Wo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí kò ní láńfàní sí ètò ẹ̀yáwó akẹ́kọ̀ọ́ ìjọba àpapọ̀

Aworan Aare Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/X

Latigba ti ijọba apapọ ti buwọ lu eto ẹyawo fun awọn akẹkọọ lorileede Naijiria ni awọn araalu, paapaa awọn akẹkọọ to jẹ pe funra wọn ni wọn n ran ara wọn lọ sile-ẹkọ ti n foju sọna.

Ijọba apapọ Naijiria jẹ ko di mimọ nigba naa pe awọn akẹkọọ ti wọn wa lawọn ile-ẹkọ ijọba ni yoo ni anfaani si eto ẹyawo naa, ati pe wọn yoo bẹrẹ sii san owo ọhun pada lẹyin ti wọn ba ti ri iṣẹ.

Ṣugbọn ni bayii, niṣe lo dabi ẹni pe ohun ti ọpọ akẹkọọ n reti tipẹ yoo tun bu omi tutu si wọn lọkan, pẹlu bi ijọba apapọ Naijiria tun ṣe kede sita wi pe gbogbo akẹkọọ ti wọn wa nile-ẹkọ ijọba apapọ nikan ni yoo ni anfaani si eto ẹyawo ọhun.

Ẹ fi ọkan balẹ

Alakoso agba fun ileeṣẹ to n ṣagbatẹru eto ẹyawo akẹkọọ ọhun, iyẹn, Nigerian Education Loan Fund (NELFUND), Ọgbẹni Akintunde Sawyerr, lo fi ọrọ ọhun lede laipẹ yii.

Sawyerr sọ pe o pọ ju, akẹkọọ miliọnu kan le ni igba (1.2m), ti wọn wa lawọn ile-ẹkọ ijọba apapọ kaakiri Naijiria ni yoo ni anfaani si ipele akọkọ eto ẹyawo naa.

Alakoso agba naa lo jẹ ki ọrọ yii di mimọ lọjọ Ẹti to kọja, nigba ti wọn n ṣiṣọ loju opo ayelujara ti awọn akẹkọọ yoo ti maa lọ fi orukọ silẹ.

O ni awọn ti ile-ẹkọ wọn ti pari fifi orukọ ati idanimọ wọn soju opo naa yanju, ni yoo jẹ anfaani yii.

Sawyerr ni lẹyin eyi, to ba di ọjọ kẹrinlelogun, oṣu karun-un, ọdun 2024 ti a wa yii, awọn akẹkọọ ti wọn ba ti peregede yoo bẹrẹ iforukọsilẹ wọn lẹkunrẹrẹ lati ya owo.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣugbọn ṣa, nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Aje, ana, Sawyerr sọ pe gbogbo akẹkọọ to wa lawọn ile-ẹkọ ijọba patapata ni yoo jẹ anfaani ẹyawo yii, ati pe awọn to wa nile-ẹkọ ijọba apapọ ni yoo kọkọ jẹ anfaani naa.

O ni lẹyin ti awọn akẹkọọ nile-ẹkọ ijọba apapọ ba ti jẹ anfaani naa ninu ipele akọkọ, ni yoo to ṣẹṣẹ kan awọn akẹkọọ to wa lawọn ile-ẹkọ ijọba ipinlẹ kaakiri Naijiria.

Sawyerr ni eto yii wa lara awọn ileri ati erongba ijọba Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, lati ṣe iranwọ owo fun awọn akẹkọọ to ku diẹ kaato fun.

O ni eyi yoo jẹ ọna ti wọn yoo fi jẹ anfaani ijọba nipa eto ẹkọ, ti yoo si mu ẹru wiwo ori wọn kuro nipa owo sisan.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe ẹyawo yii ko nii ni ele kankan ninu, ati pe wọn yoo bẹrẹ sii da owo naa pada lẹyin ọdun meji ti wọn ba pari eto agunbanirọ wọn.

Siwaju sii lo ni owo yii yoo san gbogbo ida ọgọrun owo ile-ẹkọ sinu apo aṣuwọn ile-ẹkọ wọn, ati pe awọn akẹkọọ naa yoo tun maa gba owo diẹ loṣooṣu fun asiko ti wọn yoo lo nile-ẹkọ.

O tun ṣalaye pe lara awọn amuyẹ ẹyawo yii ni ki ileeṣẹ NELFUND foju kan akẹkọọ to ba fẹẹ ya owo, ati awọn ilana to ja geere fun akẹkọọ lati fi orukọ silẹ loju opo wọn.

Bẹẹ lo kadi ọrọ rẹ nilẹ pe awọn ti n ṣiṣẹ papọ pẹlu oriṣiriṣi ileeṣẹ ti yoo ṣe iranwọ nigba ti nnkan ko ba lọ deedee nipa eto ẹyawo naa, ati pe awọn tun n ṣiṣẹ pẹlu awọn ileeṣẹ eleto aabo meloo kan lati gbogun ti iwa jibiti.