Àwọn tó kú níbi mọ́ṣáláṣí tó dàwó l’Ékòó ti di mẹ́ta

Aworan ibi iṣẹlẹ naa

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Ileeṣẹ to n ri sọrọ iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA ti sọ pe awọn ti padanu ẹmi wọn nibi ijamba mọṣalaṣi to da wo ladugbo Yusuf, Papa Ajao ni Mushin ti di mẹta bayii.

Ninu atẹjade ti LASEMA gbe sita laipẹ yii ni wọn ti jẹ ko di mimọ agbalagba ni ẹni ti wọn ri oku rẹ yọ labẹ ile naa, eyi to fi jẹ ki awọn eeyan naa jẹ mẹta.

Eyi lo jade lẹyin ti alakoso eto amuṣẹṣe ileeṣẹ naa, Ọlatunde Akinsanya sọ fun BBC nibi iṣẹlẹ ọhun lọjọ Aiku, ana pe awọn ọmọde meji lo ku, nigba ti awọn marun-un farapa.

Akinsanya sọ pe ọkan ninu awọn ọmọ naa ku nibi iṣẹlẹ yii, nigba ti ọkan yooku ku lasiko ti wọn n gbe e lọ si ọsibitu fun itọju.

Ninu ọrọ ti LASEMA gbe sita, “Pẹlu igbiyanju wa, awọn to ti jade laye lori ijamba mọṣalaṣi to da wo naa ti di mẹta bayii, ti awọn to si farapa yannayanna tun ti di meje.

“Ile to da wo naa ni a ti fi n pa ilẹ rẹ lati ko awọn ẹru buruku kuro.”

Ọmọdé méjì ló ti jáde láyé níbi ìṣẹ̀lẹ̀ Mọ́sálásí tó dàwó l'Eko- LASEMA

Aworan Mọsalasi to dawo nipinlẹ Eko

Awọn ọmọde meji kan ni wọn ti kan agbako iku ojiji lasiko ti Mọsalasi kan dawo ni agbegbe Papa Ajao nipinlẹ Eko.

Iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Yusuf Street, loju ọna marose Ladipo, Papa Ajao nipinlẹ Eko

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Adetunji Adesanya, to jẹ osisẹ LASEMA ni awọn gba ipe ni nnkan bi ago mọkanla pe Mọsalasi kan dawo, ti awọn sure de si agbegbe naa.

Adesanya ni awọn ọmọde meji lo ba iṣẹlẹ naa ti eeyan meji mii si farapa.

O ni awọn mẹta ni awọn yọ kuro labẹ ile naa lia farapa

“Ọkan ni awọn ọmọ ku lẹsẹkẹsẹ ti ikeji si gbẹmi mi ni ile iwosan.

“Awọn ọmọ yii wa ni ọmọ ọdun mọkanla si mẹtala.

”Eeyan meji lo ku, ti eeyan meji mii farapa sugbọn eeyan mẹta ni doola ẹmi lia farapa.”

Aworan Mọsalasi to dawo nipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bakan naa ni Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin tun fidi iṣẹlẹ naa mulẹ nigba to n ba ikọ BBC News Yoruba sọrọ.

O ni “Nnkan ti mo fidi rẹ mulẹ bayii ni pe wọn ti wọ oku ọmọ ọdun mọkanla kan to jẹ obinrin jade.

“Igbiyanju lati doola ẹmi awọn eeyan si n lọ lọwọ.”

Iṣẹlẹ naa waye ni agbegbe Yusuf Street, loju ọna marose Ladipo, Papa Ajao nipinlẹ Eko

Akọwe agba fun ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko LASEMA, Olufemi Damilola Oke Osanyintolu lo fi idi iroyin naa mulẹ fun ikọ BBC.

Osanyintolu ni iṣẹlẹ naa waye lasiko ti awọn olujọsin n kirun ọsan lọwọ ninu Mọsalasi naa.

O ni ohun to isẹlẹ naa ni erọ katakata to ṣe si kọlu Mọsalasi naa lasiko to sisẹ loju opopona.

O fikun pe iṣẹ ti bẹrẹ lati wa awọn eeyan to ba ha sabẹ Mọsalasi naa ni kiakia.

Ko ki ṣe igba akọkọ re ti ile yoo dawo ni agbegbe Ilu Eko.

Ọdun 2023 ni ile alaja meje kan dawo ni agbegbe Banana Island.

Bakan naa lọdun 2022 ni agbegbe Lekki, ile alaja meje kan naa dawo.

Ijọba ipinlẹ Eko jẹ ko di mimọ pe awọn ile to dawo ni ijọba ko buwọle.

Aworan Mọsalasi to dawo nipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Aworan Mọsalasi to dawo nipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, LASEMA

Aworan Mọsalasi to dawo nipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, LASEMA