Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ òkèrè kọlu DR Congo láti gbàjọba mọ́ Ààrẹ lọ́wọ́, ìró ìbọn ń dún lákọlákọ

DR Congo

Oríṣun àwòrán, getty images

Ileeṣẹ ọmọ ogun Democratic Republic of Congo ti kede pe oun ti bẹgi dina iditẹgbajọba kan to yẹ ko waye lorilẹede naa lẹyin to kọju ija sawọn ọmọ ogun ilẹ okere to fẹ gbajọba lọwọ Aarẹ Felix Felix Tshikedi.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọmọ ogun naa, Sylavin Ekenge kede lori ẹrọ amohunmaworan RTNC TV pe ọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi kan, wọn si ti wa ni ahamọ.

Ọrọ yii lo n jade lẹyin wakati diẹ ti awọn eeyan kan ti wọn di ihamọra ogun kọlu ile Vital Kamerhe, to jẹ olori oṣiṣẹ Aarẹ Tshisekedi ni afẹmọju ọjọ Aiku.

Awọn oṣojumikoro sọ pe awọn adihamọra ogun ti iye wọn to ogun, ti wọn si wọ aṣọ ologun ni wọn kọlu ile Kamerhe, ti iro ibọn si dun lakọlakọ.

Ẹṣọ meji ati ẹnikan lara awọn egbebọn naa lo ba ikọlu ọhun lọ gẹgẹ bi ọrọ ti alukoro Kamerhe ati aṣoju ijọba Japan silẹ naa sọ loju opo X.

A gbọ pe awọn adihamọra ogun ọhun ya bo ọọfisi Aarẹ ti wọn n pe ni ‘Palais de la Nation’ to wa laarin ilu.

Ṣaaju ni aṣoju ijọba Japan ni olu ilu ilẹ naa ti kọkọ kilọ pe ki ẹnikẹni maṣe jade sita.

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, Aarẹ Tshisekedi ko tii sọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa.

Ẹwẹ, awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan ti jabọ pe ọmọ ẹgbẹ New Zaire Movement lawọn agbebọn naa, ti wọn ni ajọṣepọ pẹlu Christian Malanga, to jẹ oloṣelu ti wọn ti le kuro niluu.

Ọdun to kọja ni wọn dibo yan Aarẹ Tshisekedi fun saa keji.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ araalu ni ko faramọ esi idanwo naa, ida 78% lo ni ninu esi ibo ọhun.

Nnkan bi ogun eeyan ni wọn ṣekupa ṣaaju ati lasiko idibo naa.