Ẹ̀kún omi àti ohun tó yẹ kí o ṣe bí omíyalé bá ṣẹlẹ̀ láyíká rẹ

Aworan ọmọkunrin kekere kan to n wo ọṣẹ́ ti ẹkun omi ṣe lẹkule awọn obi rẹ leyin ẹkun omi to ṣẹlẹ lọjọ kọkandinlogun, oṣu karun-un ọdun 2024, lorilẹ-ede Afghanistan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Iṣẹ kekere kọ leeyan yoo ṣe lati tun ayika ti ẹkun omi ti waye ṣe lẹyin iṣẹlẹ naa. Ọpọ dukia lo si maa n bajẹ pẹlu, bẹẹ ni amọ yoo kun gbogbo ilẹ

Ọṣẹ́ kekere kọ ni ẹkun omi ti ṣe kaakiri awọn orilẹ-ede agbaye lati ibẹrẹ ọdun 2024 titi di akoko yii. Koda, awọn eeyan ti wọn ko nile lori mọ ti wọ ẹgbẹrun niye

Iwadii fi han pe ojo nla-nla to n rọ n pọ si i lawọn ọpọlọpọ ilu lagbaaye, ohun to si n fa eyi ko ṣẹyin ayipada oju ọjọ.

Awọn akọṣẹmọṣẹ nipa oju ọjọ si ti ṣẹkilọ, wọn ni o ṣee ṣe ki omi nla tẹsiwaju lati maa bọ lati oju ọrun .

Orilẹ-ede Naijiria, Afghanistan, Brazil, Indonesia, Kenya, Oman ati United Arab Emirates jẹ diẹ lara awọn ilu to ti koju ẹkun omi ni 2024 yii.

Ko si waa si ẹkun omi to ṣẹlẹ ti ko mu ipayinkeke dani. Ọpọ dukia lo ṣegbe ti awọn eeyan mi-in ko si ribi gbe mọ.

Ninu iroyin yii, a ṣagbeyẹwo ohun to n fa ẹkun omi, idi to fi n ṣẹlẹ lemọlemọ ati ohun ti o le ṣe lati ran ara rẹ pẹlu awọn eeyan mi-in lọwọ bi ẹkun omi ba ṣẹlẹ.

Kí ni ẹ̀kún omi?

Ẹkun omi gẹgẹ bi orukọ rẹ, tumọ si igba ti omi ba kun kọja aala to si bo ilẹ gbigbẹ mọlẹ. To bori ile, bori oko.

Ẹkun omi jẹ ọkan lara awọn iṣẹlẹ ti ẹda ko ni ikapa lori rẹ ju bẹẹ lọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O le waye yipo ọdun, ṣugbọn ayipada oju ọjọ maa n fa ki ojo maa rọ ju bo ṣe yẹ lọ, eyi to n fa ẹkun omi.

Ijamba to pọ ni ẹkun omi maa n mu wa lasiko ọgbẹlẹ.

" Eyi tumọ si pe ilẹ ti le gan-an o si ti gbẹ. Bi omi to lagbara ba wa n bọ sori ilẹ lasiko naa, ilẹ ko ni i tete fa a mu.

Omi naa yoo waa jokoo le ori ilẹ, bi ko ba ti wọlẹ, yoo di ọgbara, yoo fa ẹkun omi'' Bẹẹ ni ẹgbẹ Red Cross ilẹ Gẹẹsi ṣalaye.

Ẹkun omi le fa ajalu to kari aye, o le jẹ ki ẹmi sọnu, o n ba dukia eeyan jẹ, o si tun le ko ba ilera araalu.

Gẹgẹ bi ajọ Iṣọkan Agbaye ,United Nations, (UN) ṣe ṣalaye, wọn ni laarin ọdun 1998 si 2017, eeyan to le ni biliọnu meji lo koju ẹkun omi lagbaaye.

Awọn eeyan ti ẹkun omi maa n da laamu ju ni awọn ti wọn n gbe labẹ atibaba, àlàpà ati awọn ibugbe alaini ti wọn n dọgbọn foripamọ si .

Ajọ Iṣọkan Agbaye si tun sọ pe awọn ti wọn n gbe nibi ti wọn ko ti ki n gbọ ikede ewu to n bọ naa n koju ẹkun omi.

Bẹẹ lawọn mi-in ti ko mọ pe agbegbe to lewu lawọn kọle si naa yoo koju iṣoro yii bi omi nla ba de.

Aworan awọn oṣiṣe ẹgbẹ Red Cross ni Kenya ti wọn fẹẹ lọọ ran awọn ti omi sepa mọle lọwọ, lẹyin ti odo kan kun kọja aala lẹyin ojo nla to rọ lọjọ kin-in-ni, oṣu karun-un ọdun 2024

Oríṣun àwòrán, Reuters

Kí ló ń fa ẹ̀kún omi?

Ojo nla to rọ ti ko da bọrọ aa maa fa ẹkun omi, bi yinyin ba n yara yoro silẹ, tabi ti odo nla kun naa n fa ẹkun omi.

Mẹta ni ẹkun omi to gbajumọ ju, awọn naa ni:

  • Ẹkun omi to waye nigba ti arọọda ojo rọ ti aaye ko si lori ilẹ fun omi mọ, ti omi ya sibi gbogbo bii inu ile, oju ọna, ori ile, inu mọto, inu odo ati bẹẹ bẹẹ lọ.
  • Nigba ti ojo nla ba n rọ leralera ti odo kun kọja bèbè ati agbara rẹ.
  • Ati ẹkun omi to n waye nigba ti iji lilẹ ba n ja ilẹ loju kan. Lẹyin iji ilẹ naa ni ojo nla yoo rọ, ti yoo si ya bo gbogbo agbegbe. Apẹẹrẹ rẹ ni eyi ti wọn n pe ni tsunami.

Ajọ Iṣọkan Agbaye (UN), sọ pe ẹkun omi, ọgbẹlẹ, iji lile ati ooru amuju ko ida ọgọrin si aadọrun-un ( 80-90%) ninu ijamba tawọn eeyan koju lagbaaye lati ọdun kẹwaa si asiko yii.

Aworan awọn mọto ti ẹkun omi bori wọn mọlẹ lẹyin ẹkun omi to ṣẹlẹ ni Eldorado do Sul, Brazil, lọjọ kẹtala, oṣu karun-un ọdun 2024.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, O le ni idaji miliọnu eeyan ti wọn ko rile gbe mọ lorilẹ-ede Brazil, lẹyin ti ojo nla rọ loṣu karun-un ọdun yii. Eeyan ọgọjọ (160) lo si di oloogbe.

Kí ló dé tí ẹ̀kun omi fi léwu?

Ẹkun omi n ba ile jẹ, o n ṣakoba to nipọn fun lilọ-bibọ awọn eeyan ati ọkọ wiwọ. Bakan naa lo le da gbese si eeyan lọrun nigba ti ọrọ aje ko ba ṣee ṣe mọ.

Iranlọwọ ti ko kere ni awọn eeyan ti ẹkun omi ba koju ẹ yoo nilo.

Wọn ko ni i le da aye wọn ṣe fun ọpọlọpọ ọjọ, ọsẹ, oṣu tabi ọdun paapaa, gẹgẹ bi ẹgbẹ Red Cross ilẹ Gẹẹsi ṣe ṣalaye.

Omi maa n gbe eeyan lọ, bẹẹ naa lo n gbe mọto.

Omi to mọ niwọn loju eeyan, o le ṣe bẹẹ gbe gende lọ pẹlu odidi mọto.

Aworan awọn foto mọlẹbi to bajẹ latari ẹkun omi to wọle ni Eldorado do Sul, Brazil, l'ogunjọ , oṣu karun-un ọdun 2024.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Yatọ si eyi, ẹkun omi le wọ ileegbọnsẹ, ko da ẹgbin pọ mọ omi mimu ko si ba a jẹ.

Bi eeyan ba lo iru omi bẹẹ fun ohunkohun, arun ni yoo fa, ajakalẹ arun yoo si bẹ silẹ laipẹ rara.

" Ẹkun omi le sọ atijẹ-atimu di inira, ile gbigbe ko ni i si mọ, oogun lilo yoo di dandan lati maa ra fun ilera to peye, ko ni i si aṣọ lọrun mọ, koda, owo gan-an to n bẹ nile le ti ba omi lọ.

Awọn eeyan ti wọn ba ti ṣeto ma-da-mi-dofo (Insurance) silẹ le maa ro o pe ko sewu, ṣugbọn ko dẹrun lati ri owo inṣọọransi ọhun gba lasiko lati yanju iṣọro airotẹlẹ ọhun.

Awọn ileeṣẹ adojutofo naa si ti gbọn, wọn ko ni i fẹẹ sanwo leralera fun ẹni ti ẹkun omi n yọ lẹnu nigba gbogbo.

Ṣugbọn lọpọ ilu lagbaaye, ọpọ eeyan to n koju ẹkun omi ki i ṣe inṣọransi, bi wahala naa ba ṣẹlẹ, wọn yoo maa gbọ ọ funra wọn ni.

Bí o ṣe lè dá ààbò bo ara rẹ lasiko ẹ̀kun omi

Gẹgẹ bi awọn akọṣẹmọṣẹ ṣe ṣalaye, eyi lawọn ohun to yẹ ki o ṣe lasiko ẹkun omi :

  • Tete pe nọmba pajawiri nibi to o ba ti ri i pe ẹmi rẹ n bẹ ninu ewu ẹkun omi.
  • Ma ṣe rin, wẹ tabi wa ọkọ ninu agbara omi to kún.
  • Omi ti ko gun ju ẹsẹ bata mẹfa, ti ko kọja '15 centimetres' le yara gbe ọ ṣubu sinu omi, bẹẹ lo si le gbe mọto lọ raurau
  • Ma ṣe rin ori awọn pepele tabi bèbè odo.
  • Yago fun omi to kun bii àgbàrá ojo, igbọnsẹ ati awọn ẹgbin oriṣiiriṣii le ti dapọ mọ ọn.
  • Bi o ba ba ara rẹ ninu omi àgbàrá to kun oju ọna, fọ ọwọ, ẹsẹ ati aṣọ rẹ ninu omi to mọ geere lẹyin ti o ba jade nibẹ tan.
  • Ma ṣe gba awọn ọmọde laaye lati maa fi omi to kún ṣere
Aworan mọto ti omi kun bo ni United Arab Emirates, Dubai, lẹyin ojo kejidinlogun, oṣu kẹrin 2024.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ìdí tí ẹ̀kún omi fi ń wáyé léraléra tó sì ń lágbára

Ajọ UN ṣalaye pe ayipada oju ọjọ n waye, eyo yoo si maa mu ojo rọ leralera.

" Bi oju ọjọ ṣe n mooru si i, bẹẹ ni ọwọja rẹ yoo maa pọ si i. Ojo nla nla yoo si maa rọ

Awọn onimọ ijinlẹ sọ pe ayipada oju ọjọ naa ko deede waye, wọn ni awọn eyi to ti ọwọ ọmọniyan wa pọ nibẹ.

Awọn mi-in yoo si ṣẹlẹ pẹlu iṣẹda aye gẹgẹ bi wọn ṣe ṣalaye.

Iru ojo agbayanu to rọ ni Dubai ati Oman loṣu kẹrin ọdun yii, wọn ni o ṣoro lati sọ boya ayipada oju ọjọ lo fa a.

Eyi ri bẹẹ nitori ojo nla ki i saaba rọ lapa ibẹ yẹn bi awọn onimọ Sayẹnsi ṣe sọ.

Ṣugbọn ẹgbẹ kan, World Weather Attribution (WWA), ṣalaye pe ayipada oju ọjọ nikan lo le fa ojo arọọda, eyi to pọ si i ni ida mẹwaa si ogoji (10-40% heavier rain)

Aworan to n ṣafihan bi ooru ṣe le fa arọọda ojo

" Bi awọn eeyan ba ṣi n lo gaasi, eedu ati epo idana, oju ọjọ yoo tẹsowaju lati maa mooru.

Ojo yoo tẹsiwaju lati maa pọ si i, awón eeyan yoo si maa padanu ẹmi wọn sinu ẹkun omi "

Bayii ni Dokita Friederike Otto, olukọ agba nipa oju ọjọ lati Imperial College niluu London wi.

Omiyale rẹpẹtẹ waye lawọn apa kan Ila-Oorun Afrika ninu oṣu kẹrin ọdun 2024 yii naa.

Iwadii lai sinmi si ni awọn onimọ n ṣe bayii lati mọ iṣẹ ayipada oju ọjọ gan-an.