Báyìí ni Muhammadu Sanusi II ṣe padà sípò Emir Kano

Muhammadu Sanusi

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Sanusi/X

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kano, Abba Kabir Yusuf ti tọwọ́bọ òfin tó de àwọn ọba ní ìpínlẹ̀ náà ti ọdún 2024 lẹ́yìn tí ilé aṣòfin pa òfin ìdásílẹ̀ àwọn ọba márùn-ún tó wáyé lọ́dún 2019 rẹ́.

Lẹ́yìn tó tọwọ́bọ òfin náà, gómìnà náà tún kéde ìyànsípò Khalifa Muhammadu Sanusi Kejì gẹ́gẹ́ bí Emir Kẹrìndínlógún ti Kano, tó sì yọ Aminu Ado Bayero kúrò gẹ́gẹ́ bí Emir.

Pẹ̀lú òfin tuntun yìí, ó túmọ̀ sí pé àwọn òye Gaya, Bichi, Karaye àti Rano tí wọ́n dá sílẹ̀ lọ́dún 2019 ni wọ́n ti parẹ́.

Ní ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, gómìnà Kano nígbà náà, Abdullahi Umar Ganduje yọ Muhammadu Sanusi Kejì nípò gẹ́gẹ́ bí Emir Kano fún àwọn ẹ̀sùn lóríṣiríṣi tó fi mọ́ ṣíṣe àìgbọràn sí ìjọba.

Láti ìgbà tí ìjọba APC ti fìdí rẹmi níbi ètò ìdìbò ọdún 2023, tí ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP sì gba àkóso ìjọba ni àwọn èèyàn kan ti n sọ pé ó ṣeéṣe kí Muhammadu Sanusi padà sí ipò Emir ìlú Kano.

Àti pé àwọn òye ìlú tí wọ́n dá sílẹ̀ náà máa forí sọ́pọ́n.

Ìbáṣepọ̀ tó lóòrìn láti ọdún pípẹ́ ló wà láàárín Khalifa Muhammadu Sanusi àti adarí ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP, Rabiu Musa Kwankwaso.

Kwankwaso, nígbà tó wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà Ìpínlẹ̀ Kano, ló yan Muhammadu Sanusi gẹ́gẹ́ bí Emir kẹrìnlá Kano lẹ́yìn ìpapòdà Alhaji Ado Bayero.

Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn tí Ààrẹ Goodluck Jonathan yọ Sanusi gẹ́gẹ́ bí gómìnà ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà ni Sanusi yàn án gẹ́gẹ́ bí Emir.

Lẹ́yìn tí Rabiu Kwankwaso sọ fún àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn pé àtúngbéyẹ̀wò òfin ìdásílẹ̀ àwọn ọba Kano márùn-ún lọ́dún 2024 ni àwọn èèyàn ti ń rò ó pé wọ́n máa dá Sanusi padà.

"Ẹ̀san ìwà àìda"

Sanusi àti Kwankwaso

Oríṣun àwòrán, MAJEEDA STUDIO

Àwọn abẹ́nọ̀ ìmọ̀ kan sọ pé láti ìgbà tí ìpolongo ìdìbò ni Sanusi ti ṣe àtìlẹyìn fún Abba Kabir Yusuf, tí àwọn alátìlẹyìn Sanusi náà sì tẹ̀lé NNPP.

Dókítà Kabir Sufi tó jẹ́ olùkọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ CAS Preparatory College ní Kano ṣàlàyé pé ó hàn gbangba pé Ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín Kwankwaso àti Sanusi ló ṣokùnfà ìdí tó fi padà sí ipò Emir rẹ̀.

Ìbéèrè tó gba ẹnu àwọn èèyàn báyìí ni pé ṣe ó ṣeéṣe kí ìyànsípò yìí tọ́jọ́?

Dókítà Kabir Sufi ní ó ṣeéṣe kí ìyànsípò náà tọ́jọ́ tàbí kí ìṣòro wà lọ́jọ́ iwájú àmọ́ gbogbo rẹ̀ wà lọ́wọ́ bí àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn bá ṣe gba ọ̀rọ̀ náà.

Ìdí mẹ́ta tí Ganduje fi yọ Sanusi nípò

Ganduje àti Sanusi

Oríṣun àwòrán, Kano state govt

Ní ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹta ọdún 2020 ni ìjọba Kano kéde ìyọnípò Muhammadu Sanusi kúrò nípò gẹ́gẹ́ bí Emir Kano.

Àtẹ̀jáde tí akọ̀wé ìjọba nígbà náà, Alhaji Usman Alhaji ní gbogbo ìgbìmọ̀ aláṣẹ ìjọba Kano nígbà náà ló panupọ̀ láti Sanusi.

Lára àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n kà sí i lọ́rùn ni:

Títako àwọn ètò ìjọba - Ìdí pàtàkì tí wọ́n ṣe yọ Sanusi nípò Emir Kano ni pé ó máa ń tako gbogbo ètò ìjọba Ganduje.

Àìgbọràn - Àtẹ̀jáde ìjọba nígbà náà ní Sanusi máa ń ṣe àìgbọràn, tí kìí tẹ̀lé àṣẹ ìjọba, tó fi mọ́ wí pé kì í yọjú sí ìpàdé tí ìjọba bá pè é sí láì sí ìdí kan pàtó.

Òṣèlú - Àwọn alátìlẹyìn ìjọba Kano nígbà náà máa ń fi ẹ̀sùn kan Sanusi pé ó máa dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú tí kò sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀.

Ta ni Muhammadu Sanusi II?

Muhammadu Sanusi II

Oríṣun àwòrán, MAJEEDA STUDIO

  • Ní ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún 1961 ni wọ́n bí Sanusi sínú ẹbí oyè, tó sì jẹ́ ìran Fulani.
  • Ọmọ ọmọ ló jẹ́ sí Ọba Sanusi Kano tí wọ́n rọ̀ lóyè nígbà ayé rẹ̀.
  • Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmò ọrọ̀ ajé, ẹ̀sìn Islam àti iṣẹ́ ọnà.
  • Ní oṣù Kẹfà ọdún 2009 ló di gómìnà ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà, CBN.
  • Ó gba àmì ẹ̀yẹ òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ tó dára jù lọ lọ́dún 2010 látọwọ́ Banker Magazine.
  • Lẹ́yìn tí ó ní èdè àìyedè pẹ̀lú Ààrẹ Goodluck Jonathan ni wọ́n yọ ọ́ nípò gómìnà CBN lọ́dún 2014.
  • Ní oṣù Kẹfà 2014 bákan náà ni wọ́n yàn án sípò Emir Kano kẹrìnlá.
  • Ó pá orúkọ rẹ̀ dà kúrò ní Sanusi Lamido Sanusi di Muhammadu Sanusi II.
  • Oṣù Kẹta ọdún 2021 ni wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí Kàlífà Tijaniyyah ti Nàìjíríà.
  • Ó ní ìyàwó mẹ́rin, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ àti ọmọọmọ.