Wo ọ̀nà tí o lè fi bá ẹni tó ti kú sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀

Oríṣun àwòrán, DEEPBRAIN AI
Aye n lọ, a n tọ ọ, awọn onimọ ijinlẹ ti ṣe iwadii lori ọna ti eeyan fi le ba ẹni to ti ku sọrọ.
Lọdun 2016 ni James Vlahos gba iroyin ibanujẹ kan pe baba rẹ ti ni aarun jẹjẹrẹ eyi to ti wọ ọ lara gan an.
James to n gbe ni Oakland ni California l'Amẹrika pinnu lati jẹ ki baba rẹ lo igba toku fun un daadaa ki o to ku.
Asiko yii naa ni James n n gbiyanju lati kọ nipa imọ ijinlẹ ati lilo ọgbọn ori.
"Bayii ni mo ṣe ro pe o yẹ ki n fi asiko naa ṣe nnkan gidi pẹlu akoko ti mo ni," James lo sọ bẹẹ.
Baba James ku lọdun 2017, ọdun yii kan naa ni James ṣe aapu kan to n dahun ibeere nipa baba rẹ to ti ku.
Awọn onimọ sayẹnsi ti n gbiyanju tipẹ lati maa lo nnkan awọn eeyan to ti ku, amọ, idagbasoke imọ ijinlẹ ti jẹ ki erongba wọn wa si imusẹ bayii.
Ni ọdun 2019, James pe orukọ aapu to ṣe ni "HereafterAI" eyi to n fawọn eeyan to ba fẹ lanfaani lati ka ati lo ohun awọn eeyan wọn to ti ku silẹ lẹyin ti wọn ti ku tan.
James ni aapu yii le ma mu aniyan ọkan lori iku baba rẹ kuro, amọ, yoo foun ni nǹkan ti oun ko le lanfani si lai lo aapu naa.
Aapu yii maa n fun awọn eeyan lanfaani lati lo fọto eeyan wọn to ti ku lori foonu ati ẹrọ kọmputa, amọ, ọgbọn atinuda ti wọn n pe ni AI tun ti jẹ ko rọrun si.

Oríṣun àwòrán, JAMES VLAHOS
Ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ l'ọna igbalode kan ni South Korea ti wọn n pe orukọ rẹ ni DeepBrain AI ṣe ẹda eeyan sori kọmputa lẹyin ti wọn ti ka ohun ati fidio eeyan naa silẹ fun ọpọ wakati.
Ẹda eeyan ọhun ka bi ẹni naa ṣe n rin, oju rẹ ati ohun ẹni naa silẹ.
"A n ṣe ẹda eeyan ti yoo dabi ẹni naa gan-an gan-an"
Ọgagba ileeṣẹ DeepBrain AI, Michael Jung ni ileeṣẹ awọn n ṣe ẹda eeyan ti yoo jọ onitọun gan.
A ṣe e debi wi pe awọn eeyan ẹni to ti ku yii ko ni mọ pe ki i ṣe eeyan wọn to ku ni wọn n ba sọrọ.
Bi wọn n ṣe e ni pe wọn ti maa ka ohun ati fidio ẹni to ba ti fẹ ku silẹ ki asiko to to.
Eyi ni wọn maa ṣiṣẹ le lori to si maa dabi ẹni naa lẹyin ti onitọun ba ti ku tan.
Amọ, owo gọbọi ni aapu yii da le lori.
Ẹbi kan san $50,000 fun ileeṣẹ yii lati ṣe ẹda awọn eeyan wọn nipa kika ohun ati fidio wọn silẹ ki wọn to jade laye.
Bo tilẹ jẹ pe owo aapu naa wọn, ileeṣẹ yii ni ireti wa pe awọn eeyan ṣi maa tẹwọ gba a.
Koda, ileeṣẹ DeepBrain gan an ti ri owo to to miliọnu mẹrinlelogoji dọla ko jọ fun eto yii.
Ẹwẹ, onimọ nipa ihuwasi ẹda kan, Laverne Antrobus ti kìlọ pe k'awọn eeyan ṣe pẹlẹ lori lilo aapu ọhun papaa jùlọ tawọn eeyan ba n ṣe Ibalopọ lọwọ.
O ni ki eeyan maa gbọ ohun ẹni to ti ku le jẹ ki ọkan eeyan daru.
Antrobus ni ọkan eeyan gbọdọ le daadaa ki eeyan to le maa gbọ ohun ẹni to ti ku.
Awọn ileeṣẹ to n sewadii imọ ijinlẹ to niṣe pẹlu awọn iya to ti ku ni iroyin kan fidi rẹ múlẹ pe wọn ti fi bi £100bn dokowo bayii.
Iroyin naa sọ pe ajakalẹ arun covid-19 ṣe iranwọ nipa lilo imọ ijinlẹ lati wa ọna tawọn obinrin yoo fi maa kẹdun eeyan wọn to ku.
Amọ, Antrobus ko ṣai fidi rẹ múlẹ pe ko si ohun to le kẹdun ẹni to ti ku bi eeyan ẹlẹmii.















