Olubi ọmọ dàwátí nílé ìwòsàn ‘Cottage Hospital’ ní Kwara, ilé ìwòsàn ní ajá ló gbé e
Arabinrin kan, William Oluwabukola ti ke gbajare lẹyin ti olubi ọmọ rẹ di awati nile iwosan to bimọ si niluu Iloffa nipinlẹ Kwara.
Arabinrin Oluwabukola ni ile iwosan naa sọ foun pe o ṣeeṣe ko jẹ pe aja lo gbe olubi ọmọ naa.
Arabinrin Olubukọla ‘’ni ọjọ kejila oṣu Karun un ọdun 2024 yii ni mo lọ si ile iwosan Cottage Hospital niluu Odo Owa ni Iloffa lati lọ bimọ nibẹ.
Nigba ti ago meje ku iṣẹju diẹ ni mo bi ọmọ naa, lẹyin naa ni olubi ọmọ jade.
O to bi nọọsi mẹrin atawọn oṣiṣẹ ile iwosan naa ti wọn wa nibi ti mo ti bimọ.
Nọọsi to gbẹbi fun mi, Peace Alabi ju olubi ọmọ mi sinu ọra kan lẹyin ti mo bimọ tan.
O si ju ọra naa sinu paali lẹgbẹ ibi ti mo ti bimọ.
Bayii ni wọn gbe mi lọ si wọọdu tawọn to ba ṣẹṣẹ bimọ maa n wa nibi ti ẹni to maa n tun wọọdu ṣe ti ba mi gbe ẹru mi wa.
Ni aarọ ọjọ keji ni mo ṣakiyesi pe ko si olubi ọmọ ninu ẹru mi ti wọn gbe wa.’’
Bayii ni iya ọmọ ikoko yii bẹrẹ si ni beere olubi ọmọ rẹ lọwọ awọn nọọsi atawọn to n tun wọọdu ṣe.
Arabinrin Oluwabukola sọ pe wọn ko ri ojutuu si ọrọ naa.
Oluwabukola ni ‘’nigba ti ẹni to da ilẹ nu ni wọọdu ti bimọ de laarọ ọjọ keji, o sọ pe oun ko gbogbo idọti to wa ninu ile ibimọ danu.
O ni oun ro wi pe bo ya aja le gbe olubi ọmọ naa.
Nigba ti a fa ọrọ naa lọ fa a bọ ni a gbe e de agọ ọlọpaa ni Iloffa.
Lati ibẹ ni wọn ti gbe ẹjọ naa lọ si ilu Ilorin ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara.’’
''Gbogbo ẹyin eeyan, gbogbo ẹyin abiamọ aye, ẹ gbami o.
Gbogbo ọmọ Naijiria, ẹ bami da si ọrọ yi o, ki wọn ba mi gbe olubi ọmọ mi silẹ o.
Ijọba ipinlẹ Kwara ati ti orilẹede Naijiria, ẹ bami dasi ọrọ yio,'' Olubukola ke gbajare.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti sọ pe gbogbo awọn nọọsi ati dokita to wa nile iwosan ọhun lọjọ ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ni wọn ti wa lọdọ awọn ọlọpaa fun iwadii.
Adeyemi Adetoun to jẹ agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ ọhun.
O ni lẹyin iwadii ni awọn ti ọrọ kan maa foju ba ile ẹjọ.






