Ata àkàrà tí kò ran ikọ́ ni ìpàdé Atiku àti Obi lórí ìbò ààrẹ ọdún 2027 - iléeṣẹ́ ààrẹ fèsì

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/X
Laipẹ yii ni awọn ondije meji fun ipo aarẹ orilẹ-ede yii ni 2023, Atiku Abubakar ati Peter Obi, ṣepade pọ l’Abuja.
Lẹyin ipade naa ni Alaaji Atiku sọ pe o ṣee ṣe ki ẹgbẹ PDP ati Labour Party di ọkan ṣoṣo fun idibo ọdun 2027.
Atiku ṣalaye pe ko sohun to buru ninu ki ẹgbẹ mejeeji di ọkan ṣoṣo ki wọn le bori ni 2027.
O ni bi wọn ba pin ipo aarẹ si Guusu-Ila-Oorun Naijiria ni 2027, oun ṣetan lati ti ẹgbẹ Labour lẹyin pẹlu ondije wọn.
Igbakeji aarẹ tẹlẹ naa tẹsiwaju pe iya n jẹ awọn araalu, oun ko si le laju silẹ ko maa lọ bẹẹ.
O ni atunṣe gbọdọ wa lo jẹ koun ati Obi ṣepade gẹgẹ bii ẹni ti ọrọ Naijiria jẹ logun.
Bi ọrọ naa ṣe jade lawọn eeyan ti n beere pe njẹ ohun ti yoo fidi ijọba Aarẹ Bọla Tinubu janlẹ ni 2027 kọ niyi bi?
B’awọn kan ṣe n sọ pe ajọṣepọ PDP ati LP le koba itẹsiwaju Tinubu, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe ileri alangba lasan ni ajọsẹpọ Atiku ati Obi, wọn ni ko ju idọbalẹ lọ.
Èsì iléeṣẹ́ Àárẹ

Oríṣun àwòrán, @ The Nigerian Presidency
Minista fun eto iroyin lorilẹ-ede yii, Mohammed Idris, nigba to n fesi si ipade Atiku ati Obi, sọ pe,
‘’ Rikiṣi to da Atiku Abubakar ati Peter Obi pọ ti wọn fi jọ n ṣepade ko dẹru ba Aarẹ Bọla Tinubu rara.
‘’Ẹnikẹni le ronu lati darapọ mọ ẹlomi-in ki wọn jọ maa ṣe, ṣugbọn ki lo n gbẹyin ipade ati ajọsọ iru ẹ lọpọ igba?
‘’Iṣẹ ti Aarẹ Bọla Tinubu n ṣe ni yoo jẹ kawọn eeyan mọ ohun ti wọn ro nipa rẹ ni 2027.
Ipade awọn Atiku ati Obi yii ko daamu iṣejọba Aarẹ Tinubu rara o.
‘’Awa o tiẹ ri tiwọn ro, bi a ṣe maa mu ileri ta a ṣe fawọn eeyan ṣe la dojukọ.’’
‘Atiku àti Obi ti lulẹ̀’
Bakan naa, amugbalẹgbẹ agba fun Aarẹ Bọla Tinubu, Bayo Onanuga, sọ pe Atiku ati Obi ti lulẹ lori ipinnu wọn.
Ọnanuga sọ lọjọ Satide, ọjọ kejidinlogun oṣu karun-un ọdun 2024, pe ajọsẹpọ Obi ati Atiku ko jọ ijọba Tinubu loju.
‘’ Ohun to ya wa lẹnu ni pe lẹyin ọdun kan pere ti awọn mejeeji padanu ipo aarẹ ti wọn dije fun ni wọn tun bẹrẹ si i pete abosi.
‘’Wọn n ṣe bii aladaanu ti wọn jẹ́. Ko sohun to kan Aarẹ Tinubu pẹlu wọn.
‘’Awọn ọna ti Naijiria yoo fi gunke agba, to yẹ kijọba iṣaaju ti wa tipẹ ti wọn o ṣe ni Tinubu n tọ bayii.
Eyi to kan an niyẹn, ki i ṣe tawọn to ti lulẹ to n ṣepade àdánù kiri’’
Ṣé ó ṣeé ṣe kí Atiku/Obi rọ́wọ́ mú bí wọ́n bá di ẹgbẹ́ kan ṣoṣo ní 2027? Àwọn onímọ̀ òṣèlú sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, The Punch Newspaper
Aarẹ ẹgbẹ awọn onimọ nipa oṣelu (National Political Scientists Association), Ọjọgbọn Hassan Salisu, sọ pe ajọsẹpọ PDP ati LP kọ ni koko, bi ko ṣe pe wahala to wa ninu ẹgbẹ mejeeji le ṣakoba fun wọn ni 2027.
Ọjọgbọn Salisu lati Yunifasiti Ilọrin , ṣalaye pe,
“ PDP lasiko yii ti pin si ẹka ọtọọtọ, ẹnu wọn le ma tete ko.
‘’Obi to si wa lati inu ẹgbé mi-in, ki lo fi da wa loju pe ipilẹ PDP yoo faye gba a lati dije lorukọ ẹgbẹ wọn?
“ Ṣe awọn olutẹle Atiku yoo ṣetan lati tẹle Peter Obi? Njẹ awọn Obidiẹnti (Obidients) yoo faramọ ki Obi tun pada si PDP?
‘’Awọn igun ti Wike nkọ? Awọn ọmọ Arewa ti wọn wa ninu PDP nkọ?’’
Ọjọgbọn Salisu sọ pe awọn nnkan to le dena aṣeyọri PDP ati LP pọ bi wọn ba di ẹyọkan ṣoṣo.
O ni bi wọn ko ba ri awọn nnkan wọnyi yanju, yoo ṣoro ki wọn too yege.
Ni ti Ọjọgbọn Yahaya Baba, lati Yunifasiti Usman Dan Fodiyo nipinlẹ Sokoto, o ni oloṣelu nla ni Atiku ati Obi, bi wọn ba sowọpọ, iyatọ ọtun le waye ninu itan oṣelu ilẹ Naijiria.
Yahaya ni kawọn eeyan ma gbagbe, pe PDP ni Peter Obi wa tẹlẹ, ija lo de to fi gba Labour lọ.
O ni bi wọn ba fi le di ọkan ṣoṣo bayii, o ṣee ṣe ki ajọṣepọ to nipọn waye, ki ohun to ṣẹlẹ si ẹgbẹ APC ni 2014 si tun ṣẹlẹ lẹẹkan si i.
Jackson Omenazu, onimọ nipa oṣelu mi-in naa sọ pe ewu n bẹ loko Longẹ fun Aarẹ Tinubu bi Atiku ati Obi ba di ọkan ṣoṣo.
‘’Ẹ maa reti awọn ajọṣepọ bayii ni 2027. Ko si bi ẹ ṣe le pin ipo aarẹ lorilẹ-ede yii, awọn ẹya Igbo naa lẹtọ si i, o yẹ ko kan wọn.
‘’Bi PDP ati LP ba fi le parapọ ni 2027, ko sohun to dara to o fun demokresi wa’’ Bẹẹ ni Omenazu wi.
Ṣugbọn ileeṣẹ Aarẹ Bọla Tinubu ti ni ẹru o bodo, wọn lẹni ti yoo wọ odo lominu n kọ.














