Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásiti Ajayi Crowther lu akẹgbẹ́ wọn pa nítorí fóònù, ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Others
Ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí ni fídíò kan gba orí ayélujára níbi tí àwọn ti ń na ọ̀dọ́mọkùnrin kan ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Ajayi Crowther University, Oyo.
Fídíò ọ̀hún ṣàfihàn bí àwọn géńdé ọkùnrin bíi mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ṣe ti ọmọkùnrin mọ́ inú ilé, tí wọ́n sì ń dá sẹ́rìá fun.
Bí wọ́n ṣe ń nà án ni wọ́n tún gé irun orí rẹ̀, tí ilẹ̀ ibi tí wọ́n sì ti ń nà án kún fún omi, èyí tó túmọ̀ si pé wọ́n da omi si lára kí wọ́n tó máa lù ú.
Ìròyìn ní ọmọkùnrin náà, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọmọba Alex Timi pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ látàrí ìyà tí wọ́n fi jẹ́ náà.
Lẹ́yìn náà ni ìròyìn jáde pé ọmọba Olu ti ìlú Warri ní ìpínlẹ̀ Delta ni Alex Timi tó jáde láyé náà.
Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ Ajayi Crowther University, Ibukunoluwa Taiwo, ó ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni àwọn kan wá pé òun pé akẹ́kọ̀ọ́ àwọn kan ni ẹ̀mí ti fẹ́ bọ́ lára rẹ̀.
Ó ní àwọn sáré lọ síbẹ̀ láti lọ wo nǹkan tó ṣẹlẹ̀, tí àwọn sì bá Timi níbi tí ó sùn kalẹ̀ sí ní ẹnu ọ̀nà yàrá rẹ̀ láì lè gbé apá tàbí ẹsẹ̀.
Ibukunoluwa Taiwo ní nígbà tí àwọn fi máa gbé Timi dé ilé ìwòsàn ó ti jáde láyé.
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Timi?

Oríṣun àwòrán, Others
Ibukunoluwa Taiwo ní ohun tí àwọn gbọ́ ni pé àwọn tó na Timi Alex dójú ikú náà fẹ̀sùn kàn pé àwọn rí fóònù kan tí wọ́n ti ń wá láti ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn lọ́wọ́ rẹ̀.
Ó ní ọ̀sán ọjọ́ Ẹtì ni wọ́n rí fóònù náà lọ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì gba fóònù náà padà lọ́wọ́ rẹ̀.
Ó ní ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kọ̀ láti lọ fi ẹjọ́ sun àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ilé ẹ̀kọ́ náà tàbí kí wọ́n pé òun láti fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn létí, wọ́n ṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn.
Ó ṣàlàyé pé òòru ni àwọn ọmọkùnrin náà ṣe iṣẹ́ láabi yìí tí wọ́n sì ti ilẹ̀kùn mọ́rí tí wọ́n sì nà án fún ọ̀pọ̀ wákàtí.
“Mo rò wí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà mọ̀ọ́mọ̀ hu ìwà yìí ni nítorí báwo ni wọ́n ṣe máa ri fóònù tí wọ́n ń lọ́sàn-án, tí wọn kò sì ṣe ohunkóhun àfi ìgbà tó di òru.
“Kò sí akẹ́kọ̀ọ́ tí kiò ní nọ́mbà ìbánisọ̀rọ̀ gíwá àgbà ilé ẹ̀kọ́ yìí àti nọ́mbà tèmi lọ́wọ́, ó yẹ kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ náà tó wa létí kí wọ́n tó ṣe ohunkóhun.
“Wọ́n ti Timi mọ́ inú ilé, wọ́n sì nà án fún ọ̀pọ̀ wákàtí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ̀ iye wákàtí tí wọ́n fi nà án.”
Ó ní ó ṣeni láàánú pé ẹni tó lè sọ iye ìgbà tí lílù náà fi wáyé ni ó ti pàdánù ẹ̀mi rẹ̀ yìí.
Àwọn afurasí ti wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá
Ibukunoluwa Taiwo tẹ̀síwájú pé ní kété tí àwọn dé ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ni àwọn bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti ṣe àwárì àwọn tó lu Timi títí ẹ̀mí fi bọ́ lára rẹ̀.
Ó ní láti ara fídíò tí àwọn tó ṣiṣẹ́ náà yà sórí fóònù wọn ni àwọn ti rí àwòràn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti àwọn sì ń fa gbogbo wọn lé ọlọ́pàá lọ́wọ́.
Ó sọ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lé ní ogún ni àwọn kọ́kọ́ kó lọ sí àhámọ́ ọlọ́pàá nígbà tí àwọn gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ́jọ́ Àbámẹ́ta àmọ́ àwọn ọlọ́pàá ti fi mẹ́fà kalẹ̀ nínú wọn.
“Ó jọ wí pé wọ́n ń da omi si lára bí wọ́n ṣe ń lù ú nítorí ilẹ̀ ibi tí wọ́n ti ń lù ú tutù àmọ́ nígbà ti a ma fi dé ibẹ̀ lọ́jọ́ kejì, wọ́n ti nu ilẹ̀ náà mọ́ tónítóní.
“Ó túmọ̀ si pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ nu ilẹ̀ náà bóyá láti bo àṣírí kan ni àmọ́ fídíò tí wọ́n ṣe ló tú àṣìrí wọ́n.
“Àwọn ọlọ́pàá kọ́ ló wá kó àwọn afurasí, àwa ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ni a ṣa àwọn afurasí tí a rí nínú fídíò náà, tí a sì kó wọn lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá.
“Àpapọ̀ afurasí méjìlá ló wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí.”
Níbo ni ẹ̀ṣọ́ tó ń ṣọ́ ibùgbé àwọn Timi wà lásìkò tí wọ́n ń lù ú?
Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní àwọn tó lu Timi dójú ikú jẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ máa ń ṣe papọ̀, tí yàrá wọn kò sì jìnà síra.
Ó ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ pé nǹkan bẹ́ẹ̀ ń wáyé ní òru ọjọ́ náà nítorí wọ́n ti ilẹ̀kùn mọ́rí àti pé òjò ńlá rọ̀ mọ́jú ọjọ́ náà.
Ó ṣàlàyé pé ariwo òjò kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ nǹkan tó ṣẹlẹ̀ àti pé àwọn tí wọ́n gbọ́ ní àwọn rò pé àwọn ọ̀rẹ́ kàn ń jà lásán ni.
Ó ní òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ náà tó ń ṣọ́ ibùgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní òu ń gbọ́ ariwo àmọ́ nítorí ẹnikẹ́ni kò wá sọ fun òun pé wọ́n ń na èèyàn ni òun kò ṣe dá sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ó sọ pé òṣìṣẹ́ náà ti wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá báyìí.
“Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń gbé ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ ti wáyé tí mo bá sọ̀rọ̀ ní ìgbà tí àwọn gbìyànjú láti lọ kan ilẹ̀kùn láti mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní wọ́n dúnkokò mọ́ àwọn pé àwọn máa lu àwọn náà.















