Banky W ṣàlàyé bó ṣe bá àrùn jẹjẹrẹ fínra àti bó ṣe rí ìwòsàn

Oríṣun àwòrán, Banky W
Olorin takasufe to ti di oluṣo agutan, Bankole Wellington ti ọpọ eeyan mọ si Banky W ti kede pe oun ti ṣe iṣẹ abẹ fun igba kẹrin lọna ati bọ lọwọ arun jẹjẹrẹ to n ba finra.
Banky W funra rẹ lo fi iroyin naa lede loju opo Instagram rẹ lọjọbọ nibi to ti fi ogo fun Jesus Kristi lori iṣegun to ni lori arun naa.
Iṣẹ abẹ yii lo ṣe lẹyin awọn kan to ti ṣe sẹyin ni nnkan bii ọdun meje sẹyin.
Olorin ọhun dupẹ lọwọ iyawo rẹ, Adesua Etomi, ti oun naa jẹ oloritakasufe fun aduroti rẹ.
Banwy W tun fi akoko naa rọ awọn ololufẹ rẹ ki wọn fi igbagbọ wọn sinu Ọlọrun nikan.
O ni “nigba miran, igbagbọ rẹ ninu Ọlọrun ko ni dena iṣoro... amọ yo mu ọ la iṣoro kọja.
“Ọlọrun ko sọ pe ogun ko ni dide, ṣugbọn o ṣeleri pe ogun naa ko ni bori rẹ... O ṣeleri pe ti awọn ọta ba dide bii alagbalugbu omi, ẹmi Ọlọrun yoo dide ija fun ọ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
O ṣalaye siwaju si pe oun fi kede naa sita lọna ati ṣe iwuri fun awọn ẹlomiran ti wọn ba n la irufẹ idojukọ bẹẹ kọja.
Ọdun 2017 ni Banky W kede pe oun ṣiṣẹ abẹ mẹta ọtọtọ lati yọ tumọ to wa ni ejika oun kuro.
Oniruru arun jẹjẹrẹ lo wa, awọn kan wa to maa n ba awọn obinrin finra wa, nigba ti awọn arun jẹjẹrẹ mii maa n ba awọn ọkunrin finra, bẹẹ naa ni awọn arun awọn jẹjẹrẹ mii le kọlu takọtabo.
Ẹwẹ, ọpọ ololufẹ Banky W lo tibẹrẹ si n ba ṣajọyọ bo ṣe bọ lọwọ arun naa.
Iroyin ni o le ni ẹgbẹrun mẹsan an eeyan to n ni arun jẹjẹrẹ awọ ara lojumọ nilẹ Amẹrika, nigba ti arun ọhun n mu ẹmi eeyan meji lọ laarin wakati kan nilẹ naa.















