Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara sàlàyé ìdí tó fi ń wó ṣọ́ọ̀bù ìtajà ní Ilorin, àwọ́n òntàjà pariwo

Aworan awọn ṣọọbu tijọba Kwara wó

Lẹyin ariwo awọn ontaja ti ijọba ipinlẹ Kwara wo ṣọọbu wọn lagbegbe Ahmadu Bello titi de Tankẹ, niluu Ilọrin, ijọba ipinlẹ naa ti ṣalaye idi ti wọn fi gbe igbesẹ yii.

Lakọọkọ, ijọba Kwara sọ pe awọn ti ọrọ naa kan ti mọ idi pataki ti wiwo awọn ṣọọbu yii fi gbọdọ waye.

Wọn ni awọn to kọ ṣọọbu wọnyi mọ tẹlẹ pe ilana ti wọn fi kọ wọn ko ba ofin mu. Ibi ti wọn kọ wọn si ko si tọ̀nà.

Yatọ si eyi, wọn ni ikilọ ti lọ sọdọ awọn to kọ ṣọọbu naa lọpọ igba, pe ki wọn tete kuro kijọba too de.

Ijọba Kwara sọ pe aitẹle ikilọ lo jẹ ko ba wọn lojiji.

Bakan naa, ijọba Kwara loun fẹẹ sọ Ilọrin di ilu alaranbara, ilu igbalode ti a mọ si ‘Smart City’.

Ko si bi eyi yoo ṣe wa si imuṣẹ nigba ti awọn ṣọọbu oju ọna yii ba ṣi wa nibẹ ni ijọba Kwara ṣalaye.

Eyi lo jẹ ki wọn bẹrẹ si i wo awọn ṣọọbu naa, ki atunṣe oju ọna Ahmadu Bello si le bẹrẹ lọwọ kan.

Ara ajé ta àwọn oníṣọ́ọ̀bù, wọ́n fi ariwo bọnu fún ìjọba

Aworan awọn ṣọọbu tijọba Kwara wó
Aworan awọn ṣọọbu tijọba Kwara wó
Aworan awọn ṣọọbu tijọba Kwara wó
Àkọlé àwòrán, Aworan awọn ṣọọbu tijọba Kwara wó

Nigba ti BBC Yoruba de awọn agbegbe ti wọn ti n wo ṣọọbu naa lọjọ Satide, ọjọ kejidinlogun oṣu karun-un ọdun 2024 yii, niṣe lawọn ontaja ti wọn wo ṣọọbu wọn figbe ajé bọnu.

Ọkunrin kan to pe orukọ ara ẹ ni Taye, ṣalaye pe oun ṣẹṣẹ sanwo ṣọọbu naa fun lanlọọdu ni.

O ni baba onile ko ni i da owo oun pada bayii, ijọba si ti wo ṣọọbu toun ti n ta ohun mimu ẹlẹrindodo.

Taye sọ pe ọna toun ti n rowo jẹun lo wo loju oun yii, afi ki ijọba ipinlẹ Kwara ṣaanu oun.

Bakan naa ni obinrin kan, Jumoke Bankole toun naa ni ṣọọbu lagbegbe Tanke, ṣalaye pe ojiji ni wiwo ṣọọbu yii ba oun.

O parọwa sijọba Kwara lati dide iranlọwọ, nitori ko si ọna atije mi-in mọ fawọn pẹlu bijọba ṣe wo ile itaja awọn gbogbo.