Ẹ gbà mí, inú ìrora ni mo wà, mi ò sì fẹ́ kú ní kékeré, Portable pariwo síta

Oríṣun àwòrán, Instagram/Portablebaby
Gbajugbaja olorin takasufe, Habib Okikiola, ẹni ti ọpọ mọ si Portable ti kigbe sita pe oun ko fẹ ku ni kekere lẹyin to dero ile iwosan.
Portable bọ sori opo ayelujara rẹ, to si fi awọn fọnran ibi to ti n gba itọju sita pẹlu alaye pe ara n ni oun, ti oun ko si fẹ ku lojiji.
O ṣalaye pe oun ko kabamọ ohunkohun, ti o si gba jumọ ohun ti yoo ṣe oun ni anfani.
Ninu fọnran mii ti Portable tun gbe sita, o fi da awọn ololufẹ rẹ loju pe ko si iku loju oun, ti oun si wa laaye sugbọn ara n ni oun.
“Gbogbo ara mi lo ni mi, ki ẹnikan gbadura fun mi. N ko fẹ ku ni kekere.

Oríṣun àwòrán, screenshot
“Ẹma ṣe foya, ara si n ni mi sugbọn mo wa laaye.
“Bobo o ni ku ni kekere”
Ni ọjọ kẹdogun oṣu karun un ni Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko kede sita pe wọn mu Portable fun ẹsun pe o kuna lati san owo to fi ra ọkọ G-Wagon.
Ohun taa ri gbọ ni pe Portable ra ọkọ ayọkẹlẹ G-wagon, ti owo rẹ jẹ milọnu mẹtalelogun naira sugbọn o san milọnu mẹtala fun oni mọtọ, to kọ lati san owo yooku.
Fọnran to wa lori ayelujara fihan pe ọpọ igba ni ẹni ti Portable jẹ lowo ti kesi sugbọn o ni Portable kọ lati san owo naa pada, eyi to fa to fi wa fi ọlọpaa gbe Portable.
Nigba ti akitiyan lati jẹ ki Portable san owo ja si pabo lo jẹ Ontaja mọto kesi ileeṣẹ ọlọpaa pe ki wọn wa dasi ọrọ naa.
Ko pẹ ni Portable gba itusilẹ kuro ni ahamọ ileeṣẹ ọlọpaa lẹyin to gba beeli.















