Wo àwọn ọ̀nà tó dára láti gba ọyàn lẹ́nu ọmọ

Ìyá tó ń fún ọmọ lọ́yàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbígba ọyàn lẹ́nu ọmọ jẹ́ ìpele tó ṣe pàtàkì sí ìdàgbàsókè ọmọ tó sì jẹ́ ohun ẹlẹgẹ́ tí èèyàn nílò láti fi ẹ̀sọ̀ ṣe.

Àkókò yìí ṣe pàtàkì fún ìyá tó fẹ́ gba ọyàn lẹ́nu ọmọ àti ọmọ tí wọ́n fẹ́ gba ọmú lẹ́nu rẹ̀ nítorí ó nííṣe pẹ̀lú ìlera àyá àti ọmọ gẹ́gẹ́ bí àwọn onímọ̀ ṣe sọ.

Àkókò yìí ni ìyá máa ń fún ọmọ ní oúnjẹ yàtọ̀ sí omi ọyàn tó ti ń mú fún ọdún kan sí ọdún méjì, tí ọmọ yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ gbogbo oúnjẹ yàtọ̀ sí ọyàn nìkan.

Ní ilé ìwòsàn Gaspard Kamara health center ní Dakar, orílẹ̀ èdè Senegal, Ndèye Awa ń fún ọmọ rẹ̀, ọmọ oṣù mẹ́fà lọ́yàn.

Abẹ́rẹ́ àjẹsára àti ìtọ́jú ọmọ rẹ̀ ló gbé Ndèye lọ sí ilé ìwòsàn.

Ó ní ọmọ òun fẹ́ràn láti máa lo fídà nítorí náà ni òun ṣe máa ń fún ní ọyàn ní gbogbo ìgbà àti pé ara òun máa ń balẹ̀ nígbà tí òun bá ń sọ̀rọ̀ nípa gbígba ọyàn loẹ́nu ọmọ.

Ó ṣàlàyé pé gẹ́gẹ́ bí àṣà àti ìṣe àwọn, ọdún méjì ni òun fi fún àkọ́bí òun lọ́yàn nítorí ọkùnrin tó jẹ́ ṣùgbọ́n ọdún kan àti oṣù mẹ́ta ni ọmọbìnrin tí òun bí ṣìkejì wà tí òun fi gba ọyàn lẹ́nu rẹ̀.

Ndèye Awa ní ìpinnu òun àti ọkọ òun ni pé omi ọyàn nìkan ni àwọn máa fún ọmọ àwọn fún oṣù mẹ́fà gbáko kó tó di wí pé àwọn tó máa bẹ̀rẹ̀ sí ní fun wọn ní oúnjẹ kankan.

Gbígba ọyàn lẹ́nu ọmọ díẹ̀ díẹ̀ àti pátápátá

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ilẹ̀ Adúláwọ̀, gẹ́gẹ́ bí ti Awa, ọdún kan àbọ̀ sí ọdún méjì ni àwọn ìyá sábà máa fi ń fún ọmọ lọ́yàn kí wọ́n tó gba ọmú lẹ́nu rẹ̀.

Ètò gbígba ọyàn lẹ́nu ọmọ máa ń bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú fífún wọn ní oúnjẹ bíi ìrẹsì, ọ̀gẹ̀dẹ̀, ẹja, ẹran, mílíkì, ẹ̀kọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Ní orílẹ̀ èdè Senegal àṣà àti ìṣe wọn ni fún ìyá tó bá fẹ́ gba ọyàn lẹ́nu ọmọ láti gbé ọmọ náà lọ sí ọ̀dọ̀ ìmáàmù láti ka kéwú sínú oúnjẹ tí wọ́n bá fẹ́ fú ọmọ náà jẹ, tí ọmọ náà bá sì ti jẹ oúnjẹ yìí, wọn ò ní fún ní ọyàn mọ́.

“Kí a tó gba ọyàn lẹ́nu ọmọ pátápátá, a ti máa kọ́kọ́ máa fun ní àwọn oúnjẹ tí à ń jẹ láì fi ata tàbí òróró púpọ̀ si.”

Awa ṣàlàyé pé àwọn tó gba ọyàn lẹ́nu ọmọ pátápátá, àwọn á ti kọ́kọ́ máa gba díẹ̀ díẹ̀ nípa ríri pé ọyàn tí ọmọ ń mu lójú ọ̀sán kò pọ̀ tó oúnjẹ gidi tó ń jẹ, tó sì jẹ́ pé òòru nìkan ló ń mu ọyàn púpọ̀.

Nígbà tí ọmọ kò bá mju ọyàn mọ́ rárá ló túmọ̀ sí pé èèyàn ti gba ọyàn lẹ́nu ọmọ.

Àwọn dókítà ọmọdé àtàwọn onímọ̀ nípa oúnjẹ máa ń fún àwọn ìyá ní ìmọ̀ràn láti máa gba ọyàn lẹ́nu ọmọ díẹ̀díẹ̀ kí wọ́n tó gbà á pátápátá láti má le jẹ́ kó ṣe ìpalára fún ọmọ.

Èyí yóò tún ṣe àǹfàní fún ọmọ láti le ti máa jẹun tí yóò ṣe ara lóore fún-un tí wọ́n bá gba ọyàn náà tán.

Kí ni ìpalára tó wà nínú gbígba ọyàn lẹ́nu ọmọ lẹ́ẹ̀kan náà?

Ìyá tó ń fún ọmọ lọ́yàn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbígba ọyàn lẹ́nu ọmọ gba ètò, tó sì yẹ kó máa wáyé díẹ̀díẹ̀ kó tó di pé ìyá gba ọyà lẹ́nu ọmọ pátápaátá.

Àwọn onímọ̀ gbígba ọyàn lẹ́nu ọmọ lẹ́ẹ̀kan náà le ṣe àkóbá fún ọmọ nítorí náà ó dára kí ìyá fi kọ ọmọ kí wọ́n tó gba ọmú loẹ́nu r.

Dókítà Borel Zebaze tó jẹ́ onímọ̀ nípa oúnjẹ àwọn ọmọdé ní kí ọmọ tó pé oṣù mẹ́fà, àwọn ẹ̀yà ara tó máa ń lọ oúnjẹ nínú èèyàn, kò lè ti dàgbà débi tí yóò lè máa lọ oúnjẹ nínú ọmọ ju omi ọyàn lọ.

Ó ní tí ìyá bá ṣàdédé gba ọyàn lẹ́nu ọmọ láì kọ́kọ́ máa gbà á díẹ̀díẹ̀ le fa kí ọmọ bẹ́ẹ̀ ṣe àìsàn tàbí kó má lè máa jẹun dáadáa.

Ó fi kun pé ọmọ náà kò ní ní àǹfàní láti máa fi ara ro ara pẹ̀lú ìyá rẹ̀ tó máa ń wáyé nígbà tí ìyá bá ń fún ọmọ lọ́yàn.

Bákan náà ló ní ọyàn ìyá bẹ́ẹ̀ máa wú, tí yóò sì máa dùn-ún.

Báwo ló ṣe yẹ kí ìyá gba ọyàn lẹ́nu ọmọ nírọ̀rùn?

Dókítà Borel Zebaze sọ fún BBC pé láti ìgbà tí ìyá bá ti kọ́kọ́ bí ọmọ, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní funní ọyàn ló ti yẹ kí ó máa múra bí ó ṣe máa gba ọyàn lẹ́nu ọmọ náà.

Ó ní ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni pé kí ìya fún ọmọ ni omi ọyàn nìkan, láì fun ni omi tàbí oúnjẹ míì fún oṣù mẹ́fà gbáko.

Ó sọ pé lẹ́yìn oṣù mẹ́fà yìí ni ìyá gbọdọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ wá máa fi àwọn oúnjẹ mìíràn kọ́ ọmọ náà díẹ̀díẹ̀, tí yóò sì tún máa fun ní ọyàn tí ọmọ náà ma fi pé ọdun méjì.

Dókítà náà ní lásìkò yìí, àwọn oúnjẹ bíi ẹ̀fọ́, ẹja, ẹyin, ẹran àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ dára láti máa fún àwọn ọmọ lásìkò tó bá ṣì ń mu ọyàn lọ́wọ́.

Ó ní àsìkò ni ìyá yóò máa ṣe àmójútó bí ọmọ ṣe ń jẹun si àti pé ibẹ̀ ni ìyá yóò ti mọ àwọn oúnjẹ tí ọmọ rẹ̀ fẹ́ràn, àtàwọn tó máa ń mú ìpalára kan tàbí òmíràn, tí wọn yóò sì lè máa mọ irú oúnjẹ tí ọmọ náà yóò máa jẹ lẹ́yìn tí wọ́n bá gba ọyàn lẹ́nu rẹ̀ tán.