ jẹ 900grams ni wọn ba nibẹ.
Nibẹ ni wọn sọ pe Hamed ti jẹwọ pe lara awọn ọja ti Imran n gbe lọ si Oman ni, eyi toun yọ ninu silẹ sile.
Hamed lo tun ṣatọna bi wọn ṣe lọ sile tọkọ-taya naa to wa ni ojule ogun, adugbo Eyiaro, Ogudu Orioke nipilẹ Eko, nibi ti ọwọ ttun ti tẹ afurasi kan ati mọto Toyota RAV4 SUV tuntun ti nọmba rẹ jẹ FKJ-773 JJ.
Mọto ọhun ni wọn lo jẹ ti Rashidat, ti wọn si tun ba egboogi oloro ti iwọn rẹ jẹ irinwo giraamu (400grams) nibẹ pẹlu baagi ti wọn fẹẹ fi gbe e.
Àwọn mẹ́rin mìíràn tún há
Bakan naa, ninu iroyin miran ni ọwọ tun ti tẹ afurasi mẹrin pẹlu awọn ẹrun ofin ti wọn pe ni Improvised Explosive Devices (IED) to le diẹ ni ẹgbẹrun meji (2,025), eyi ti wọn ba ninu ọkọ Toyota Hummer Bus ti nọmba rẹ jẹ AGL 905 XX.
Opopona Agaie-Lapai nipinlẹ Niger lọwọ ti tẹ wọn.
Abdulrauf Shitu Adeyemi, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta ati Asmiyu Rahim, ẹni ọdun marundinlaadọta lọwọ tẹ loju ẹsẹ pẹlu ẹru IED ọhun.
Bi ọwọ ṣe tẹ wọn lo mu ki aṣiri awọn meji miran, Husaini Abdullahi, ẹni ọdun marundinlọgbọn ti ọwọ tẹ ninu ọja Sokoto ati Nazifi Abdullahi, ẹni ọdun mẹtadinlogoji ti ọwọ tẹ ni garaaji Naibawa to wa ni Kano lọjọ Ẹti to kọja.
Alaga ati alakoso ajọ NDLEA lorileede Naijiria, Ajagunfẹyinti Mohamed Buba Marwa ti wa paṣẹ pe ki wọn tare awọn afurasi mẹrẹẹrin lọ si ọdọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo to yẹ fun iwadii siwaju sii.















