Èéfín ẹ̀rọ amúnáwá pa èèyàn méje, ará ìlú gbarata

Ero amunawa

Oríṣun àwòrán, Others

Kò dín ní èèyàn méje tó pàdánù ẹ̀mí wọn bí wọ́n ṣe bá òkú wọn nínú ilé tí wọ́n ti máa ń ká orin sílẹ̀.

Àwọn èèyàn ọ̀hún ni ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Niger Delta tó wà ní Yenegoa, olú ìlú ìpínlẹ̀ Bayelsa.

Ohun tí wọn furasí pé ó ṣekúpa àwọn èèyàn náà ni èéfín ẹ̀rọ amúnáwá generator.

Ilé iṣẹ́ ìròyìn PUNCH Metro ní òpópónà Transformer Road, agbègbè Amarata, Yenegoa ni ilé tí wọ́n ti máa ń ká orin sílẹ̀ tí ni wọ́n ti bá òkú àwọn ènìyàn náà wà.

Ọ̀kan lára àwọn òkú náà, Akpos Barakubo ló ni ilé orin ọ̀hún.

Ìròyìn ní àwọn èèyàn náà ń ṣiṣẹ́ ní studio lálẹ́ ọjọ́ Ajé tí oorun sì gbé wọn lọ nídìí rẹ̀, tí wọn kò sì rántí pa ẹ̀rọ amúnáwá tí wọ́n tàn láti fi ṣiṣẹ́, tó sì ṣokùnfà ìjàm̀bá náà.

Wọ́n ní òkú àwọn mẹ́fà ni wọ́n kọ́kọ́ bá ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun àmọ́ tí ẹnìkéje ń pọ̀kàkà ikú, tí wọ́n sì sáré gbe dìgbà dìgbà lọ sí ilé ìwòsàn kí òun náà tó jáde láyé.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ti gbé ilé náà tì pa láyé tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, tí wọ́n sì ti gbé àwọn òkú náà lọ sí mọ́ṣúárì.

Àwọn ará àdúgbò náà di ẹ̀bi ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí ru àwọn ìjọba, tó fi mọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìjọba àpapọ̀ àti ilé iṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná ní Port Harcourt pé àwọn ló ṣokùnfà ikú àwọn ọ̀dọ́ náà.

Àwọn ará àdúgbò náà ní tó bá jẹ́ pé iná mọ̀nàmọ́ná bá wà bó ṣe yẹ àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn náà kò ní sọ pé àwọn máa tan ẹ̀rọ amúnáwá láti fi ṣiṣẹ́.

Wọ́n kọminú pé àsìkò tí àwọn tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná bá fẹ́ gba owó nìkan ni wọ́n máa ń múná dé fún àwọn, tí wọ́n sì máa pá ní kété tí wọ́n bá ti gba owó tán.

Wọ́n rọ ìjọba láti máa pèsè iná mọ̀nàmọ́ná lásìkò tó yẹ kí ẹ̀mí àwọn ọmọ Nàìjíríà yé bọ́ sí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí.