Lórí ọ̀rọ̀ oyè Emir ìlú Kano, wo ohun tí ilé ẹjọ́ sọ nípa rẹ̀ níbi ìgbẹ́jọ́ tó wáyé nílùú Kano

Oríṣun àwòrán, Instagram/hrh_aminu_ado_bayero/sanusilamidoofficial
Ile ẹjọ giga apapọ kan nilu Kano ti sun igbẹjọ siwaju lori ẹjọ to wa niwaju rẹ nipa edeaiyede lori alefa Emir ti ilu Kano to n waye laarin Aminu Ado Bayero ati Sanusi Lamido Sanusi.
Aminu Ado Bayero to jẹ Emir karundinlogun ni ilu Kano pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ kan ti ile ẹjọ naa gbe kalẹ pe ko gbọdọ pe ara rẹ ni Emir ilu Kano tabi ṣe oju rẹ. Ile ẹjọ naa paṣẹ nigba naa pe ki awọn agbofinro lọ fi panpẹ ọba gbe e ni.
Onidajọ Amobeda Simon to gbọ ẹjọ naa sun igbẹjọ siwaju lẹyin ti o gbọ awijare igun mejeeji.
Agbẹjọro fun olupẹjọ rọ ile ẹjọ naa lati daabo bo ẹtọ Emir Aminu Ado Bayero ki o si maṣe gba ẹnikẹni laaye lati dun mọhurumọhuru mọ ọ.
Agbẹjọro agba fun ijọba ipinlẹ Kano, Mahmud Magaji tako awijare ati ẹbi olujẹjọ naa; to si rọ ile ẹjọ pe ko fi ẹyin ọwọ da a nu.
Onidajọ Amobeda Simon sun igbẹjọ siwaju leyi to ni yoo jẹ ọjọ ti oun yoo gbe idajọ kalẹ lori ohun ti igun olupẹjọ ati olujẹjọ n beere fun.
Bi ọrọ oye Emir ilu Kano ṣe n fa awuyewuye lati igba ti gomina ipinlẹ Kano ti yọ Ado Bayero gẹgẹ bi Emir ni awọn mejeeji ti n ti ile ẹjọ kan bọ si ikeji.
Ni ọjọ kọkanla oṣu kẹfa ni ile ẹjọ giga kan ni ipinlẹ Kano yoo gbọ ẹjọ tiEmir kẹrindinlogun ni ilu Kano, Sanusi Lamido Sanusi keji pe taki aṣẹ ti ile ẹjọ pa pe ki awọn agbofinro o rii pe wọn yọ ọ kuro laafin.

Oríṣun àwòrán, KAMFA
Ile ẹjọ giga to n jokoo nipinlẹ Kano ti pa a lasẹ fun Aminu Ado Bayero pe ko gbọdọ pe ara rẹ ni Emir ti ilu Kano mọ.
Ileẹjọ tun paṣẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa lati le e kuro ni Aafin to wa lọwọlọwọ bayii.
Adajọ Amina Adamu Aliyu lo gbe idajọ naa kalẹ lọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2024.
Bakan naa ni Ile ẹjọ tun fofin de awọn ori ade marun un; Alhaji Nasiru Ado Bayero, Ibrahim Abubakar II, Alhaji Kabiru Muhammad Inuwa ati Alhaji Aliyu Ibrahim Gaya pe wọn ko gbọdọ ṣafihan ara wọn gẹgẹ Emir Bichi, Gaya, Rano ati Karaye mọ.

Oríṣun àwòrán, Kano Court

Oríṣun àwòrán, Kano Court
Awọn ipo yii ni ijọba to kogba wọle nipinlẹ Kano labẹ Abdullahi Umar Ganduje da silẹ nipinlẹ Kano.
Ile ẹjọ ti wa sun igbẹjọ si ọjọ kọkanla oṣu kẹfa ọdun 2024.
Bẹ ẹ ba gbagbe, Gomina ipinlẹ Kano, Abba Yusuf da Emir ilu Kano tẹlẹ, Sanusi Muhammadu, pada sori itẹ rẹ gẹgẹ bii Emir Kano.
Ọjọ Ẹti, ọjọ kẹrinlelogun, ọdun 2024 ni gomina Yusuf fun Sanusi ni lẹta idapadasipo rẹ ọhun.
Idapadabọsipo yii lo waye lẹyin ọdun mẹrin gbako ti gomina Kano ana, Abdullahi Ganduje, yọ Sanusi bii jiga.
Bakan naa ni Ijọba ipinlẹ Kano labẹ iṣakoso Gomina Abba Kabir Yusuf tun paṣẹ pe ki wọn lọ fi kele ofin gbe Emir to rọ loye, Aminu Ado Bayero.
Gomina Yusuf lo paṣẹ naa ninu atẹjade ti alakoso eto iroyin ileeṣẹ ijọba, Sanusi Bature Dawakin Tofa gbe jade laarọ ọjọ Abamẹta.
Ẹsun ti ijọba Kano fi kan Ado Bayero ni pe o n da họhuhọhu to le da wahala nla silẹ laarin ilu Kano, to si ni awọn ni lati tete fi kele ofin gbe ko too pẹ ju.
Ìfaǹfà lórí oyè Emir Kano, ibi tí ọ̀rọ̀ dé dúró nìyí

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Sanusi/FACEBOOK/MAJEEDA STUDIO
Níṣe ni ọ̀rọ̀ di inú fu àyà fu bí ọ̀rọ̀ oyè Emir ìlú Kano ṣe gba ọ̀nà míì yọ lọ́jọ́ Àbamẹ́ta.
Èyí kò ṣẹ̀yìn bí Emir tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn, Muhammadu Sanusi II àti Emir tí wọ́n yọ nípò, Aminu Ado Bayero ṣe ń pe ara wọn ní ọba Kano.
Emir Sanusi II ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba Kano, tó sì ti wà ní ààfin ìlú, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Emir tí ìjọba yọ nípò, Ado Bayero ti wà ní ààfin Nasarawa tó wà nínú ìlú Kano bákan náà.
Sanusi II tó wọ ààfin lórí ẹṣin pẹ̀lú họ̀bùrẹ́là lórí tó ṣàfihàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Emir.
Ìpadàbọ̀ Sanusi gẹ́gẹ́ bí Emir Kano
Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Karùn-ún, 2024 ni gómìnà ìpínlẹ̀ Kano Abba Yusuf buwọ́lu òfin àwọn lọ́balọ́ba ìpínlẹ̀ náà.
Òfin tuntun náà pa ìdásílẹ̀ àwọn igun lọ́balọ́ba márùn-ún ìyẹ Kano, Bichi, Rano, Karaye àti Gaya tí Ganduje dá sílẹ̀ nígbà tó wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà.
Lẹ́yìn tó buwọ́lu òfin náà tán, gómìnà Yusuf kéde ìyànsípò Sanusi II padà gẹ́gẹ́ bí Emir Kano lẹ́yìn ọdún mẹ́rin tí Abdullahi Ganduje yọ́ nípò náà.
Ẹ̀wẹ̀, Bayero balẹ̀ sí pápákọ̀ òfurufú Aminu Kano International Airport ní nǹkan bíi aago mẹ́rin àbọ̀ òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta, tí àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ sì lọ pàdé rẹ̀ tìlù tìfọn.
Gómìnà Yusuf pàṣẹ kí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fòfin gbé Bayero
Ijọba ipinlẹ Kano labẹ iṣakoso Gomina Abba Kabir Yusuf ti paṣẹ pe ki wọn lọ fi kele ofin gbe Emir to rọ loye, Aminu Ado Bayero.
Gomina Yusuf lo paṣẹ naa ninu atẹjade ti alakoso eto iroyin ileeṣẹ ijọba, Sanusi Bature Dawakin Tofa gbe jade laarọ ọjọ Abamẹta.
Ẹsun ti ijọba Kano fi kan Ado Bayero ni pe o n da họhuhọhu to le da wahala nla silẹ laarin ilu Kano, to si ni awọn ni lati tete fi kele ofin gbe ko too pẹ ju.
Atẹjade ọhun ti akọle rẹ sọ pe ‘Gomina Yusuf paṣẹ ki wọn fi kele ofin gbe Emir Kano ti wọn rọ loye, Aminu Ado Bayero’ ni gomina ti sọ pe oun ko le laju silẹ lati jẹ ki wahala ṣẹlẹ niluu.
“Gomina ipinlẹ Kano, Abba Kabir Yusuf ti paṣẹ pe ki wọn lọ fi kele ofin gbe Emir tiluu Kano tẹlẹ, Aminu Ado Bayero, lori họhuhọhu to n da silẹ nipinlẹ yii.
O ni Emir ana naa wọnu ilu Kano, pẹlu erongba lati fi ipa pada sinu aafin lẹyin ọjọ meji ti gomina ti rọ ọ loye.
O ṣalaye pe eyi lo mu ki gomina, gẹgẹ bi alakoso fun eto aabo ilu ṣe dari Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Kano lati fofin gbe Emir ọhun lai fi asiko ṣofo pẹlu bo ṣe n gbiyanju lati da alaafia ilu laamu.
Tofa tu fi kun ọrọ rẹ pe Emir Muhammadu Sanusi ti pada si aafin to si kọwọrin pẹlu gomina, igbakeji gomina, olori ile igbimọ aṣofin ati awọn alẹnulọrọ ninu ijọba ni nnkan bi agogo kan oru, ọjọ Abamẹta, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2024.
Òfin ilé ẹjọ́ la máa tẹ̀lé - ọlọ́pàa
Nígbà tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ń fèsì sí àṣẹ tí gómìnà Yusuf pa pé kí wọ́n fi kélé òfin gbé Emir Ado Bayero, wọ́n ní àṣẹ ilé ẹjọ́ tó ní kí ìjọba má tù ú àwọn lọ́balọ́ba náà ká ni àwọn máa tẹ̀lé.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kano, Muhammad Hussain Gumel jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ri dájú pé ẹnikẹ́ni kò tẹ òfin lójú mọ́lẹ̀, tó sì àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò máa ri dájú pé ààbò tó péye wà káàkiri ìlú Kano.
Ó ní òfin láà kalẹ̀ kedere pé ẹnikẹ́ni tó b’fẹ́ da omi àláfíà ìlú rú ni kí àwọn fojú rẹ̀ winá òfin, tí àwọn kò sì ní wo bí ẹni náà bá ṣe gàǹgà tó.
Gumel ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn tó bá ń gbèrò láti dá wàhálà sílẹ̀ lórí awuyewuye ìfaǹfà ọ̀rọ̀ oyè tó ń lọ ní ìlú náà pé kí wọ́n pa èrò náà rẹ́, kí wọ́n sì so agbéjẹ́ mọ́wọ́.
Ó ní ẹnikẹ́ni tí ọwọ́ òfin bá bà pé ó da wáhàlá láàárín ìlú máa fi imú gbọ́ òórùn ara rẹ̀ àti pé gbogbo nǹkan ni àwọn ti ṣe láti ri pé àláfíà jọba ní ìlú náà.
NSA ló jẹ́ kí Ado Bayero padà sí Kano
Lẹ́yìn tí Emir tí wọ́n yọ nípò, Ado Bayero padà sí ìlú Kano ni àwọn kan ti ń fẹ̀sùn kàn pé olùbádámọ̀ràn ààrẹ Tinubu lórí ètò ààbò, Nuhu Ribadu ló ń ṣe àtìlẹyìn fún Bayero láti padà sí ìlú Kano.
Àmọ́ agbẹnusọ Ribadu, Zakari Mijinyawa ní irọ́ tò jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà.
Mijinyawa tó sọ̀rọ̀ ní ìlú Abuja ń fèsì sí ẹ̀sùn tí igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Aminu Gwarzo fi kan Ribadu pé òun ló ní kí Bayero padà sí ìlú Kano.
Ṣáájú ni Gwarzo ti fẹ̀sùn kan Ribadu pé ó ń lo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti fi dúnkokò mọ́ àwọn èèyàn Kano, tó sì ní òfin tó de oè jíjẹ ní Kano jẹ́ èyí tó hàn gedegbe tí kò yẹ kí ará ìta dá sí rárá.
Agbẹnusọ Ribadu wá sọ àfọ̀mọ́ rẹ̀ pé Ribadu kọ́ ló pèsè ọkọ̀ òfurufú tí Bayero fi padà sí Kano.
Atiku nàka àléébù sí ìjọba àpapọ̀
Igbákejì ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí, Atiku Abubakar ní Emir tí wọ́n yọ nípò ní Kano, Ado Bayero kò ní padà sí Kano tí kò bá jẹ́ pé ó rí àtìlẹyìn ìjọba àpapọ̀.
Nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí X rẹ̀ lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní èròńgbà láti fi da omi àláfíà ìlú Kano rú kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà àti pé bí ìjọba ṣe da àwọn ọmọ ogun sí ìgboro Kano lórí ọ̀rọ̀ oyè jẹ́ ohun tó lòdì sí òfin orílẹ̀ èdè.
Atiku ní ìgbésẹ̀ ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Kano láti mú àtúnṣe bá òfin tó de ọ̀rọ̀ oyè ní ìpínlẹ̀ náà, àti bí gómìnà ṣe dá Sanusi II padà bíi Emir jẹ́ àwọn nǹkan tó bá òfin mu.
Ó ní ó wá jẹ́ ohun fún òun pé Ado Bayero pẹ̀lú àtìlẹyìn ìjọba àpapọ̀ padà sí ààfin Nasarawa ìlú Kano nígbà tí Muhammadu Sanusi wà ní ààfin Gidan Dabo tó jẹ́ ojúlówó ààfinh gangan.
Ó ní ìjọba àpapọ̀ nílò láti rántí pé ìlú àláfíà ni Kano àti pé nígbà tí wọ́n yọ Sanusi lọ́sún 2020 kò sí wáhàlá kankan tó wáyé ní agbègbè náà, tí kò sì gbọdọ̀ sí wáhàlá kankan lásìkò yìí náà.
Ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP ní ìjọba kò gbọdọ̀ kéde ìlú ò fararọ
Ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria People’s Party (NNPP) ti ṣèkìlọ̀ fún ìjọba àpapọ̀ láti dènà pé àwọn fẹ́ kéde pé ìlú kò fararọ lórí ọ̀rọ̀ oyè Emir Kano.
Àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ ẹgbẹ́ náà, Ladipo Johnson fi léde lọ́ja Àbámẹ́ta ní ìjọba ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC) ń lo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti fi tẹ ìfẹ́ àwọn èèyàn lójú mọ́lẹ̀.















