Èèyàn 670 há sábẹ̀ ilẹ̀ níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ ríri ni Papua New Guinea

Aworan bi wọn se n wọ awọn eeyan jade labẹ ilẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O le ni eeyan 670 to ha sabẹ ilẹ lẹyin ti iṣẹlẹ ilẹ riri nla kan waye ni orilẹede Papua New Guinea, ajọ agbaye UN ṣalaye.

Awọn alaṣẹ ni ilẹ riri nla mi abule kan titi ni Papua Guinea lọjọ Kẹrinlelogun oṣu karun un, ti wọn si n bẹru pe ọpọ eeyan lo ti le ba iṣẹlẹ naa lọ.

Serhan Aktoprak, olori ẹgbẹ irinajo ni Papua Guinea ni ipa ti iṣẹlẹ naa ti ko ni agbegbe Enga kọja nnkan ti ẹnu le sọ.

“Ile to le 150 lo ti dawo.” Aktoprak ṣalaye.

Aktoparak tẹsiwaju pe awọn eeyan to n gbiyanju lati doola ẹmi awọn eeyan n bẹru fun ẹmi ara wọn naa nitori ilẹ naa si n mi.

“Omi n le te, eyi si jẹ ewu nla fun gbogbo awọn to wa ni ibẹ.”

O to ẹgbẹrun mẹrin eeyan to n gbe ni agbegbe ti ilẹ riri ti waye.

O le ni ẹgbẹrun kan eeyan ti iṣẹlẹ yii ti sọ di alai ni ile lori mọ.

Aktoprak ni gbogbo agbala ti n wọn fi omi ati ounjẹ pamọ lo ti fẹ gbẹ tan.

Iṣẹlẹ ilẹ riri yii waye ni bi nnkan bi ago mẹta lọjọ Ẹti lasiko ti ọpọ awọn eeyan n sun lọwọ.

O ni awọn eeyan lo n pese iranlọwọ n lo ohunkohun lati fi doola ẹmi awọn eeyan to ha sabẹ ilẹ

Ni Ọjọ Aiku, wọn ti yọ oku eeyan marun un to ha sabẹ ilẹ.

Ileeṣẹ iroyin AFP ni ohun yoo de si agbegbe ni lọjọ Aiku

Olootu ijọba Australia, Anthony Albanese sọ pe orilẹede ti ṣetan lati ran “awọn ọmọ iya wa ni orilẹede Papau Guinea lọwọ.”

Aworan bi wọn se n wọ awọn eeyan jade labẹ ilẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images