Ìdí rèé tí òkú Pa Akinkunmi tó ya àsìá Nàìjíríà ṣí fi wà ní mọ́ṣúárì láti ọdún 2023 di àkókò yìí

Àkọlé fídíò, ''A ti fẹ́ sin òkú Pa Akinkunmi tó ya àsìá Nàìjíríà tipẹ́, ìjọba ló ń dáwa lọ́wọ́ kọ́''
Ìdí rèé tí òkú Pa Akinkunmi tó ya àsìá Nàìjíríà ṣí fi wà ní mọ́ṣúárì láti ọdún 2023 di àkókò yìí

Awuyewuye to n lọ lori eto isinku Pa Taiwo Akinkunmi to ya asia orilẹede Naijiria ko tii tan pẹlu bi ẹbi baba naa ṣe ke gbajare pe ijọba ko tii fesi lori ọjọ ti awọn mu fun eto isinku naa.

Ni ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹjọ ọdun 2023 ni Pa Akinkunmi jade laye.

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ, Ọgbẹni Akinkunmi Akinwunmi to jẹ agbẹnusọ fun ẹbi oloogbe sọ pe ti ẹbi ba ti duro diẹ si ti ijọba ko ba sọ nkan kan, awọn maa tẹsiwaju lati sin oku baba awọn.

Ọgbẹni Akinwunmi sọ pe ‘’awa ẹbi ti fẹ sin oku baba lati ọdun 2023 ki ijọba ipinlẹ Oyo ati ijọba apapọ to dawa lọwọ kọ wi pe oku baba ki i ṣe oku ti a kan le sin bẹyẹn tori eeyan pataki ni baba wa.

A ti kọ ọpọ lẹta si ijọba ipínlẹ̀ Oyo ati ti apapọ lori ọrọ naa, amọ, a ko ti i ri esi kankan gba titi di akoko yii.

Ṣugbọn a ko mọ bo ya ijọba n ṣiṣẹ lori ọrọ naa ti ko han si wa.

Ohun ti ijọba sọ fun wa ni pe awọn ni lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun baba ki wọn to wọ kaa ilẹ sun.

Awa ni a n sanwo inu yinyin ti baba wa lati ọjọ yii wa, kii ṣe ijọba tabi ẹnikan nibi kan.

Amọ, ilana to wa nilẹ ni a n tẹle tori ko si ẹni to le jare ijọba.

A kan si ijọba ipinlẹ Oyo ati ijọba apapọ lori ọrọ naa, amọ, wọn ko tii fun wa lesi di akoko ti a kọ iroyin yii.